Osun Election 2018: Wọ́n ṣe ìbúra fún Oyetọla gẹ́gẹ́ bí gómìnà tuntun

Aworan Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Gboyega Oyetola/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Oyetola je olori awọn osisẹ ni ọfisi Gomina Aregbesọla.

Tonile talejo lo peju sibi ibura-wọle fun gomina tuntun Ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla ni papa iṣere ni Ilu Oshogbo.

Oyetola ni ajọ INEC kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo gomina to waye losu to lọ.

O dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nibi to ti fẹyin alatako rẹ, Ademola Adeleke ti o ṣoju ẹgbẹ PDP ninu ibo naa janlẹ.

Oríṣun àwòrán, Gbemi Jesuleke

Àkọlé àwòrán,

Gómìnà tuntun Ìpínlẹ̀ Osun Adegboyega Oyetola gbàwé ẹ̀rí

Ademọla Adeleke to jẹ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP to se ikeji ninu idibo naa ni eeru wa ninu esi idibo ọhun, ṣugbọn ajọ INEC Oyetọla lo jawe olubori.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Osun 2018: Àwọn olùdíje ADC, ADP, APC, SDP bá aráàlú sọ̀rọ̀ lórí èròǹgbà wọn

Ohun mẹwaa nipa Alhaji Isiaka Adegboyega Oyetola to dije dupo labẹ ẹgbẹ oselu APC

Isiaka Adegboyega ti wọn bi ni ilu Iragbiji, ni ijọba ibilẹ Boripe ni ipinlẹ Ọsun lo si ile iwe girama ti Ifeoluwa Grammar School ni ilu Osogbo ni ọdun 1972. Lati ibẹ̀, O lọ si ile iwe giga ti Fasiti Ilu Eko nibi ti o ti gba iwe ẹri ikẹkọgboye imọ ijinlẹ Bachelor of Science (Honours) ni imọ ẹkọ idojutofo ni ọdun 1978.

  • Ipinlẹ Yobe ni Oyetola ti sin ilẹ baba rẹ ni ọdun 1980 ni agbegbe Potiskum, ki o to bẹrẹ isẹ ti o yan laayo pẹlu ile isẹ adojutofo Leadway Assurance Company.
  • Ni ọdun 1990 ni Oyetola gba iwe ẹri imọ oye onimọ nipa eto ọrọ aje ni fasiti Eko kan naa.

Oríṣun àwòrán, Gboyega Oyetola/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Muhammadu Buhari kò gbẹ́yìn lásìkò tí Oyetọla n polongo ìbò

Bawo ni ìṣèlú Oyetọla Adegboyega ṣe bẹ̀rẹ̀?

  • Ọdun 1997 ni Oyetola ti darapọ mọ sise oselu, O pẹlu awọn to da ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy AD silẹ ni ọdun 1998, ki o to di alaga ẹgbẹ oṣelu ACN to di APC bayii.
  • Ọpọlọpọ eniyan lo ti sọ pe Oyetọla ni igi lẹhin ọgba fun isejọba gomina Rauf Aregbesọla lati ọdun mẹjọ sẹhin.
  • Oyetola to jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa lo jẹ onimọ nipa eto ìṣúná ati inawo, pẹlu ile isẹ adojutofo ti ti rẹ, Silvertrust Insurance Brokers Limited ti o da silẹ lati ọdun 1991, to si jẹ oludari fun ko o to di adari ajọ osisẹ fun gomina Aregbesola.
  • Awọn eniyan n pe oludije naa ni olufẹ ara ilu nitori awọn eto igbayegbadun to ti ṣe fun awọn ara ilu.
  • Bi o tilẹ jẹ pe ogun ọdun niyi ti Oyetọla ti n ṣe oselu, igba akọkọ ni yii ti yoo ma a dije du ipo labẹ ẹgbẹ oṣelu kankan.
  • Ọjọ keje lẹyin ti idibo Ọsun waye lọjọ́ Kẹjìlélógún, Osú Kẹ̀sán an, Ọdún 2018 ni Oyetọla yoo pe ọmọ ọdun mẹrinlelọgọta.
  • Amọ, oludije si ipo gomina ni abẹ oselu APC naa ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti ọpọlọpọ eniyan sọ pe oun ni ẹyinoju Alaga Ẹgbẹ Oselu APC, Asiwaju Ahmed Tinubu ati ti Gomina Ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola.