Tọkọtaya láti Najiria wọ wahálà torí ààwẹ̀ p'ọmọ wọn ní Amẹrika

Kehinde Omosebi ati iyawo re, Titilayo Omosebi, 48,

Oríṣun àwòrán, Sauk County Sheriff's Office

Tọkọtaya kan lati orilẹede Naijira, Kehinde Omosebi ati iyawo rẹ Titilayo Omosebi ti foju ba ile ẹjọ kan ni Ipinlẹ Wisconsin, orilẹede Amẹrika nitori ọmọ wọn ẹni ọdun marundinlogun gbẹmi mi nigba ti wọn n gba aawẹ.

Ileeṣẹ ọlọpàá ilu Reedsburg ni ọkọ to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta ati iyawo ẹni ọdun mejidinlaadọta naa ni awọn fi ẹsun aitọju ọmọ ati aikọbi ara si ọmọ ara ẹni to fa iku kan.

Ọga ọlọpàá Reedsburg Timothy Becker ni Kehinde funra rẹ lo wa si ileeṣẹ ọlọpàá lati wa funra rẹ jẹwọ pe ọmọ wọn ti gbẹmi mi ninu ile. O sọ fun awọn ọlọpaàá pe awọn ti n gbàwẹ̀ nàá fun ọjọ mẹ́rìnlelogoji ki ọmọ wọn to gbẹ́mìí mi.

Nigba ti awọn ọlọpàá tẹ le Kehinde dele, wọn ni lati ja lẹkun wọle ni. Wọn ṣakiyesi wipe, ko si ounjẹ kankan ninu ile naa ti wọn si ri oku ọmọdekunrin naa ti ko ni omi kankan lara.

Bẹẹ naa ni wọn ri aburo rẹ ọmọ ọdun mọkanla, ti ebi ti fẹ luu pa. Ipo kan naa ni wọn ba Titilayo, ko si omi kankan lara rẹ. Awọn ọlọpàá gbe ọmọ ọdun mọkanla naa ati iya rẹ lọ ile iwosan ṣugbọn iya rẹ kọ itọju; o sọ pe igbagbọ oun ko gba. Lẹyin naa ni wọn gbee lọ ẹwọn.

Ọlọpaaa ni awọn ti fa ọmọdekunrin naa le ẹka ijọba to n ri si itọju ọmọde lọwọ.

Kehinde sọ fun awọn ọlọpaa pe adari ijọ ni oun ni ile ijọsin Cornerstone Reformation Ministries, ṣugbọn awọn ọlọpaa ni o jọ pe ofege ni ọrọ rẹ.