2019 Election: Reuben Abati ni igbakeji gomina fún Kashamu

Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Àkọlé àwòrán,

Ìròyìn ní Adeleke Shittu tò borí ní ìdìbò abẹ́lẹ́ fipò sílẹ̀ fún Sẹ̀nétọ̀ Kashamu to n soju ẹkún ìdìbò Ìlá-Oorun ìpínlẹ̀ Ogun.

Ẹgbẹ oselu PDP ti fa ọwọ sẹnetọ Buruji Kashamu soke gẹgẹ bi ẹni ti yoo dije dupo gomina ni ipinlẹ Ogun ni idibo gbogboogbo ọdun 2019.

Oluranlọwọ fun Kashamu lori ọrọ to jẹ mọ iroyin, Austin Oniyokor sọ wi pe awọn adari ẹgbẹ lo parọwa si Kashamu lati dije dupo naa lẹyin Adeleke Shittu jọwọ ipo rẹ lẹyin idibo abẹle.

Adeleke Shittu to jawe olubori ninu idibo abẹlẹ ẹgbẹ oselu PDP ni iroyin fi lede wi pe o fi ipo rẹ silẹ fun sẹnetọ naa.

Àkọlé fídíò,

World Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Amọ, iroyin fikun wi pe agbẹnusọ tẹlẹri fun Aarẹ, Reuben Abati naa ni yoo ma dije dupo gẹgẹbi igbakeji gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP naa ni ipinlẹ Ogun.

Dapọ Abiọdun jáwé olúbori f'ẹgbẹ APC ní Ogun

Àṣẹ̀yìn wá àṣẹ̀yìn bọ̀ Dapọ Abiọdun ní ẹgbẹ́ òsèlú APC kéde gẹ́gẹ́ bíi olùjáwé ilúbori níbi ìdìbò abélé fún ẹni ti yóò dupò gómìnà lábẹ́ àsíà APC ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Saáájú ní àwọn ọmọ égbẹ́ APC ẹka ti ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde Adekunle Akinlade ní yóò dupò gómìnà lái fi ariweo ará ìlú àti àwọn olùkopa tókù ṣe.

Àkọlé àwòrán,

Ogun 2019: APC fà Dapọ Abiọdun silẹ loludije ipò Gómìnà ajumọyan

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí

Akinlade to jẹ́ ọmọ ilé ìgbàmọ aṣofin l'Abuja ní wọn ti fà kalẹ̀ tẹ́lẹ̀, sùgbọn lẹ́yìn ti àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe tí Adams Oshiomhole ń dari dé láti wá tun ìbò dí làwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ipínlẹ̀ Ogun bẹ̀rẹ̀ sí ni ké gbàjarè pé ilé ẹgbẹ́ àpaps frẹ́ yàn lé àwọn lọ́wọ́. Ẹ̀yìn ò rẹyìn Dapọ̀ Abiodun ló wolé níbí àtúndi ìbò tí ìgbìmọ amúṣẹ́ṣe àpapọ̀ darí.

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'

Dapọ Abiọdun jáwé olúbori pẹ̀lú ìbò ẹgbẹ̀rún lónà ọgọ́rùn o lé méjì àti márùnlélọ́ọ̀dúrúǹ, nígbà ti Jimi Lawal to pọwa lée ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànléní ààdọ́ta àti ẹ̀tàléláàdọ́jọ, Bimbo Ashiru tó ní ìbò ẹgbẹ̀rún makàndínlọ́gbọ̀n àti ẹ̀rìnlélọ́gọ́talélẹ́ẹ̀dẹ̀gbẹ̀rin.

Ẹni tó tún tòlé èyí ní Adekunle ti wọn kakọ́ yàn ní ìbò ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún àti ẹ̀tàlélógójìlénírinwó, Sẹnatọ Adegbenga Kaka ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàd'inlógún àti ọ̀kanléláàdọ́rinlélẹ́ẹ̀dẹ́gẹ̀rin àti Abayomi Semako0 Koroto tó ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn àti mẹ́wàálélẹ́gbẹ̀ta

Ogun 2019: APC fà Adekunle Akínlàdé silẹ loludije ipò Gómìnà ajumọyan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adekunle Abdulkabir Akinlade

Àkọlé àwòrán,

Asoju fun ẹkun idibo guusu Egbado ati Ipokia ni Adekunle Abdulkabir Akinlade

Awọn agbagba ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun ti kede orukọ ẹni ti yoo jẹ oludije fun ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ wọn .

Adekunle Akínlàdé Abdulkabir lorukọ rẹ.

Eyi jẹyo lẹyin ti awọn eekan ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun se ipade nile akọwe ijọba ipinlẹ Ogun nigba kan ri Oloogbe Poju Adeyemi lori ọna ti wọn yoo fi yan oludije ẹgbẹ fun ipo Gomina.

Bakanna la gbo wi pe Gomina Ibikunle Amosun naa ti kede pe oun yoo du ipo asofin agba labe asia APC fun ẹkun arin gbungbun ipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò,

Ìdìbò Ọṣun: Omisore, Akinbade ni ìjọba àpapọ̀ fẹ fi N10,000 rà'bò ni

Adekunle to jawe olubọri gẹgẹ bi oludije ayanfẹ ẹgbẹ jẹ asoju sofin nile asofin orileede Naijiria.

A gbo pe oun lo pegede laarin awọn oludije ti wn le ni mewa to n du ipọ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adekunle Abdulkabir Akinlade

Àkọlé àwòrán,

Gomina Ibikunle Amosun n gbero lati pada si ile asofin gẹgẹ bi Seneto lọdun 2019

Ẹwẹ,Gomina ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimọbi naa ti ni oun ati awn eekan ẹgbẹ yo pa'mọranpọ lati yan ẹni ti yoo soju ẹgbẹ ninu idije Gomina lọdun 2019.

Ikede yi la gbo pe o waye lọjọru nibi ipade awọn alẹnulọrọ ẹkun arin gbungbun ipinlẹ Oyo ni papa isere Durbar ni Oyo.

Ijọba ibilẹ mọkanla lo wa labẹ ẹkun idibo yii.