Rinsola Abiola: ADP fi ayé gba obìnrin ati ọdọ ni mo ṣe darapọ̀ mọ́ wọn.

Aworan Rinsola Abiola pẹlu ọmọ ẹgbẹ ADP

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rinsola Abiola

Àkọlé àwòrán,

ADP ni adisokan lati fi aaye gba ọdọ ati obinrin ninu eto oselu

Ọmọ oloogbe MKO Abiola, Rinsola Abiola, ti yan ẹgbẹ oselu ADP laayo lẹyin igba to fi ẹgbẹ oselu APC sillẹ.

Ikede to se atọna igbese rẹ yii jẹyọ loju opo Twitter rẹ .

Ninu ọrọ to fi sita, o sọ wipe oun ''darapọ mọ awọn obinrin ati ọdọ ninu ẹgbẹ oselu ADP nibi ifilọlẹ awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ́ naa ni ijọba ibilẹ ariwa Abeokuta''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Josh Posh: Inú mi máa ń dùn láti kọrin fún àbúrò mi ní kékeré

Ninu alaye to se nipa igbese toun gbe yii, Rinsola so pe fifun awọn obinrin ati ọdọ lanfaani lati kopa ninu oselu jẹ nnkan gbogi ti oun yan ladi-sọkan.

''ipinnu mi lati yan ADP ko sin lẹyin pe wọn ni ifarajin fun ọrọ obinrin ati ọdọ''

Bakanna lo tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe, iye owo ti ẹgbẹ oselu ADP n gba fun fọọmu fifi erongba han lati dije fun ipo oselu, ko gunpa rara.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rinsola Abiola

''Fun awọn to n dije ipo ile asofin nipinlẹ, ₦330,000.00 ni wọn n san, nigba ti awọn to n du ipo ile asoju sofin si n san N1,100,000''

O ni awọn oludije obinrin laanfani pe wọn ko ni san owo fọọmu.

Bi APC ṣe pàdánù ọmọ MKO Abiọla

Ọmọ ẹgbẹ oselu APC ni Rinsola jẹ tẹlẹ ti o si n ba olori ile asoju sofin agba labuja, Yakubu Dogara, sisẹ gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki.

Nigba ti afẹfẹ iyiẹgbẹ pada n fẹ loun naa kede pẹ oun ko se ẹgbẹ APC mọ.

Ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si alaga wọọdu idibo rẹ, eyi to tẹ fi sọwọn si oju opo Twitter rẹ ni Rinsọla ti salaye pe igbesẹ ohun lati fi ẹgbẹ APC silẹ ko ṣẹyin ofin tuntun ti awọn oludari ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, fi sita.

O ni irinajo ọdun maarun pẹlu ẹgbẹ osẹlu naa jẹ eyi to kun fun ẹ̀ka ti ko ṣe e gbagbe.

Bi o tilẹ jẹ wipe awọn kan n sọ lori ayelujara Twitter pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ni Rinsọla darapọ mọ, arabinrin naa ni oun ko ti darapọ mọ ẹgbẹ́ oṣelu kankan.

Ati pe awọn nkan bi fifi aaye gba awọn obinrin ati ọ̀dọ́, to fi mọ iṣejọba awa-arawa l'abẹle, ni yoo sọ ẹgbẹ oṣelu ti oun yoo pada darapọ mọ.

O ni ki awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣi fi ara balẹ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si:

Àkọlé fídíò,

Ọdalẹ ni Babangida ati Abacha - Ọmọ Abiola

Àkọlé fídíò,

'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'