Òjò àrọ̀rọ̀dá: Iṣẹ́ òòjọ́ dẹnu kọlẹ̀ l'Ékòó

Àkọlé fídíò,

Ojo arọrọda Eko ṣe idiwọ fún káràkátà

Lati owurọ kutukutu ọjọ Ẹtì, bii deede aago mẹfa, ni ojo arọrọda ti bẹrẹ, to si se idiwọ feto karakata nipinlẹ Eko.

Ọpọlọpọ òpópónà ló kún fún omi, ti awọn awakọ mi i si duro diẹ ki ojo naa wawọ, ki wọn to tẹsiwaju lẹnu irinajo wọn.

Àsìkò yi ni ojo máa n pọ ní orílèèdè Naijirià, tí àwọn àjọ tó n mójú tó ojú ọjọ sí ti fi ìkìlọ síta pé, o ṣeéṣe kí ọjọ po lẹnu ọjọ mẹta yí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

NISE NI OJO TO RO LEKO KUN OJU TITI

Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba, to tọpinpin ojo arọrọda naa ti wi, ọpọ isẹlẹ sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lo waye lawọn ọpọ oju popo nilu Eko, ti aimọye osisẹ si pẹ pupọ, ki wọn to de sẹnu isẹ wọn.

Koda, ọpọ awọn ọja nla-nla gbogbo lo da paro-paro nitori bawọn ontaja ati onibara ko se ri ọna de awọn inu ọja yii, ti agadagodo si wa lẹnu awọn sọọbu ile itaja gbogbo.

Ladugbo Ikoyi nibi ti ofisi Ile isẹ BBC wa, awọn opopona bi Lugard, Alfred Rewane ati Glover kun fọfọ fun omi.