Tremor: Awọn olùgbé Mpape sọ ìrìrì wọn

Ile awoku
Àkọlé àwòrán,

Ojú kan la fí ń sùn, lẹ́yìn ilẹ̀ mímì tó wáyé

Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé Mpape ní wọn sọ pé orùlé ilé àwọn ti lọ lẹ̀yìn ilẹ̀ mímì tó wáyé ní ni Abuja tí gbogbo ile àwọn sì ti ń dàwó.

Ọpọ wọn sàlàyé pé ilé ọ̀rẹ́ àti ẹbí ní àwọn ńgbé báyìí nígbà ti àwọn kán kó ẹ̀rù wọn sí ẹgbẹ́ kan ilé àwókù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bótilẹ̀ jẹ́ pé sps ilé ti wàhálà yìí ṣẹ̀lẹ̀ sí jẹ́ ilé alábara ti àwọn míràn máà ń pè ní ilé alámọ̀ tí wọn sì ńka ohun tí wọn pàdánù báyìí.

Abdullahi sàlàyé pé ọdún mẹ́ẹ̀dógún séyìn ní òun ka ilé òhun tí oun kò sí mọ pé bí gbogbo rẹ̀ yóò ṣe dàyà déll rèé.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ojú kan la fí ń sùn, lẹ́yìn ilẹ̀ mímì tó wáyé

O fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé nígbà ti ilẹ̀ mú àrìwo ńlá ka jáde ní ìpìlẹ̀ ilé náà bẹ̀rẹ̀ sí ni mì títí ti àpá kan ilé náà fi ya lulẹ̀.

Abdullahi ní kọ́tìnì ni oun fí bo apá kan ile tó yapa tí oun àti ebí oun ń sùn.

Àkọlé àwòrán,

Abuja Tremor: Adarí àjọ DGNG rọ àwọn ará Abuja láti fọkan balẹ

Ní ti Hafusatu Haruna, ó sàlàyé pé nígbà tí òun gbọ́ àriwo nla náà ẹru ba oun àti pe oun rò pé àyé ti parẹ́ ni, kíá ni oun ti sáré lọ sápamọ nínú yàrá kí ọkan oun to balẹ̀

O ní ẹ̀ru sì ń ba oun pé ti irú ǹkan bayìí bá tẹ̀siwajú, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò dàmú pùpọ̀

Oluwafẹmi Samuel sọ pé lati ìgbà tí dé àdúgbò náà oun ò rí ńkan tó jọ bẹ́ẹ̀ rí, ati pé ní bayìí oun kìí fi ọkan balẹ̀ sùn mọ.

Abuja Tremor: Adarí àjọ DGNG rọ àwọn ará Abuja láti fọkan balẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kò sí ewu ló ilè mímì ìlú Abuja

Olùdarí àgbà fàjọ tó ń rí sí ìwádìí imọ ijinlẹ nipa ọ̀rọ̀ ilẹ ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà, Alex Nwegbu tí rọ àwọn olúgbé ìlú Abuja pé, kò si ewu nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nípa ilẹ mímì.

Ó fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn oníròyín sọrọ nílù Abuja, pẹlu afikun pé Nàìjíríà kò pààlà pọ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tó le koju ilẹ̀ rírì.

'Fún ìdí èyí, ó ṣeeṣé kí rí ilẹ mì díẹ̀. Fún àwọn tó ń gbé àgbègbè Mpape, níwọn ìgbà tí ilé ò bá ti wó, kò sí wàhálà, wọn lee padà sí ilé wọn.

"Lẹ́yìn tí ìṣèlẹ̀ yẹ sẹlẹ̀ ní ijẹ́ta 05-09-2018, à ti rán àwọn òṣìṣẹ́ lati lọ wo ìdí abájọ rẹ, sùgbọ́n àkíyèsi ní pé, kò sí pé ogiri ile to lanu tabí pé ile wo, èyí sì túmọ sí pé ilẹ mímì náà kò lágbára.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Tremor: Adarí àjọ DGNG tí rọ àwọn ènìyàn Abuja láti fọkan balẹ

Tí ẹ ò bá gbàgbé, ní ààrọ kùtùkùtù ọjọru ní ìlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní mí, ilé mímì yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùgbé àdúgbò kan ṣe fidi rẹ mulẹ.

Níbà yìí àjọ tó ń ri sí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì l'Abuja FEMA tí gbé àwọn ìtọ̀nà tí àwọn ará ìlú yóò máa tọ tí ilẹ̀ rírì bá ṣẹlẹ̀.

  • Fara balẹ̀ máá bẹ́rù
  • Bí o bá wà nínú ilé, wá yàrà tí ó ní ààbò, kí gbogbo àwọn tó bá wà nínú ilé bẹ̀rẹ̀ sí abẹ́ tábìlì, kí wọn sì dìí mú ṣinṣin, sùgbọn ríi dájú pé ẹ ò sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrèsé nítorí o ṣeeṣe kí ó wo
  • Tí o bá wà ní ìta, wá ibi ti kò sí igi tó ga gogoro, ilé tó ga gogoro àtí òpó ina sa sí
  • Tí o bá wà ní inú moto, rìn jẹ́jẹ́ kí wá ibi ti ilẹ ti tẹ́jú, dúró síbẹ títí ilẹ mímì náà yóò fi pari.

Oríṣun àwòrán, FEMA

Àkọlé àwòrán,

Tremor: Adarí àjọ DGNG tí rọ àwọn ènìyàn Abuja láti fọkan balẹ