NEMA, NHISA ní ó ṣeéṣe kí ẹ̀kun omi wáyé ní ìpínlẹ̀ méjìlá

Awọn eeyan ninu agbami agbara nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ki awọn eeyan orilẹede yii, paapaa awọn olugbe ipinlẹ ti ọrọ kan atawọn alẹnulọrọ lee gbaradi ni awọn ajọ tọrọkan yii fi ke ibosi sita

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA pẹlu ajọ to n ṣe iwadi nipa ọrọ omi lorilẹede Naijiria ti ṣekilọ pe awọn ipinlẹ mejila kan lorilẹede Naijiria ko ni pẹ foju wina ẹkunomi eleyi ti yoo waye nipasẹ arọọrọda ojo.

Awọn ajọ mejeeji yii tọka si awọn ipinlẹ ti ọrọ shun yoo kan gẹgẹ bii ipinlẹ Kogi, Kebbi, Niger, Kwara, Edo, Anambra, Rivers, Bayelsa ati Delta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn tun darukọ Taraba, Benue ati Adamawa gẹgẹ bii ara awọn ipinlẹ ọhun.

Awọn ajọ naa ni, iṣẹlẹ ẹkun omi naa ti n kankun ni lọwọlọwọ bayii nitori gbogbo awọn ohun atọka to ṣe atọna fun iṣẹlẹ ẹkun omi lọdun 2012 ti farahan bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ṣiṣi awọn adagun omi Shinroro, Kainji ati Jebba nitori arọọrọda ojo ti n mu ki iṣẹlẹ ẹkun omi o maa kan ilẹkun ni Naijiria

Awọn ajọ mejeeji yii ni idi ti awọn fi ke ibosi sita lori rẹ naa ni lati fun awọn eeyan orilẹede yii, paapaa awọn olugbe ipinlẹ ti ọrọ kan atawọn alẹnulọrọ laaye lati gbaradi.

Ọkan lara awọn ọgaagba ajọ to n ṣe iwadi nipa ọrọ omi lorilẹede Naijiria, Clem Eze ṣalaye wi pe bi ati n sọrọ yii, kikun omi odo ọya, iyẹn River Niger ti le ni mita mẹwa eleyii to pọ ju mita mẹwa o din diẹ to wa lasiko iṣẹlẹ ẹkun omi ọdun 2012 to si n pọ sii ni wakati, wakati.