Fayoṣe fẹ́ kí EFCC sàn owó Ìtanràn N20 biliọnu fún òun

Fayose/Ami idanimọ̀ EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC/Fayose/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Ẹ̀nu kun EFCC lórí ìkéde tó fi síta nípa Fayose níkété tí wọ́n kéde èsì ìbò gómìnà Ekiti

Gomina Ayodele Fayose ti ipinlẹ Ekiti ti kowe si ile isẹ EFCC, Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹ-ede yii, lori ẹsun pe won ba oun loruko je ti wọn si kowe majade nilu si awọn ile isẹ alaabo.

Iyẹn nikan kọ, Fayose ni ki ọrọ naa to le tan nilẹ afi ki wọn san ogún biliọnu Naira ki wọn si kowe mabinu soun.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fún gomina Fayose, Lere Olayinka, fi sita loju opo ayelujara,o ni wakati méjíléláàdọ́rin ni oun fun ajọ EFCC lati se atunse bi bẹẹ kọ, awọn agbejọro yoo pe wọn lẹjọ.

Ọjọbọ ni atejade naa jade nibi ti agbẹjọro Fayose, Obafemi Adewale ti bẹnu atẹ lu igbese ajọ EFCC ninu iwe kan ti wọn fi sita lọjọ kejila, Osu kẹsan pe ki ''awọn ile isẹ alaabo ma sọ Fayose tọwọ tẹsẹ ni awọn ibode Naijiria ki o ba ma sa mọ wọn lọwọ.''

Obafẹ́mi ni ''Ọrọ yi mu abuku ba ẹni ti a n soju fun paapa julọ pe o tilẹ jẹ Gomina ti ofin daabo bo. Looto ni pe wọn n se iwadi ẹsun ti wọn fi kan Fayose sugbọn eyi ko tumọ si wi pe yoo wa fẹsẹ fẹ. Fun idi eyi, a fẹ ki ẹ se agbeyewo ki ẹ si yọ orukọ Fayose kuro ninu awọn ti wọn le sa kuro nilu tori pe awọn agbofinro n se iwadi wọn''

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'

Obafemi pari ọrọ rẹ́ pe wọn gbodo ko iwe lati fi tọrọ aforijin lọdọ Fayose ti wọn si gbọdo san bilionu ogun Naira lowo itanran bi bẹ kọ,ile ẹjọ ni yoo pari ọrọ fun awọn.

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí

Gomina Fayose ati ajọ EFCC ki se ajoji ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Ayodele Fayose/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ayọdele Fayoṣe ti máa ń tako ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ni ọdun 2016 ni àjọ EFCC gbẹ́sẹ̀ lé àṣùwọ̀n ìfówópamọ́sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ayọ̀délé Fáyóṣe.

Ni kete ti igbakeji Fayose,Olusọla Eleka ti fidirẹmi ninu idibo Gomina ipinlẹ Ekiti ajọ EFCC kede pe 'awọn ti gbọn awọn iwe to wa lọwọ awọn lori magomago to waye lori awọn ile adiyẹ ti wọn dá sílẹ̀ l'Ekiti.'

Ko pẹ si igba naa ni EFCC kowe ransẹ ki Fayose yọ́ju si ile isẹ ajọ naa ti o si kọ lati yọju.

Lati igba naa ni ọrọ laarin ajọ naa ati Fayose ti di ikun n dẹ dẹdẹ,dẹdẹ n dẹ ikun.

Ọrọ ko wọ laarin Fayose ati Fayemi naa

Laipẹ yi ni Ijọba ipinlẹ Ekiti labẹ akoso Gomina Ayodele Fayose fẹsi si ẹsun ti Gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan ni ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi fi kan lori jijẹ gbese ₦117bn kalẹ de Fayemi.

'Awa ko tọwọ bọ iwe adehun ẹyawo kankan ko si si bi a ti ṣe le ya owo ti ile iṣe to n risi ọrọ gbese ati ile ise fun eto isuna ko nimọ nipa rẹ'

Atejade lati ọdọ Lere Olayinka to jẹ agbenusọ fun Gomina Fayose ni niṣe ni Fayemi n ''wa awawi kale de bi ijọba rẹ yoo ba fori sanpọn.

O tẹsiwaju pe ijọba Fayose ko da bi Fayẹmi ti eru n ba lati koju igbimọ iwadi lẹyin to pari saa rẹ gẹgẹ bi Gomina.

''ẹru o ba odo wa. Bi won ba fe ṣe iwadi baa ti ṣe ṣe ijọba kiba jẹ ijọba ipinlẹ tabi lati ọdọ ijọba apapọ.''

Lere ni gbese tiijọba ipinlẹ Ekiti jẹ kalẹ jẹ N59.5bn eyi ti awọn jogun lati ọdọ ijọba Fayemi ati awọn eyawo miran to ti ati ọwọ ijọba apapọ wa latari bi wọn ti ṣe ṣe atunto awọn eyawo ohun.

Fayemi ke gbajare

Bi a ko ba gbagbe laipe yi ni Gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan ni ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi kede pe, oun ti fa gomina to n kogba wọle nipinlẹ naa, Ayọdele Fayọṣe si kootu Ọlọrun lori awọn obitibiti gbese to jẹ lasiko to wa nijọba.

Fayẹmi ni, gbogbo gbese yoowu ti ijọba to n palẹmọ bayii lati kogba wọle nipinlẹ naa ba jẹ, ni oun yoo tẹwọ gba nitori igbagbọ oun ni pe, ijọba n tẹsiwaju ni, ko duro si oju kan.

Lasiko ti o fi n tẹwọgba abajade iṣẹ igbimọ to gbe kalẹ fun iyipada iṣejọba nipinlẹ Ekiti ni Ọmọwe Fayẹmi kede eyi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

O ni iyalẹnu lo jẹ bi gbese ipinlẹ naa ṣe gbera lati biliọnu mejidinlogun lasiko ti oun fi ipo silẹ di biliọnu mẹtadinlọgọfa labẹ iṣejọba Fayose, gẹgẹ bii ileeṣẹ to n mojuto ọrọ gbese lorilẹede Naijiria, DMO ṣe sọ.

Ohun ti igbimọ naa sọ fun Fayẹmi ni pe, gbese ti a n sọrọ rẹ yii ko mọ owo oṣu ti ijọba jẹ awọn oṣisẹ ati oṣiṣẹ fẹyinti atawọn owo to yẹ ni sisan fawọn Agbasẹṣe to n ṣiṣẹ fun ijọba nibẹ.

Bakan naa ni Fayẹmi tun pe fun agbekalẹ ofin, ti yoo kan nipa fun ijọba to ba n fipo silẹ lati fun eyi to fẹ wọle lanfani, si gbogbo iroyin nipa eto ati iṣẹ ijọba gbogbo nitori gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ijọba Fayoṣe kuna lati fi anfani silẹ fun igbimọ rẹ lati mọ ibi ti nnkan de duro nidi isejọba rẹ.