Agbófinró mú afurasí to ṣekú pa Collins Esiabor

Malik Onebiri ti w[ọn funra si pe o pa ọlọpaa
Àkọlé àwòrán,

Malik Onebiri ni wọn fi ẹsun kan pe o yinbọn to pa sajẹnti naa

Ifakọ Ijaye ni Ọgba ni wọn ti yinbọn pa agbofinro naa.

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko ti tẹ arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Malik Onebiri ti wọn fura si pe o pa sajẹnti ọlọpaa kan.

Collins Esiabor ni wọn yinbọn pa ni Ifako Ijaiye, Ogba ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Chike Oti ni ilu Gboko ni Ipinlẹ Benue ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti mu Onebiri ti inagijẹ rẹ n jẹ Kobad Baron.

Àkọlé fídíò,

Àjọ Ọlọ́pàa Naijiria: A ó fi òsìsẹ́ SARS tó se isẹ́ ibi náà jófin

Onebiri ni wọn fi ẹsun kan pe o yinbọn to pa sajẹnti naa.

Ara ikọ ọlọpaa kan to wa ni Haruna Bus Stop ni Ijako Ijaiye ni Esiabor wa nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Eiye ṣe ikọlu si wọn ọlọpaa naa. Wọn tun ba ọkọ ọlọpaa jẹ ninu akọlu naa.

Ẹyin iṣẹlẹ naa ni kọmiṣọna fun ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal leri pe, ibikibi ti Onebiri to yinbọn to pa sajẹnti naa ba wọ, ọwọ yoo tẹ.

Lẹyin naa ni awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ lati Area 'G' Ogba gbe awọn mọkandinlogun ti mọle, ti wọn si tun wa Onebiri lọ.

Ọlọpaa ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naaa pa ọlọpaa naaa lati gbẹsan ọkan lara wọn ti wọn ni o gbẹmi mi nigba to fara pa nibi to ti n sa lọ nigba to ri awọn ọlọpaa ni Ifakọ Ijaiye.

Àkọlé fídíò,

Bọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́