Àarẹ Tanzania: Ẹ má lo òògùn ìfètò sọ́mọ bíbí mọ́

Àwọn ọbinring ati ọmọde Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn obinrin Tanzania maa n bi to ọmọ marun ni ọjọ aye wọn

Ààrẹ orilẹede Tanzania John Magufuli ti rọ awọn obinrin orilẹede naa ki wọn ye lo oogun ìfètò sọ́mọ bibi nitori awọn eniyan orilẹede naa ko pọ to.

Ṣugbọn olori alatako ni ile igbimọ aṣofin orilẹede naa Cecil Mwambe ti bẹnu atẹ lu ọrọ naa. O ni ọrọ ọun lodi si ilana eto ilera orilẹede Tanzania.

Miliọnu mẹtalelaadọta eniyan lo wa ni Tanzania, ti ida mọkandinlaadota ninu ọgọrun wọn n gbe igbe aye wọn pẹlu dọla meji lọjumọ.

Bi ida mẹta ninu ọgọrun ni awọn ero orilẹede naa fi n pọ si, eyi to fi wa lara orilẹede to tete n pọ si ju lagbaye.

Its population is growing by more than 3% a year, among the highest rates in the world.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Àarẹ Magufuli ni ọlẹ ni awọn ti ko fẹ ọmọ si.

Magufuli sọ nibi ipade ita gbangba kan ni ọjọ Aiku pe awọn to n lo oogun ifeto sọmọ bibi, ọle ni wọn.

O ni, "Wọn ko fẹ ṣiṣẹ lati bọ idile to tobi ni. Wọn fẹ maa lo oogun ifeto sọmọ bibi ki wọn baa le bi ọmọ kan tabi meji. Ẹ lọ si oke okun ki ẹ lọ ri ijamba ti oogun ifeto sọmọ bibi n ṣe lara."

Image copyright AFP

Ọjọ kan lẹyin ti Magufuli sọ ọrọ yi, olori ile igbimọ aṣofin Job Ndugai fi ofin de awọn aṣofin to jẹ obinrin lati maa lẹ ike mọ eekan ọwọ wọn ti wọn ba wa ni gbọngan aṣofin.

Ndugai sọ fun BBC Focus on Africa pe nitori ilera ni oun ṣe gbe igbesẹ naa, ṣugbọn ko ṣalaye.

Ofin naa tun de awọn obinrin aṣofin lati maa wọ aṣọ penpe tabi jinsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSe ẹ mọ pe pẹlu Google Maps, ọmọ to ba sọnu lee di riri?