David Bamigboye: Ọjọ́ Ẹtì ló mí kanlẹ̀ lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́

David Bamigboye Image copyright @IlọrinInfo

Igi da, erin wo, Ajanaku ti sun bi oke, iku ti mu akọni lọ.

Gomina ologun akọkọ ni ipinlẹ Kwara, Ajagunfẹyinti David Bamigboye, ti ki aye pe o digbose ni ọjọ ẹti.

Aburo oloogbe, Ajagunfẹyinti Theophilus Bamigboye lo tufọ iku rẹ, pẹlu afikun pe aisan ranpẹ lo mu ẹmi rẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Election 2018: Aráàlú ní àwọn kò fẹ́ ìjọba elébi mọ́

Oloogbe David Bamigboye ni wọn bi lọjọ keje, osu kejila ọdun 1940. Oun si ni lo se agbekalẹ ile ẹkọ gbogbo n se Poly tijọba ipinlẹ Kwara lọdun 1972,

Niwọn igba to si jẹ pe baa ba ku laa dere, eeyan kii sunwọn laaye, awọn ẹni bii ẹni, eeyan bii eeyan ti n sedaro iku akọni oloogbe to faye silẹ naa.

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ransẹ ibanikẹdun sawọn ọmọ ilẹ yii lori iku David Bamigboye.

Image copyright @IlọrinInfo

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ Buhari feto iroyin, Shehu Garba fisita ni, titi aye ni awọn ọmọ orilẹ-ede yii yoo maa seranti oloogbe naa fun ifaraẹnijin rẹ, isẹ takuntakun ati iwa asaaju rẹ, to fi mu idagbasoke ba ilẹ Naijiria.

Bakan naa, loju opo Twitter,@bukọlasaraki, aarẹ ile asofin agba ilẹ wa, Bukọla Saraki ti n para poro lori iku David Bamigboye, to si ni isẹ takuntakun to se si ipinlẹ Kwara, lawọn ko ni gbagbe laelae.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdul Fatai Ahmed ni ọkan oun gbọgbẹ lori iku Bamigboye, ti iku rẹ si jẹ adanu nla fun ipinlẹ Kwara amọ igbe aye rere to gbe ati idagbasoke to mu ba ipinlẹ́ Kwara lawọn yoo fi rẹ ara awọn lẹkun.

A wa gbadura pe ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun ẹni re to lọ.

Oku Koffi Annan gunlẹ́ si Ghana

Okú àgba ọ̀jẹ ọmọ Ghana, Kofi Annan to jẹ akọwe agba fun àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé nígba kan rí ti de Accra ni orilẹede Ghan ni ọjọ Aje.

Baalu ajọ ìṣọ̀kan agbaye (United Nations) lo gbe lati Geneva ni orilẹede Switzerland wa si Ghana.

Iyawo oloogbe naa, Nane Maria ati awọn ọmọ wọn (Ama, Kojo and Nina) darapọ mọ awọn oṣiṣẹ ajọ agbaye to tẹle oku naa wa si Ghan fun isinku. Ijọba orilẹede Ghana ni yoo ṣe isinku naa ni ọjọ Ojobo, ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn, ọdun 2018.

Ààrẹ Nana Akufo-Addo ati awọn ẹẹkan ilu ati ileeṣé oloogun orilẹede naa ni wọn lọ pade oku naa ni ibudo ọkọ ofurufu ti Kotoka.

Lati ibudokọ naa, wọn gbera lọ oriko apejọro to wa ni Accra nibi ti wọn yoo ti tẹ safẹfẹ ti awọn eniyan yoo lanfani lati wa wo ni ọjọ Iṣẹgun.

Ijọba orilẹede Ghana kede ni osẹ to kọja wipe ilẹ isinku ti awọn oloogun to wa ni Accra, ni wọn yoo Annan si.

Ilẹ isinku tuntun naa ni Ghana ma n sin awọn ẹẹkan ni ileeṣẹ oloogun, awọn aarẹ to ba di oloogbe ati awọn eekan ilu si.

Image copyright Kofi Annan/Twitter
Àkọlé àwòrán Kofi Annan ati awọn ẹbi rẹ

Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ni Anna ku ni Bern, ni orilẹede Switzerland lẹyin aisan ranpẹ.