Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní N16 bílíọ̀nù, owó Paris fund ti tẹ àwọn lọ́wọ́

Rauf Aregbesola Image copyright Rauf Aregbesola
Àkọlé àwòrán 'Ko si idi fun ijọba ipinlẹ Ọṣun lati san abọ owo oṣu mọ bayii'

Ariwo ta ni ọjọ diẹ sẹyin nipa iroyin kan to kan nigboro pe ijọba apapọ ti gbẹyin san adapada owooya Paris fund fun ijọba ipinlẹ Ọṣun.

Bi awọn eeyan kaakiri ibu ati oro orilẹede Naijiria ni wọn sọ si ọrọ naa; koda ẹgbẹ oṣelu PDP gan ko gbẹyin pẹlu ẹhonu pe ti iroyin naa ba jẹ lootọ, o ku diẹ kaato fun ijọba apapọ labẹ aarẹ Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

APC pàdánù aṣòfin míràn ní'pínlẹ̀ Osun

APC àti PDP takora wọn lórí Olùsirò owó àgba Ọsun tó fisẹ́ sílẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́

Nibayii, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọọ wi pe lootọ lawọn gba biliọnu mẹrindinlogun naira lọwọ ijọba apapọ.

Olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Rasaq Salinṣile lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ ori ẹrọ Ibanisọrọ kan pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti tẹwọ gba owo naa lọwọ ijọba apapọ.

"Owo naa wa lara owo ti a o mu lara rẹ fi san lara ajẹẹlẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ọṣun"