Mimiko: Mo ti jáwọ́ lórí ìdíje ààrẹ, Sẹ́nétọ̀ ni mo fẹ́ báyìí

Segun Mimiko

Oríṣun àwòrán, @Segunmimiko

Àkọlé àwòrán,

Gboye Adegbenro to n dije fun ipo sẹnetọ ni ẹkun idibo Ondo Central tẹlẹ, ni oun pẹlu ti yọ ọwọ lati fun Mimiko laaye lati dije.

Oludije ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party , Olusẹgun Mimiko ti dagbere fun idije ipo aarẹ lọdun 2019.

Lasiko ti o fi ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni ọjọbọ ni Dokita Mimiko kede ọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni 'fun anfani ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ni mo ṣe gbe igbesẹ yii.'

Amọṣa, Mimiko ti ni oun ko ni lọ lọwo ofo o nitori naa ipo sẹnetọ ni oun yoo maa lọ fun bayii ni abẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu kan naa.

Oríṣun àwòrán, @Segunmimiko

Àkọlé àwòrán,

Mimiko ni fun anfani ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ni igbesẹ ti oun gbe

Ni bayii, oludije fun ipo sẹnetọ ni ẹkun idibo ile aṣofin apapọ Ondo Central tẹlẹ, Onimọ ẹrọ Gboye Adegbenro ni oun pẹlu ti yọ ọwọ kuro ninu idije fun ipo sẹnetọ lọdun 2019 lati fun gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Oluṣẹgun Mimiko laaye lati dije.

Amọṣa Mimiko ko sọ ọrọ lori boya yiyọ ti ẹgbẹ oṣelu rẹ yọ ọwọ ninu idije aarẹ tumọ si pe wọn yoo gbaruku ti ẹgbẹ oṣelu miran fun idije ipo arẹ lasiko idibo apapọ lọdun 2019.

Ṣe Ọlọrun ko sọrọ mọ ni?

Mimiko ti kọkọ ṣalaye ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba laipẹ yii pe ohun ti ṣeto igbaradi gbogbo to yẹ lati di aarẹ.

Bakan naa lo sọ pe Ọlọrun sọ fun oun pe awọn ipo ti oun ti de ṣaaju wa lati mu oun dide fun ipo aarẹ lọdun 2019, ohun ti o wa n fa ibeere bayii ni boya ohun Ọlọrun naa ti yipada?

Àkọlé fídíò,

'Lọ́gán tí mo bá di ààrẹ, mo máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́'

Olusegun Mimiko yóò du ipò àarẹ Nàìjíríà

Àkọlé àwòrán,

Mimiko kéde láti dupò Ààrẹ ni 2019

Wọn ko fẹ ọ nilu o ń da orin,toba da tan tani yoo ba o gbe?

Apejuwe to fẹẹ se rẹgi rẹ lori ọrọ to n sẹlẹ laarin ẹgbẹ osise orileede Naijiria ati Gomina ana fun ipinlẹ Ondo Olusegun Mimiko to ni oun fẹ du ipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu osisẹ,LP.

Mimiko fẹ du ipo sugbọn ẹgbẹ ni awọn ko fọwọsi erongba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Labour Party Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbe oselu awon osisẹ Naijiria ni Labour Party

Ayuba Waba to jẹ Aarẹ ẹgbẹ osise lo sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe adisọkan Mimiko ati tawọn ko papọ fun idi eyi,awọn ko le gba gẹgẹ bi oludije Aarẹ awọn.

''Ẹiyele Mimiko ba onile wa jẹ o ba wa mu,sugbọn nigba ti o di ọjọ iku nise ni o yẹri. Nigba ti wọn kọọ nibi to salọ,o wa fẹ pada si ẹgbẹ wa, Ko jọ rara''

Lọ́jọ́bọ̀ ni Mimiko kede pé òun yóò gbé àpótí ìbò láti di Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ́dún 2019 labẹ asia ẹgbẹ Labour Party.

Oríṣun àwòrán, @Segunmimiko

Àkọlé àwòrán,

Mimiko ni Gomina akọkọ to wole labẹ asia ẹgbẹ Labour Party lorileede Naijiria

Mimiko tó kúrò lẹ́gbẹ́ òṣèlú alátakò, PDP nínú oṣù kẹ́fà ọdún yìí láti dara pọ̀ mọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kéde ní ìlú Abuja.

Ó ní ìpinu òun láti padà sí ẹgbẹ́ oṣèlú LP jẹyọ látàrí èrèdí láti ṣe àgbéǹde àfojúsùn ńla fún gbàgede òṣèlú Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

Ọmọdé tó ń fi ọpọ́n àyò gba ipò