Davido: Bí ọjọ́ ìbí mi se ń súnmọ́lé, lẹ̀bùn olówó ńlá ń wọlé fún mi

Aago ọwọ ti wọn fun Davido bii ẹbun

Oríṣun àwòrán, davidoofficial

Bi o tilẹ́ jẹ pe ayẹyẹ ọjọ ibi ilu mọọka olorin taka-sufe ni, Davido si ku ranpẹ ko wọle de, sibẹ awọn ọrẹ, ẹbi, ara ati ojulumọ ti n fi ẹbun olowo iyebiye ransẹ si.

David Adeleke, taa mọ si Davido, kede ni oju opo ikansira ẹni Twitter rẹ pe ojo awọn ẹbun olowo nla lo n rọ le oun lori, ninu eyi taa ti ri aago ọwọ ati ẹgba ọrun lorisirisi.

Davido ni aago ọwọ, ti awọ rẹ jẹ alawọ funfun lo kọkọ wọle de, tawọn goolu ọrun naa si bẹrẹ si ni tẹle.

Ọjọ Kọkanlelogun Osu Kọkanla ni Davido maa n sami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, to si seese ki awọn ẹbun naa ti pọ ju eyi lọ, ti yoo ba fi di ọjọ naa.

Davido wọ́gilé òde eré rẹ̀ l'Ámẹ́ríkà nítorí NYSC

Gbajugbaja olorin takasufee nni, Davido ti wọgile ode ere rẹ lorilẹede Amẹrika lati lee wa pari eto ifinimọle agunbanirọ rẹ.

Ọwọ keji eto agunbanirọ orilẹede Naijiria fun ọdun 2018 yoo maa pari eto ifinimọle ni ọjọ aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan eleyi ti Davido si ti gbọdọ kopa nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, @iam_Davido

Àkọlé àwòrán,

Ile ya

Dandan lowo ori ni eto isinrulu fun awọn akẹkọ jade faisiti lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin to pari eto iforukọsilẹ rẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ni Davido ti fi ibudo ifinimọle wọn silẹ lati lọ gbaradi fun ode ere ti o ni lorilẹede Amẹrika.

Ni ọjọ ẹti ni Davido kede funrarẹ pe oun ti wọgile ode ere gbogbo ti oun ni nilẹ Amẹrika lati lee pada wale fun eto isinruulu naa.

Oríṣun àwòrán, @iam_Davido

"Nitori bi ọjọ eto agunbanirọ mi ati awọn ọjọ ode ere ni mo ni ti ṣe forigbari, mo ti wọgile awọn ode ere to ku funmi ni Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, @iam_Davido

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin to pari eto iforukọsilẹ rẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ni Davido ti fi ibudo ifinimọle wọn silẹ

"Gbogbo awọn to ti san owo iwọle ni a o da owo pada fun ni ibi gbogbo ti wọn ti sanwo.

"Mo tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn ololufẹ mi patapata; ṣugbọn mo ṣeleri ati kede awọn ọjọ tuntun fun Houston Dallas, Lọs Angeles ati San Fransisco."