Ìjọba Buhari: Orúkọ Adeọsun tún wà lórí òpó ayélujára lẹ́yìn tó fipò sílẹ̀

Kẹmi Adeọṣun n buwọlu iwe niwaju aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

"Iwe ofin ko sọ pe ki wọn maa lẹ orukọ eeyan kan mọ ipo kan ni pato"

Lẹyin ọjọ merindinlaadọta ti minisita eto inawo tẹlẹ ri, Kemi Adeọṣun kọwe f'ipo silẹ, orukọ rẹ si tun wa lori oju-opo ayelujara ijọba apapọ.

Koda, orukọ minisita ọrọ obinrin tẹlẹ ri, Aisha Alhassan, to kuro ninu ẹgbẹ APC ati gomina tuntun ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, to jẹ minisita fun idagbasoke ohun alumọọni naa wa nibẹ.

Adeọsun kọwe f'ipo silẹ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an, ọdun 2018 lori ẹsun pe o lo ayederu iwe-ẹri agunbanirọ.

O si fori le Ilẹ Gẹẹsi lọjọ keji to kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii minisita fun eto inanwo lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi

Ewu wo lo wa ninu ki iroyin to wa lori oju-opo ayelujara ti pẹ?

Onimọ nipa oju-opo ayelujara kan, Zainab Sule, sọ pe ''iroyin to ti pẹ maa n saaba wa lori oju-opo ayelujara ijọba nitori ''kii saaba ni ẹnikan gbogi ti o maa n bojuto o.''

Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe ninu ewu to wa nibẹ nipe ''awọn ti wọn ba bẹ lati ṣiṣẹ lori oju-opo naa le parọ ohun to wa nibẹ nigba kuugba.''

Gbogbo akitiyan wa lati ba minisita eto iroyin ati aṣa, Oloye Lai Mohammed sọrọ lo jasi pabo.

Ta ló lẹ̀bi ọ̀rọ̀ lórí awuyewuye ayédèrú ìwé ẹ̀rí NYSC Adeosun?

Ni aipẹ yii ni okiki kan pe ayederu iwe ẹri agunbanirọ ni minisita feto iṣuna fi wọ iṣẹ minisita; lẹyin o rẹyin ni arabinrin naa kọwe fipo silẹ lẹyin to kọ lẹta si aarẹ pe 'aimọ lo ṣe oun nipa ọrsọiwe ẹri naa nitori awọn ti oun fẹyinti lati ba oun gba iwe ẹri naa ni wọn gbẹyin b'ẹbọ jẹ.

Eyi lo mu ki ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria o maa beere ohun ti o ba eyi wa nitori kii ṣe ohun ikọkọ pe ki eeyan to de ipo ilu giga bẹẹ yoo la ọpọlọpọ iwadi ati ifọrọwanilẹnuwo kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun eeyan bii Kẹmi Adeọṣun to ti fi igba kan ri ṣe kọmiṣọna ni ipinlẹ abinibi rẹ, iyẹn ipinlẹ Ogun ki o to wa di minisita, o fihan pe igba meji ọtọọtọ lo ti la irufẹ awọn igbesẹ iwadi bẹẹ kọja.

Idi niyi ti BBC Yoruba fi kanlu agbami itọpinpin lori ohun gan ti awọn aṣofin maa n wo ki wọn to gba eniyan kan sipo ilu.

Aṣofin Babatunde Ọlatunji to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin ni ipinlẹ Ọṣun, to si tun jẹ alaga igbimọ to n mojuto karakata nile aṣofin naa ṣalaye pe ohun marun lo ṣe koko.

Oríṣun àwòrán, @nassnigeria

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n pariwo lori ohun to faa ti aṣiri ayederu iwe ẹri agunbanirọ minisita feto iṣuna tẹlẹ ṣẹṣẹ n foju han.

Kikun oju iwọn ẹni ti wọn yan:

"Iwe ofin ko sọ pe ki wọn maa lẹ orukọ eeyan kan mọ ipo kan ni pato. Nitorinaa, ohun akọkọ ti a maa n wo ni pe ṣe irufẹ ẹni bẹẹ nikun oju iwọn ati di eyikeyi ninu ipo ilu mu lorilẹede Naijiria."

Ifẹ orilẹede tabi ipinlẹ ti o fẹ yan an: O ni ohun keji ti awọn aṣofin maa n wo ni ṣe ẹni ti wọn fi orukọ rẹ ranṣẹ ni ifẹ ilẹ rẹ denudenu. Ṣe kii ṣe ẹni ti yoo joko si ipo eku maa huwa ẹyẹ.

Ẹmi adari tabi aṣiwaju:

Ohun miran ti awọn aṣofin tun maa n wo ni boya ẹmi adari wa lara ẹni ti wọn fẹ yan sipo naa.

Oríṣun àwòrán, @nassnigeria

Àkọlé àwòrán,

"Ẹrẹ naa kanawọn aṣofin apapọ ti wọn ṣe ayẹwo fun"

Ayẹwo ipilẹ ẹni bẹẹ:

"Lara awọn ohun ti a n wo ni ayẹwo ti awọn agbofinro ba ṣe lori ẹni bẹẹ. Awọn ileeṣẹ agbofinro bii DSS ni o maa n saba ṣe eleyii."

Idi eyi ni lati rii pe awọn eeyan ti wọn jẹ ọdaran ko bọ si ipo ọṣelu.

Ayẹwo iwe ẹri: o ni ohun ti o tun ṣe pataki ni lati mọ boya lootọ ni awọn eeyan yii ni iwe ẹri ti o fi ṣọwọ si wọn.

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán,

Ayẹwo wa lati rii pe awọn eeyan ti wọn jẹ ọdaran ko bọ si ipo ọṣelu.

Ṣugbọn Aṣofin Babatunde Ọlatunji ṣai m'ẹnu ba awọn ipenija ti o maa n waye lori awọn igbesẹ wọnyii paapaa gbedeke asiko ti o maa n wa fun eto naa eleyi ti kii ba iwadi iwe ẹri d'ọrẹ nitori gẹgẹ bii ọrọ rẹ, " ọpọ igba lo jẹ pe bi ẹ ba kọ iwe si awọn ileewe ti awọn eeyan wọnyii lawọn ti gba iwe ẹri, ko ni si idahun lasiko, eleyi si maa n ṣe ipenija tirẹ pẹlu."

O ni sibẹ eyi ko wẹ ile aṣofin mọ bi irufẹ ohun to ṣẹlẹ si Minisita yii ba ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, @nassnigeria

Àkọlé àwòrán,

Ojuṣe awọ̀n agbofinro ni lati ṣe iwadi ipilẹ ẹni to fẹ di ipo ilu mu

O ni lootọ ọpọ igba lawọn aṣofin maa n nii lskan pe ko si bi ẹni ti wọn pe fun ipo to gaa lawujọ lee wa lai ni awọn iwe ẹri to yẹ, ṣugbọn nitori ki ọrọ o ma baa ba ẹyin yọ ni eyi ṣe pọn dandan.

Amọṣa, o ni ohun to ṣẹlẹ lori ọrọ minisita tẹlẹ Kẹmi Adeọṣun jẹ ohun to ku diẹ kaa to ṣugbọn to jẹ pe laifọta pe abawọn nla lo jẹ fun ile aṣofin apapọ orilẹede Naijiria.

Níbo ni Kemi Adeosun wà?

Oríṣun àwòrán, @HMKemiAdeosun

Àkọlé àwòrán,

Kemi Adeosun

Lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìròyìn abẹ́lé ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni ó ti jáde wí pé mínísítà àná fún ètò ìsúná, Kemi Adeosun ti rìnrìnàjò jáde kúrò lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Onírúurú ilé iṣẹ́ ìròyìn ló jábọ̀ láti pápákọ̀ òfurufú wí pé o ti tẹkọ̀ òfurufú létílọ sí London.

Wọ́n ni gbogbo akitiyan láti bá olùgbaninímọ̀ràn rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó kan ìròyìn, Oluyinka Akintunde sọ̀rọ̀ lórí èyí, pàbó ló já sí.

Bákan náà ni agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú British Airways tí àwọn akọ̀ròyìn abẹ́lé ni Nàìjíríà sọ pé ó bá rìnrìnàjò, Yinka Kola sọ pé òun kò ní lè pèsè ìròyìn kankan fún wọn ''nítorí àṣírí ni ohunkóhun tí gbogbo oníbarà wọn bá ṣe jẹ́ sí oníbarà tìkárarẹ̀".

Lọjọ ẹti ni okiki kan pe Kẹmi Adeọṣun kọwe fipo minisita feto iṣuna silẹ lori ẹsun ayederu iwe ẹri ti wọn fi kan an.

PDP pè fún fífi Kemi Adeosun jófin

Lẹyin ti minisita feto iṣuna, Kẹmi Adeọṣun kọwe fipo silẹ lọjọ ẹti lori ẹsun ayederu iwe ẹri agunbanirọ rẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Naijiria ti beere fun fifi minisita naa jofin lori ẹsun ko ṣe eto isinruulu NYSC rẹ ti o si tun lọ lo ayederu iwe ẹri fun.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita ni ọjọ abamẹta, ẹgbẹ oṣelu naa ni o ti lu si awọn lọwọ pe ijọba apapọ ti n gbero ati fi oru boju gbe Kẹmi Adeọṣun kuro lorilẹede Naijiria lọ si oke okun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP ni ọrun aarẹ Buhari ni ẹbi ẹsun gbogbo ti wọn fi kan Adeọṣun wa nitori, gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu naa ṣe sọ, Buhari ni anfani si gbogbo awọn iwadi lori iwe ẹri rẹ lai ṣe ohun to tọ sii.

"Ẹgbẹ oṣelu PDP wa pe fun iwadi iṣẹ ileeṣẹ eto iṣuna apapọ orilẹede Naijiria lasiko ti Kẹmi Adeọṣun fi jẹ minisita nibẹ lati lee ṣawari awọn iwa kots ti awọn agbẹyinbẹbọjẹ to wa ni iṣejọba aarẹ Buhari n ṣe titi to fi kan kiko owo epo rọbi sapo ara wọn pẹlu adinku owo to wa ninu aṣuwọn apapọ orilẹede yii nilẹ okeere"

Oríṣun àwòrán, @FinMinNigeria

Àkọlé àwòrán,

Adeọṣun pada sọrọ lori ẹsun ayederu iwe ẹri isinruulu NYSC ti wọn fi kan

Kemi Adeosun: Ìdí tí mo fi kọ̀wé fipòsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi mínísítà fétò ìṣúná

Lẹyin nnkan bi osu meji ti awuyewuye lori ẹsun ayederu iwe ẹri isinruulu NYSC ti wọn fi kan an ti n ja ranyin ranyin,Minisita fun feto iṣuna lorilẹede Naijiria,Kemi Adeosun ti kọwe fi ipo silẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle gbogbo lorilẹede Naijiria ni wọn ti saaju gbe e sita lọsan ọjọ ẹti pe minisita Adeosun ti kowe fipo sile.

Sugbọn nigba ti yoo fi di asalẹ ọjọ ẹti ni o fi ikede soju opo Twitter ti ile ise Aarẹ Naijiria naa si kede ifiposilẹ rẹ

Adeosun ninu iwe ifiposilẹ rẹ loun dupe lọwọ Aarẹ Buhari fun anfaani ti o fun oun l;ati di ipo mu ninu ijọba rẹ.

O salaye pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe iwe ẹri ayederu ni oun gbe ka ati wi pe oun ko mọ wi pe ọna eru ni wọn fi ba oun gba.

Ikowefiposile rẹ ko ya ọpọ eeyan lẹnu nitori awọn ara ilu ti n farata lati igba ti iroyin lu jade pe iwe ẹri ayederu ni o n lo.

Ki lo mu papa fipo silẹ?

Ohun ti awọn ileeṣẹ iroyin abẹle lorilẹede Naijiria kan n gbe kaakiri bayii ni pe, minisita Adeọṣun kọwe fi ipo silẹ ki ọrọ ẹsun ayederu iwe ẹri isinruulu NYSC ti wọn fi kan an ma baa pagi dina erongba ati pada sipo aarẹ lẹẹkeji eleyi ti aarẹ Buhari n gba fun ọdun 2019.

Awọn kan pẹlu ni boya o fẹ lọ du ipo gomina ni ipinlẹ rẹ, iyẹn ipinlẹ Ogun lati gba ọpa aṣẹ lọwọ Gomina Amosun ti yoo pari saa keji rẹ ni ọdun to n bọ ni.

Kini awọn ọmọ Naijiria n sọ

Oju opo ayelujara gbana jẹ pẹlu ikede yi ti awọn ọmọ Naijiria si n sọ iriwisi ọtọọtọ.

Awon kan kaanu rẹ pẹlu isẹlẹ naa ti wọn si ni ki ijọba forijin fun ẹsẹ pe o lo ayederu iwe.

Sugbọn lọdọ awọn kan, ohun to jẹ lo yoo ti wọn si ni ijiya tọ si

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, @HMKemiAdeosun

Àkọlé àwòrán,

Awọn kan ni boya o fẹ lọ du ipo gomina ni ipinlẹ rẹ ipinlẹ Ogun ni

Bi a ko ba ni gbagbe, ileeṣẹ iroyin Premium Times lo kọkọ gbee sita pe lẹyin ti awọn ṣe iwadi lori iwe ẹri ti Adeọṣun n gbe kiri fun eto isinruulu rẹ lawọn kẹẹfin pe ayederu gbaa ni.

Titi di igba to wa kowe fipo silẹ, Adeọṣun ko sọrọ lori rẹ.

Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati fi idi ọrọ ọhun mulẹ nigba ti o sẹlẹ lo n ja si pabo pẹlu bi ko ṣe si ẹnikẹni ni ijọba ti a kan si, tabi minisita naa fun ara rẹ to fẹ sọrọ lori rẹ.

Ṣugbọn iroyin kan pẹlu tun n sọ ọ pe eeyan kan lati ileeṣẹ aarẹ ni kii ṣe ootọ.

Ileeṣẹ aarẹ ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ yii bẹẹ ni igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria pẹlu.