Buhari: Àìsí ìtọ́jú tó péye ló mú ṣọ́jà gba iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe láwùjọ

Buhari n ki awọn ọga ileeṣẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni awọn ọlọpaa yoo tubọ tẹpa mọ iṣẹ wọn

Idunnu ti ṣubu lu ayọ fun awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria lẹyin ti iroyin kan sita ni ọjọ aje pe Aarẹ Buhari ti buwọlu owo oṣu tuntun fun awọn ọlọpaa.

O ti to ọjọ mẹta ti ọrọ naa ti n ja ranyin ṣugbọn ẹnikankan ko ti lẹ́ sọ pato boya ootọ ni.

Amọ ṣa abẹwo awọn igbimọ alakoso ajọ to n ṣe amojuto ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria to lọ ki aarẹ lati dupẹ lọwọ rẹ fun igbesẹ naa lo jẹ ki awo ọrọ yii lu sita.

Labẹ eto ẹkunwo oṣu tuntun ti Buhari fọwọ si yii, owo oṣu, ajẹmọnu ati owo ifẹyinti awọn ọlọpaa ni yoo gbẹnusoke.

Lasiko abẹwo naa, Aarẹ Buhari ṣalaye pe aisi amojuto to peye fun awọn ọlọpaa lo fa aijafafa wọn lẹnu iṣẹ wọn eyi ti o ni o mu ki awọn ologun maa ti oju bọ iṣẹ amojuto ofin ati abo laarin ilu jakejado orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Buhari ní ìjáfáfá ọlọ́pàá yóò fún ìjọba àti aráàlú ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó kúnná

'lati Taraba de Sokoto, de ẹkun aringbungbun gusu orilẹede yii, ọkan ọpọlọpọ araalu kii balẹ ayafi ti wọn ba ri awọn ologun. Inu mi dun lati buwọlu ẹkunwo oṣu naa pẹlu ireti pe yoo mu ki ijafafa awọn ọlọpaa o lọ siwaju sii."

Kí ló ń fa ikùn yíyọ láàárín àwọn ọlọ́pàá?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alhaji Smith ni ai kii ṣe ere idaraya deede lo faa ti awọn ọlọpaa fi n yọkun ayọju

Ni aye atijọ gẹgẹ awọn agba ilẹ yii ṣe sọ, o ṣoro lati ri agbofin to yọ ikun ni igboro.

Amọṣa ni bayii awọn ọyọkun agbofinro ti di tọrọ-fọnkale, eleyi to si da bi ẹnipe o n kọ awọn adari ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lominu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibayii, ajọ to n mojuto akoso ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ti ke gbajare sita pe 'ọyọkun ọlọpaa ti pọju nigbeoro.

Ajọ naa ti wa fi ikilọ sita pe ki awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa lati tete lọ wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ọgọrọ ọlọpaa to yọkun nigboro Naijiria bayii.

Alaga ajọ naa, Alhaji Musiliu Smith lo paṣẹ yii.

Kini awọn ohun miran ti ajọ to n mojuto akoso ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria tun yọ sita fun amojuto?

Gbogbo ọlọpaa lo gbọdọ le wa ọkọ pẹlu iwe aṣẹ iwakọ to pe.

Titun gbogbo ileegbe awọn ọlọpaa kọ ni ibamu pẹlu ilana igbalode.

Ṣiṣe aṣọ iṣẹ awọn ọlọpaa ni oju kan naa.

Alhaji Smith ni ai kii ṣe ere idaraya deede lo faa ti awọn ọlọpaa fi n yọkun ayọju.

Bakanna ni ajọ naa ninu atẹjade rẹ tun kọminu lori bi awọn ọlọpaa ṣe n ko awọn to wa lẹka akanṣe iṣẹ si ẹnu iṣẹ ọlọpaa igboro laiko fi ti eto ati ilana gbogbo to yẹ ṣe?

Bakan naa ni Alhaji Smith, ti oun pẹlu ti fi igbakan ri jẹ ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria tun ni ko si aaye fun ọlọpaa lati gba igbega lẹnu iṣẹ lai jẹ pe o ṣe awọn idanwo gbogbo to ba yẹ.