Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ́ àwọn ajókùúgbé mọ́túárì

Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ́ àwọn ajókùúgbé mọ́túárì Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ́ àwọn ajókùúgbé mọ́túárì

Àwọn Ọlọ́pàá ti mú ọkùnrin méjì kan ti ń bèèrè owó ìtanràn mílíọ̀nù mẹ́rin náírà kí wọ́n tó dá òkú tí wọ́n jí gbé ní mọ́ṣúárì padà.

Àwọn ẹbí olókùú ti ń múra láti sin òkú wọ́n nígbà tí àwọn ajínigbé yìí ṣe ọṣẹ́.

Òkú Kofi Annan balẹ̀ sí Ghana

Àyẹ̀wò DNA bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìjàmbá iná Eko

Sallah vs Kane, tani yóò pegedé?

Ni ọjọ́ ẹtì ni àwọn Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo sọ wí pé lóòtọ́ ni ọwọ́ ti tẹ àwọn ọ̀daràn náà tó lọ jí òkú arábìnrin kan gbé ní mọ́ṣúárì nílùú Owerri.

Wọ́n ni ṣe ni àwọn ajínigbé ọ̀hún gbé òkú arábìnrin yìí wọ inú igbó lọ tí wọ́n sì blrl sí ní da àwọn ẹbí olóku àti ilé ìwòsàn tó ni mọ́ṣúárì láàmú pé kí wọ́n san mílíọ̀nù mẹ́rin náírà kí àwọn tó gbé òkú náà sílẹ̀.

Andrew Enwerem tó jẹ́ alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo sọ fún ile iṣẹ́ BBC Igbo pé nígbà tí wàhálà wọn pọ̀ ni àwọn bí olóku wá fi ẹjọ́ sun Ọlọ́pàá lẹ́yìn náà ni ọwọ́ sì tẹ̀ wọ́n.

Ó ní àwọn afurasí méjèèjì ti jẹ́ èrò ọgbà ẹ̀wọ̀n rí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà àti mẹ́rìnlá lẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìjínigbé.

Ọ̀gbẹ́ni Andrew ní Ọlọ́pàá ti dá òkú padà fún ẹbí rẹ̀ láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìsìnkú tí wọ́n ti dájọ́ sí tẹ́lẹ̀.

Ìròyìn tó tẹ̀ wa lọ́wọ́ ni pé arábìnrin tí wọ́n jí òkú rẹ̀ gbé yìí kò fíbẹ́ẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'

Related Topics