ICPC: Ìwádìí ti pari lóri iwe ẹ̀ri ayéderú Kemi Adeosun

Image copyright @HMKemiAdeosun
Àkọlé àwòrán Kemi Adeọṣun kọwe fipo rẹ silẹ

Àjọ tó ń ri sí ìwá ajẹbanu àti jẹgúdújẹrá lórílẹ̀-èdè Nàìjiríà (ICPC) ní òun kò ṣe ìwadìí mọ lóri ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí NYSC ayédèrú tí ó fa awuyewuye fun mínísítà owó àti ìsuná Kemi Adeosun.

Àjọ ICPC sọ èyí di mímọ̀ ní kété tí àjọ tó ń ri sí ètò ìsinrú ìlú baba ẹni sọ pé òun ti pari ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà tí ó si ti fi àbájáde rẹ̀ sọwọ́ sí ilé iṣẹ́ tó ń ri sí ìdàgbàsokè ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Decides: Adegoke ni òun kò ni lo kọngilá n

Kẹmi Adeọṣun kọwe fipo rẹ silẹ

Mínísítà tẹ́lẹ̀rí kòwé fipò sílẹ̀ lọ́jọ Etì lẹ̀yìn tó gbà pé ayédèrú ní ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀ ti òun ní.

@officialkemiAdeosun
Àkọlé àwòrán ICPC: Ìwádìí ti pari lóri iwe ẹ̀ri ayéderun Kemi Adeosun

Agbẹnusọ fún ICPC, Rasheedat Okoduwa sọ̀rọ̀ sàlàyé pé àwọn dáwọ́ ìwádìí náà dúro kó máa dí ọ̀nà méjì.

Tẹ́ ò bá gbàgbé àjọ agùnbánirọ̀ sọ nínú oṣù keje pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tí adarí ẹka igbọ́rọ̀ sáfẹ́fẹ́ àjọ náà Adenike Adeyemi si sọ pé abájade ìwádìí náà ti wa ní ile iṣk ọ̀dọ́.

PDP: Kẹmi Adeosun gbọ́dọ̀ fojú winá lórí ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí NYSC rẹ̀

Kemi Adeosun Image copyright @HMKemiAdeosun
Àkọlé àwòrán Kẹmi Adeọṣun kọwe fipo minisita feto iṣuna silẹ lori ẹsun ayederu iwe ẹri ti wọn fi kan an

Lẹyin ti minisita feto iṣuna, Kẹmi Adeọṣun kọwe fipo silẹ lọjọ ẹti lori ẹsun ayederu iwe ẹri agunbanirọ rẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Naijiria ti beere fun fifi minisita naa jofin lori ẹsun ko ṣe eto isinruulu NYSC rẹ ti o si tun lọ lo ayederu iwe ẹri fun.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita ni ọjọ abamẹta, ẹgbẹ oṣelu naa ni o ti lu si awọn lọwọ pe ijọba apapọ ti n gbero ati fi oru boju gbe Kẹmi Adeọṣun kuro lorilẹede Naijiria lọ si oke okun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP ni ọrun aarẹ Buhari ni ẹbi ẹsun gbogbo ti wọn fi kan Adeọṣun wa nitori, gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu naa ṣe sọ, Buhari ni anfani si gbogbo awọn iwadi lori iwe ẹri rẹ lai ṣe ohun to tọ sii.

"Ẹgbẹ oṣelu PDP wa pe fun iwadi iṣẹ ileeṣẹ eto iṣuna apapọ orilẹede Naijiria lasiko ti Kẹmi Adeọṣun fi jẹ minisita nibẹ lati lee ṣawari awọn iwa kots ti awọn agbẹyinbẹbọjẹ to wa ni iṣejọba aarẹ Buhari n ṣe titi to fi kan kiko owo epo rọbi sapo ara wọn pẹlu adinku owo to wa ninu aṣuwọn apapọ orilẹ-ede yii nilẹ okeere"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́