BBC OSUN DEBATE: Àwọn olùdíje sípò gomina sọ̀rọ̀ lórí ètò Èkọ́

Àwọn oludije

Awọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Ọsun fi erongba wọn han lori ọna abayọ siṣoro eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọsun.

Awọn oludije lati ẹgbẹ oselu APC, ADP, ADC ati SDP fi ero wọn han lasiko ipade itagbangba ti Ile-Ise Iroyin BBC News Yoruba gbe kalẹ saaju ọjọ idibo si ipo goimna ti yoo waye ni Ọjọ Kejilelogun, Osu yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun 2018: Àwọn olùdíje ADC, ADP, APC, SDP bá aráàlú sọ̀rọ̀ lórí èròǹgbà wọn

Eto ipade itagbangba naa waye ni gbongan Olagunsoye Oyinlọla ni fasiti ipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an.

Àkọlé àwòrán Alhaji Gboyega Oyetola ni gbese daa, ti a ba mọ nkan ti a fi ṣe

Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, Alhaji Gboyega Oyetola lasiko to n fesi si ibeere nipa eto ẹko to da ẹnu kọlẹ ni ipinlẹ Osun, ni wi pe ijọba to wa ni ipo lọwọlọwọ n gbiyanju lati mu ibugbooro ba eto ẹkọ ati pe o ti dara si i ju ti atẹyinwa lọ. O ni ijọba ṣẹṣẹ san owo fun ile iwe giga Ladoke Akintola University ni Ogbomosọ laipẹ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́

Ninu ọrọ ti rẹ, oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu ADC, Fatai Akinbade ni awọn yoo da ogo ipinlẹ Osun pada nipa mimu eto ẹkọ lọkunkundun. O mẹnuba ohun tó ni lọkan lati ṣe fun itẹsiwaju LAUTECH ki eto ẹkọ le dara sii ni Ọṣun.

INTERACTIVE Tap or click to interact

image
Moshood Olalekan Adeoti
Action Democratic Party (ADP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
 • A bí Moshood Olalekan Adeoti ni Ilú Ìwo, ijọba ibilẹ Iwo ní ìpínlẹ̀ Osun lọjọ́ kẹ́tàdínlogun oṣù kejì ọdún 1953
 • Ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ ní District Council Primary Schoollọdun 1959 àti Aipate Day School lọdun 1964, lẹ́yìn náà ló lọ ilé ìwé Grammer lọdun 1974
 • Moshood Adeoti gboyè ìmọ ìṣòwò láti Fasiti Benin lọdún 1984
 • Moshood Olalekan Adeoti jẹ alága ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance For Democracy 1998-2003, alága ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress 2006-2010 àti alága Action Congress of Nigeria ti alaga àkọkọ fún ẹgbk oselu APC 2010-2011
image
Isiaka Oyetola
All Progressives Congress (APC)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
 • Isiaka Adegboyega ti wọn bi ni ilu Iragbiji, ni ijọba ibilẹ Boripe ni ipinlẹ Ọsun.
 • Ọdun 1997 ni Oyetola ti darapọ mọ sise oselu, ati wipe o pẹlu awọn to da ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy AD silẹ ni ọdun 1998.
 • Biotilẹjẹpe ogun ọdun niyi ti Oyetọla ti n se oselu, igba akọkọ ni yii ti yoo ma a dije du ipo labẹ ẹgbẹ oselu kan kan.
 • Amọ, iroyin kan ni wipe oun ni ẹyinoju Alaga Ẹgbẹ Oselu APC, Asiwaju Ahmed Tinubu ati Gomina Ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola
image
Alhaji Fatai Akinbade
African Democratic Congress (ADC)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
 • O darapọ mọ ilẹeṣẹ ijọba Ipinlẹ Ọṣun nibi to ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹrindinlogun labẹ akoso ijọba oloogun mẹta ati ijọba alagbada Olagunsoye Oyinlọla.
 • Wọn yan Akinbade gẹgẹ bii akọwe ijọba Ipinlẹ Ọṣun nigba iṣakosi Olagunsoye Oyinlọla ni ọdun 2003.
 • O kede ipinnu rẹ lati gbe apoti ibo fun gomina ni ọdun 2010 laarin awọn oludije mẹrinla miiran, ṣugbọn ipinnu naa f'ori sanpọn.
 • Akinbade di oludije ẹgbẹ oṣelu ADC lẹyin ọsẹ meji to fi ẹgbẹ PDP silẹ.
image
Ademola Adeleke
People's Democratic Party (PDP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
 • A bí Ademola Jackson Adeleke Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù karún-un ọdún 1960 ní ìpínlẹ̀ Enugu ní ìdílé sínatọ̀ Raji Ayoola àti Nnena Esther Adeleke ní ìlú Ede
 • Ó lọ sí iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Methodist ní Surulere àti Nuwarudeen ní Ikire, bákan náà ló lọ iléèwé Seventh Day àti iléèwé Muslim Grammar ni ìlú Ede tí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa ìwádìí ọ̀daràn ní Jacksonville State University Alabama USA.
 • Ó jẹ́ adarí àgbà ní iléeṣẹ́ Pacific Holdings Limited láti 2001 sí 2006 àti Quicksilver Courier Company ní Atlanta, Georgia láti 1985 sí 1989
 • Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ òṣèlú ní ọdún 2007, ó sì dí sẹ́nétọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìwọ̀-oòrùn Oṣun lẹ̀yìn ikú ẹgbọn rẹ̀ sẹ́nétọ̀ Isiaka Adeleke tó jẹ́ Gomìnà alágbádá àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà
image
Senator Iyiola Omisore
Social Democratic Party (SDP)
Kíni ọjọ́ ìbí yin?
Iṣẹ́ wo ni ẹ̀ ń ṣe?
Ìkádìí
 • Wọ́n bí Iyiọla Ajani Omisore sí ìdílé ọba ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn án, ọdún 1957 ní ìlú Ilé-Ifẹ̀.
 • Omisore jẹ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun, Adebisi Akande láàrin ọdún 1999- 2003.
 • Wọ́n dìbò yàn án sí ipò sẹ́nétọ̀ láti ṣojú ẹkùn ìdìbò ìlà oòrùn Ọṣun l'ábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láàrin ọdún 2003 sí 2007, wọ́n tún padà dìbò yàn án ní 2007.
 • Ó díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun l'ọ́dún 2014 l'ábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, sùgbọ́n Rauf Aregbẹsọla fi ẹ̀yìn rẹ̀ janlẹ̀ nínú ètò ìdìbò nàá tó wáyé ní ọjọ́ kẹsàn án, oṣù Kẹjọ 2014.
Wo àwọn olùdíje
image
Ìkádìí
Àkọlé àwòrán Akinbade: ''Due Process'' ni awa yoo fi se ijọba

Akinbade ni Ile-iwe giga fasiti LAUTECH ti awọn olukọ ko ki n ye da isẹ silẹ nitori ijọba kò san owo oṣu wọn, sọ pe òun yoo rii daju pe wọn da eto ẹkọ pada si ipo to yẹ ki o wa.

Bakan naa, Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP, Moshood Adeoti ninu ọrọ tirẹ fikun wi pe eto ẹkọ se pataki o ṣe koko si ìjọba òun, ati pe ọna abayọ si isoro eto ẹkọ ni ipinlẹ Osun ni gbigba awọn olukọ to dangajia lati bu iyi kun eto ẹkọ lọna to yẹ. O ni ọrọ LAUTECH yoo jẹ afẹnuko ijọba ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun ni.

Àkọlé àwòrán Alhaji Adeoti

Ti a ko ba gbagbe, ni esi idanwo asekagba ile iwe girama WAEC ti wọn fi lede laipe yii, ipinlẹ Osun lo se ipo kọkandinlọgbọn ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji.

Awọn ohun miran ti awọn oludije naa sọrọ le lori ni itẹsiwaju ijọba, iyẹn Kọntínúítì, gbèsè ti ijoba ipinle osun jẹ ile ifowopamọsi banki agbaye, eto ẹkọ fásitì LAUTECH to dẹnu kole, eto ilera alabọde àti àwọn ìbéèrè mìíràn lo jẹyọ ní ìpàdé ìtagbangba Ọṣun.

Olúdíje ẹgbẹ òṣèlú PDP nikan ni kò yọjú síbi ìpàde ìta gbángba ninu gbogbo awọn oludije ti wọn kọwe pe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀rọ̀ Imam yìí ṣe kòńgẹ́ bó ti ń rí láàrin lọ́kọ láya