Èrò Akinbade, Oyetọla, Adeoti àti Omiṣore ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípinlẹ Ọṣun
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọṣun Decides: ADC, ADP, APC àti SDP soju abẹ níkòó lórí ìwà ìbàjẹ́

BBC Yorùbá ṣètò ìpàdé ìtagbangba fún marun un ninu àwọn oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ọṣun.

Awọn mẹrin to wa ni Alhaji Fatai Akinbade, Alhaji Gboyega Oyetọla, Alhaji Moshood Adeoti àti Senetọ Iyiola Omiṣore nigba ti a kò ri Senetọ Ademọla Adeleke.

Ọkan pataki lara àwọn koko ti BBC yan nàná pẹlu wọn ni ohun ti onikaluku ni lọkan fun gbigbogun ti ìwa jẹgudujẹra nipinlẹ Ọṣun.

Moshood Adeoti ADP

Moshood Adeoti ni oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP, o ni oun a ṣagbekalẹ igbimọ elétí gbáròyé kalẹ̀ ti yoo wa fun ijọba àti ẹlẹgbẹjẹgbẹ.

Fatai Akinbade ADC

Fatai Akinbade ti ADC ni oun yoo gbogun ti iwa ibajẹ yii ni nipa lilo 'Due Process' ninu ijọba ki aaye má si fun ole jija. O ni 'ẹni to ba jale ti pari iṣẹ rẹ pẹlu wa niyẹn'.

Gboyega Oyetọla APC

Gboyega Oyetola lo n dije lẹgbẹ oṣelu APC, o ṣalaye nibi ipade ijiroro naa pé ijọba wọn ni igbimọ ti wọn ṣagbekalẹ rẹ ti o n ṣayẹwo iye owó to n wọle finifini. O ni àwọn oṣiṣẹ ati ijọba ni wọn jọ wa nibẹ.

Iyiọla Omiṣore SDP

Iyiọla Omiṣore n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP, o ni ijọba òun ko ni jẹ ti Omiṣore bikoṣe ijọba to gba gbogbo eeyan laaye pẹlu ilana àátẹ̀lé fún idagbasoke.