Adeleke: 'Èmi ò kú o, koko lara mi le'
Èmi ò kú o
Ademọla Adeleke ti kede pe oun ko ku o lẹyin tim ọrọ kan ti tan kaakiri pe o ti jade laye.
Adeleke ni oludije ti 'Jackson' wa ninu inagijẹ rẹ, ti o si jẹ oludijẹ ti iwọle rẹ taara sinu agbami oselu orileede Naijiria waye lẹyin igba ti ẹgbọn rẹ papoda.
Senetọ Nurudeen Ademola Adeleke, ni oludije ipo Gomina labe asia ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP, ninu idibo Gomina ipinlẹ Osun .
Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook
Adeleke ni oludije ẹgbẹ òṣèlú PDP nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun
Ọdun ti orileede Naijiria gba ominira, 1960 ni wọn bi i ni ilu Enugu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni
Raji Ayoola baba rẹ jẹ Musulumi, ọmọ bibi ilu Ede nipinlẹ Osun, sugbọn mama rẹ Nnena Esther Adeleke jẹ ẹya Igbo, ti o si jẹ Kristẹni .
Koda Isiaka di ipo asofin agba to n soju ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Osun mu leemeji, ki ọlọjọ to de ni odun 2017.
Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Awọn amoye kan ni orukọ ẹgbọn Ademola, Isiaka Adeleke ko ipa ribibi bi o ti se di Sẹnẹtọ
Idile Oloselu ni Ademọla ti wa
Ti a ba so wi pe oselu jẹ nkan ti o n tọ iran Sẹnẹtọ Adeleke lẹyin, a ko j'ayopa.
Bẹrẹ lati ori baba rẹ, Ayoola Adeleke, to jẹ Sẹnẹtọ ni saa isejọba oselu ẹlẹkeji, ẹgbọn rẹ naa, Isiaka Adetunji Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si ''Sẹrubawọn'' jẹ Gomina akọkọ lẹyin ti wọn da ipinlẹ Osun silẹ.
Oríṣun àwòrán, Osun Defenders
Nipa eto ẹkọ rẹ, a ri akọsilẹ pe:
- Seneto Ademola Adeleke lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ niluEeko ati ile ẹkọ Nawarudeen nilu Ikire.
- O lọ si ile ẹkọ Girama Adventist Secondary ni Ede ati Muslim Grammar school feto ẹkọ Girama.
- Jacksonville ni Alabama lorileede Amerika lo ti kẹkọ nipa imọ eto ẹkọ nipa idajọ, iwadi iwa ọdaran ati eto oselu.
Abi ẹ n ro wi pe Jacksonville ni inagijẹ Jackson rẹ ti waye ni?
Irinajo Oselu rẹ
Lọdun 2017 ti ẹgbọn rẹ, Isiaka Adetunji ku, anfaani si silẹ fun Nurudeen Ademọla lati wọ agbami oselu taara.
O dije fun ipo asoju labe asia ẹgbẹ oselu PDP, lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ APC.
Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Ọmọ igbimọ ile asofin agba lori ọrọ idasẹsilẹ ati isẹ ilu ni Sẹnẹtọ Adeleke
Adeleke gbe igba oroke, ti o si jẹ asofin agba to n soju ni ile asofin agba labuja lọwọ-lọwọ yii.
Adeleke pegede gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oselu PDP ninu idije Gomina nipinlẹ Osun, lẹyin to fẹyin Akin Ogunbiyi janlẹ pẹlu ibo meje.
‘Dancing Senatọ’ni baba olorin Takasufe meji
Ti a ba ni ki a sọrọ nipa iriri rẹ nipa oselu, ko fẹ si ọrọ pupo ju wi pe, o bẹrẹ irinajo oselu pẹlu ẹgbọn rẹ, Isiaka Adeleke ni ọdun 2001.
Koda awọn to mọ ọ daada ni, Ademọla a maa saba tele ẹgbọn rẹ lo si ibi ipolongo oselu, ni ibi ti awọn to mọ ọ daada ni a ma fi ijo da ara.
Oríṣun àwòrán, @IAM_DAVIDO, @ISIAKAADELEKE1
Adeleke ni aburo baba gbajugbaja olorin Davido
O seese ko jẹ wi pe ibi ti inagijẹ rẹ ‘Dancing Sẹnẹtọ’ ti wa ye ree.
Adeleke jẹ aburo Baba gbajugbaja olorin takasufe, ti gbogbo aye mọ si Davido sugbọn se ẹ mọ wi pe, awọn ọmọ rẹ okunrin meji naa a ma kọ orin takasufe?
Sina Rambo ati B red lorukọ awọn ọmọ Ademọla mejeeji tawọn naa n kọ orin.
Oríṣun àwòrán, @iam_Davido
Ọmọ Adeleke T red jẹ olorin takasufe
Oríṣun àwòrán, @SINARAMBO
Orin kikọ jẹ atewọgba laarin awọn ọmọ okunrin mọlẹbi Adeleke
Ki a to gbagbe, onisowo ni Adeleke, ti o si ti fi igba kan jẹ oga ni ile ise Pacific Hoildings to jẹ́ ti ẹgbọn rẹ, laarin odun 2001 si 2016.
Saaju igba naa lo ti ba ile ise Quicksilver Courier Company lorileede America sisẹ gẹgẹ bi osisẹ́ fun igba ranpẹ.