Ìtàn Mánigbàgbé: Kuti ni akọni Obìnrin Ẹ̀gbá tó di àwòkọ́ṣe rere f'áwọn ọ̀dọ́bìnrin ìwòyí

Funmilayo Kuti

Oríṣun àwòrán, @NzekweGerald

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ju ọmọ lọ, agbára ju agbára lọ ni ọrọ Funmilayọ Kuti tí Ilééṣẹ́ Google ń ṣe ìrántí rẹ̀.

Ọmọ ju ọmọ lọ, agbára ju agbára lọ ni ọrọ Funmilayọ Kuti tí Ilééṣẹ́ Google ń ṣe ìrántí rẹ̀.

A bi Olufunmilayọ Frances Abigail Thomas ni ilu Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun, Naijiria ni ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1900.

Funmilayọ Ransome Kuti jẹ ọmọ iya aranṣọ àti agbẹ ti baba rẹ ti oko ẹru de ni ilẹ Saro.

Oríṣun àwòrán, @Ransome-Kuti

Àkọlé àwòrán,

Akọni obìnrin Olufunmilayọ Ransome-Kuti

Ọjọ kẹta, oṣù kinni, ọdún 1949 jẹ́ ọjọ́ málegbàgbé ni Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

Ọjọ yii ni pẹpẹyẹ pọnmọ, ti Oba Samuel Ladapọ Ademọla kejì kọwe fipo rẹ silẹ ni Ẹ̀gbá.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Funmilayọ gba agbára lọ́wọ́ Ọba Ladapọ Ademọla keji

Olufunmilayọ ni olori ẹgbe ìṣọ̀kan àwọn obinrin Ẹ̀gbá nigba naa. Oun lo ṣaaju ìwọ́de ti wọn ṣe lati fẹhonu han lori owo orí gọbọi àti ìyà ti wọn n jẹ lọwọ awọn Oyinbo Ajẹ́lẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣé ìwọ mọ̀ pé Funmilayọ Ransome- Kuti ni obìnrin àkọ́kọ́ ti...

  • Funmilayọ ni obìnrin akọkọ to wa ọkọ̀ ayọkẹlẹ ni Naijiria
  • Oun naa ni akikanju obinrin ti o di ìyá agba fun awọn èèkàn nla lasiko yii.
  • Lara Funmilayọ ni àwọn ọmọ ti talẹnti wọn kuro ni kèrémi ti jáde
  • Nínú wọn ni Olikoye Ransome-Kuti, to di minista fun eto ilera ni Naijiria, Fẹla Ransome-Kuti to jẹ ogbontarigi onkọrin Afrobeat ati Bẹkọ Ransome-Kuti to jẹ ajijangbara.
Àkọlé fídíò,

'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

  • Funmilayọ jẹ ọkan lara awọn obinrin to lagbara ju ni Naijiria nigba aye rẹ.
  • O jẹ ajijagbara fun ẹ̀tọ́ àwón obinrin lẹkun ìwọ̀ oorun ilẹ Adulawọ nigba naa.
  • Funmilayọ ni akẹkọbinrin akọkọ to lọ sile iwe Abẹokuta Grammar School.

Ta ni Olufunmilayọ Ransome-Kuti?

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1900 ni a bi Frances Abigail Olufunmilayọ Thomas sinu idile ti wọn fẹran ẹ̀kọ́ iwe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àwọn Ajẹ́lẹ̀ miran huwa kòtọ́ nilẹ alawọ dúdú.

Nigba ti o lọ sile iwe ni England, ni oju rẹ ṣi si bi àwọn oyinbo kan ṣe n huwa ìdẹ́yẹsí si àwọn alawọ dudu.

Eyi ni àwọn kan fi ro pe o jẹ ki o yọ orukọ oyinbo kuro lara orukọ rẹ, to fi n jẹ Olufunmilayọ nikan.

Àkọlé fídíò,

Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ

Kíni ó ṣokùnfà làásìgbò àti ẹ̀jẹ̀ nínu ìṣèlù?

Nigba ti Funmilayọ pada sile ni Naijiria, o rii pe, awọn oyinbo Ajẹlẹ ti n ṣiṣe ibi nipa gbigbe owó orí gọbọi le awọn eniyan lori.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Orí ń ta àwọn olokowo ni Naijiria

Ijọba ibilẹ ti Alake ti Ẹ̀gba n bojuto ni wọn n gba bu owó orí naa fawọn ọlọ́jà. Owó orí gọbọi lori ọjà yii pẹlu iwa ipá ti awọn agbofinro n lò lati fagidi mu awọn ọlọja, di ẹru nla lori awọn obinrin.

Bẹẹ, wọn ko fi aaye gba awọn obinrin lati da si ọrọ oṣelu, ko si ọna fun awọn obinrin lati gbe ọrọ wọn jade.

Eyi lo mu wọn forikori lati ṣe iwọde, eyi ti ẹgbẹ Iṣokan awọn obinrin Abẹokuta ṣaaju rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, @Ransome Kuti

Àkọlé àwòrán,

Agbara obinrin pọ̀

Ẹgbẹ́ Iṣọ̀kan àwọn obinrin Ẹ̀gbá

Funmilayọ Ransome-Kuti ati àbúrò ọkọ rẹ̀, Ẹniọla Ṣoyinka ( Iya Wọle Ṣoyinka), ni wọn jọ dá ẹgbẹ iṣọkan yii silẹ lati fi ja ija ominira awọn abo kuro lọwọ awọn Ajẹlẹ.

Ọkan Funmilayọ poruru nigba ti o gbọ ohun to n ṣelẹ sawọn obinrin Egba lọwọ awọn oṣiṣẹ Alake ati Ajẹlẹ ati pe, wọn n tún irẹsi ti wọn fagídí gbà lọwọ awọn obinrin tà, ti wọn n kowo rẹ sapo ara wọn.

Àkọlé fídíò,

Ìgbésí ayé àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyìí di ọ̀tun láti 2008

Eyi lo fi bẹrẹ iwọde ojoojumọ ṣe lodi si iwa Alake ati Ajẹlẹ yii. Ijọba n yin tajútajú fi tú wọn ka pẹlu kóńdó àti kùmọ̀ ni.

Gbogbo rẹ dé òtéńté nigba ti Funmilayọ kò san owó orí ara rẹ, ti wọn fi gbee lọ sile ẹjọ́ ti ọpọlọpọ awọn obinrin sì tẹle lọ lọdun 1947.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàámi ni Ẹ̀gbá, ominira dé f'awọn obinrin, Alake kọwe fipo rẹ silẹ

Kete tijọba ti mu Funmilayọ lori ẹsun pe kò san owó orí ara rẹ, ni awọn obinrin ti pe bo ilé ẹjọ naa.

Wọn kò gbé igi tabi kùmọ̀ rara. Wọn ṣe gẹgẹ bi awọn obinrin ilu Aba ṣe ṣe lọdun 1929, nigba ti wọn n ja pe owọ orí ti áwọn n san ti pọ̀ ju. Eyi kò jẹ ki o ṣeeṣe fawọn agbofinro lati kọlu wọn.

Oríṣun àwòrán, @Ransome-Kuti

Àkọlé àwòrán,

Awon obinrin Ẹ̀gbá fariga

Ọba Alake igba naa, Ọba Samuel Ladapọ Ademọla ati awọn Oyinbo Ajẹ́lẹ̀ gbogun ti aya Ransome-Kuti.

Wọn fi ofin dee pe kò gbọdọ wọ àfin mọ, wọn gbiyanju lati da aarin awọn oloye ẹgbẹ rú, ki wọn le rọ Kuti loye, ṣugbọn pàbó ló já sí.

Awọn obinrin naa fi aake kọri pe, a fi ti Alake ba kọwe fipo rẹ silẹ ni awọn yoo to dẹkun iwọde.

Àkọlé fídíò,

Ilu Ubang, jẹ ilu kan nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ifẹhonuhan, ni oṣu keje, ọdun 1948, ni awọn Oloye Ẹ̀gbá atawọn agbaagba ninu iṣelu gbe ofin sita, to fẹsun kan Alake pe o n huwa aitọ, to tun n ṣi agbara Ọba lò.

Wọn yọ Alake kuro nipo, wọn si lu ilu iyọkuro nipo fun un leyin ikede.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ti ọmọ ko ba jọ iya, aa jọ baba; Fẹla Anikulapo Kuti ba awọn iwa kan nile ni.

Alake fi orí oye rẹ silẹ, o tun fi Ẹ̀gbá silẹ. Awọn obinrin mẹrin pẹlu Olufunmilayọ Ransome-Kuti ni wọn yan si ara igbimọ ijọba ibilẹ, ti wọn si fi ofin de ki obinrin maa san owọ orí.

Funmilayọ tun tesiwaju lori ijajagbara fun ẹtọ awọn obinrin kaakiri ilẹ Adulawọ lọ si Ghana, Sierra-Leone ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Loṣu keji, ọdun 1978 ni wọn ju Funmilayọ Kuti lati oju ferese nile ọmọ rẹ Fela Anikulapo Kuti ni eyi to ja si aarẹ fun un.

Àkọlé fídíò,

'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Oṣu kẹrin, ọdun 1978 ni Funmilayọ jade laye.

Bi aladi ko ba si nile, ọmọ wọn nii jogun ẹbu ni Funmilayọ fi ọrọ ijajagbara rẹ ṣe, Awọn ọmọ rẹ bii Bẹkọ Ransome - Kuti ati Fẹla naa tẹsiwaju lori eyi ni, sé ọmọ ti ẹya ba bi, ẹya nii jọ.

Àkọlé fídíò,

Obinrin lo mu mi fẹran orin kikọ - Patoranking