NEMA: Ǹkan méje ló ń fa omíyale ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Kaduna

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipinle Niger, Kogi, Anambra ati Delta lo faragba julo.

Ọdọọdun ni òjò arọọda maa n waye ni orilẹ-ede Naijiria, ti ọpọlọpọ ile to wa leti omi si ma n faragba ninu isẹlẹ omiyale.

Ni ọdun 2019 yii, awọn eniyan to ti papoda ninu isẹlẹ omiyale to igba eniyan, ti ọgọọrọ si ti di alairile gbe.

Ajọ to n risi ọrọ ìsẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA, ni o ṣeeṣe ki iye awọn to faragba ninu isẹlẹ naa ti peleke sii pẹlu bi wọn ṣe kede ipinlẹ Niger, Kogi, Anambra ati Delta gẹgẹ bi ipinlẹ to faragba julo.

Ki lo máa n fa ijamba omiyale ni Naijiria?

Orilẹ-ede Naijiria lo ni odo meji to tobi julọ ni agbaye. River Niger to wa ni Iwọ-oorun ariwa ati River Benue tó n ṣan wa lati Ila oorun Cameroon.

Ajọ to n risi wiwo oju ọjọ, NIMET sọ pe ojo arọọrọda ọdọọdun maa n fa omiyale, agbara ya sọọbu.

Nkan miran to tun n fa omiyale ni isoro awọn adagun odo dáàmù pẹlu bi ojo arọọrọda se n jẹki awọn adagun odo to n mu ina ijọba wa fun awọn eniyan bii Kainji, Jebba ati Shiroro ru soke.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kainji dam

Bi awọn eniyan ṣe n kọ ile si oju omi naa jẹ ọkan lara awọn ohun to n fa ijamba omiyale nitori oju omi ko fẹ to lati jẹ ki omi raye kọja.

Ilu Lokoja jẹ ọkan lara awọn agbegbe to n lugbadi omiyale nitori aarin gbungun ọdọ River Benue ati Niger lo wa.

Bakan naa ni kikọ ile si awọn agbegbe ti ọdọ wa naa le fa ijamba omiyale ati agbara ya sọọbu.

Awọn elomiran a tun ma a da idoti si oju omi ati panti si oju odo, eyi ti o fa ki odo máa dagun ati ẹkun omi.

Osisẹ Ajọ to n risi ọrọ pajawiri naa, Hussaini Ibrahim, ni bi awọn eniyan se n bẹ igi ni igbo naa n se okunfa omiyale nitori igi maa n gba omi sara, sugbon awọn olugbe orilẹ-ede Naijria ma n bẹ igi ni igbo lati fi dana tabi ta a lati fi ko ile.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn elomiran a tun ma a da idoti si oju omi ati panti si odu odo, eyi ti o fa ki odo o ma dagun ati ẹkun omi.

Ọna abayọ si ijamba omiyale ni Naijiria

Ọna abayọ to jẹ gboogi si ọrọ omiyale lorilẹ-ede Naijria ni ki ajo to n risi ile kikọ máa bojuto ọna igbalode ti awọn eniyan n gba fi kọ ile, ki wọn dawọ lati maa ko ile si oju agbara tabi eti odo.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

NEMA: Ǹkan méje ló ń fa omíyale ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Bakan naa, ijọba Naijria gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn orilẹ-ede to wa layika wọn, lati le fi aye gba ki omi o lo bi o se yẹ, ki awọn adagunodo maṣe ru soke ju bi o ti yẹ lọ.

Amọ, awọn onimọ nipa oju ọjọ ti wi pe ojo arọọrọda ni se pẹlu bi oju ọjọ se n yipada (climate change).

Àkọlé fídíò,

Painter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!