Osun Election Results 2018: Adeleke ní òun yóò gba ipò gómìnà padà, ó sì rí bẹ́ẹ̀

Osun Election Results 2018: Adeleke ní òun yóò gba ipò gómìnà padà, ó sì rí bẹ́ẹ̀

Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun, Ademọla Adeleke, ti ilé ẹjọ́ ti kéde pe oun lo gbe igba oroke ninu idibo gomina Oṣun to kọja se apejuwe bo se fidi rẹmi ninu eto idibo naa gẹgẹ bii ifasẹyin ranpẹ, eyi ti yoo ni atunse laipẹ.

Ademọla Adeleke, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ to wa ni Ẹdẹ, tun fikun pe, ẹgbẹ oselu oun, PDP, yoo lo gbogbo agbara ofin to ba wa nikawọ rẹ lati gba ipo rẹ ti wọn ‘ji gbe’ pada.

O fikun pe "Ẹgbẹ oselu to n se ijọba lọwọ mọọmọ fi tipa-tipa gbe ifẹ ọkan wọn le awọn araalu lori ni, pẹlu bo se ko awọn janduku lati awọn ipinlẹ miran wa dunkoko mọ awọn araalu atawọn akọroyin."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: