Àwọn amọkòkò kò fẹ́ fi iṣẹ lé ọmọ lọ́wọ́ mọ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Juweratu Yunusa: Wọ́n bí iṣẹ́ yìí mọ́ wa ni

Orin, ẹrin ati ayọ láwọn amọkoko adugbo Dada Okelele nilu Ilorin n fi ṣiṣẹ wọn

Àwọn obìnrin tó n mọ ikoko wọnyi tí n ṣé iṣẹ yí láti ọdún tó tí pé.

Àwọn obìnrin nikan ló má n ṣé iṣẹ yí ti ọpọ nínú wọn si bá a lówó iya wọn

Káàkiri ìgbèríko àti àwọn ilu to sunmọ Kwara ni wọn ti n lo awọn koko wọn yí

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ọọnirisa pa àwọn aṣàtìpó lẹ́rin ayọ̀ ni Ibùdó Wasa

'Ẹni tí yóò tún ìtàn Eko kọ ló yẹ fún gómìnà'

Àwọn tó mọ rírí koko wọn yí ni anfààní púpọ̀ wa lára wọn

Pẹlú bí wọn ti ṣe rẹwa tó, owó ṣipini láwọn amọkoko náà má n ri gẹgẹ bi ere

Èyí mú kí ọpọ nínú wọn má ṣe fẹ kí àwọn ọmọ wọn jogun iṣẹ náà lọwọ wọn.

Ṣugbọn awọn ọmọ wọn kan ní ìrètí pé agbega lè dé bá iṣẹ ọnà adayeba yí lọjọ iwaju