Obìnrin míràn gbẹ́mi mi torí pé o fẹ́ ki ìdí òun tóbi síi

Ìdí ti kò tẹ́ àwọn obìnrin lọ́rùn ń jẹ́ ki iṣẹ́ abẹ rán wọn sọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìdí ti kò tẹ́ àwọn obìnrin lọ́rùn ń jẹ́ ki iṣẹ́ abẹ rán wọn sọrun.

Ìdí ti kò tẹ́ àwọn obìnrin lọ́rùn ń jẹ́ ki iṣẹ́ abẹ rán wọn sọrun.

Àjọ àwọn oniṣegun fun iṣẹ abẹ atunṣe agọ ara nilẹ Gẹẹsi, British Association of Aesthetic Plastic Surgeons (Baaps) ti fi ikede sita pẹ ki awọn obinrin ṣọra fun iṣẹ abẹ ikebe nla nitori pe o léwu pupọ.

Wọn ke gbajare yii lẹyin iku ọmọbinrin ilẹ Gẹẹsi kan to lọ ṣe iṣe abẹ naa to si gabẹ re ọrun aremabọ.

Àkọlé fídíò,

'Oúnjẹ ibìkan jẹ́ èèwọ̀ ibòmíì ni ọ̀rọ̀ ọmú ńlá'

Awọn gbajugbaja ilumọọka adanilaraya ni wọn saaba n ṣee ti o fi n di itẹwọgba kaakiri agbaye bayii.

Losu kẹjọ ni Leah Cambridge to jẹ ọmọ Turkey doloogbe lataari iṣẹ abẹ idi ni eyi to dẹmi ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn naa legbodo.

Àkọlé fídíò,

Àwa obìnrin tó ń lépa afòjúsùn máa n ba ọkùnrin lẹ́rù ni -Toyin Lawani

Orilẹ-ede Brazil lo ti lọ ṣe iṣe abẹ naa ni eyi ti àwọn dokita gba imọran pe ki wọn ṣọra fún iṣẹ abẹ lọwọ awọn ti kò koju oṣuwọn tó.

Ìṣẹ abẹ ikebe nla ti Brazil (BBL) jẹ ọkan lara awọn ọna ti awọn obinrin fi n ṣafikun ẹwa ẹya ara paapaa idi wọn ko lè tobi sii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ilẹ̀ Gẹẹsi gbẹ́mi mi torí pé o fẹ́ ki ìdí òun tóbi síi

Baaps ṣalaye fun Victoria Derbyshire ti BBC pe o keere tan, ẹni kan ninu ẹgbẹrun mẹta lo n ku lagbaye lataari nkan to n tẹyin iṣẹ abẹ naa jade.

Iwadii BBC fihan pé ọmọbinrin Gẹẹsi mii ku latari iṣẹ abẹ naa.

Victoria Derbyshire tún ṣe ìwàdìí pé obìnrin ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì mii tó ku díẹ̀ kó tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún naa tun ku ni eyi ti ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ lórí ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Àkọlé fídíò,

'Obinrin jẹ amuludun'

Gerard Lambe. to jẹ oniṣegun oyinbo lori atunṣe ẹwà sọ pe ohun ni iṣẹ abẹ to lewu jú, nítorí àwọn àbẹ́rẹ́ tí wọn máà ń lò lati fa ọ̀rá sí inú iṣan tó wà nínú ìkébè a máa rìnrìn àjò lọ sí inú ọkàn tàbí inú ọpọlọ.

Obinrin ilẹ Gẹẹsi kan ni oun ṣe iṣẹ abẹ toun ni Turkey lọdun meji sẹyin nitori pe, o dinwo ni Turkey daadaa.

O ni iṣẹju mẹwaa ṣaaju iṣẹ abẹ naa loun to foju kan dokita to fẹ ṣee fun oun ati pe, oun ṣaisan lẹyin ti oun ṣee tan ki oun to pada lọ si UK fun itọju to peye.

Ms Palmer-Hughes ni o le ni idaji awọn onibara oun ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ ikebe nla yii ni orilẹ-ede bii Turkey, Hungary, Belgium ati Spain.