Gbenga Daniel: Onímọ̀ ọrọ̀ ajé tó dáńtọ́ àti ọ̀dọ́ ni Peter Obi ló se kájúẹ̀

Image copyright @Demolalanrewaju

Oludari agba feto ipolongo ibo aarẹ fun Atiku Abubakar, Ọtunba Gbenga Daniel, ti salaye ọpọ ohun amuyẹ ti wọn ri lara gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹri, Peter Obi, ki wọn to ni oun lo kajuẹ lati ba Atiku dije gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ninu eto idibo to n bọ ni 2019.

Gẹgẹ bi Daniel ti wi ninu atẹjade kan to fi sita, ika to ba tọ simu, la fi n re imu, Obi ti jẹ gomina ri, to si tun jẹ́ alaga tẹlẹ fun banki fidelity. Koda, ọdọ to jẹ ọlọpọlọ pipe ni, to si tun ni imọ pipe nipa eto ọrọ aje labẹle ati lagbaye.

O fikun pe, awọn iriri Peter Obi yii ko se fi owo ra, iriri si se agba ohunkohun, irufẹ ọlọpọlọ pipe bayii si ni orilẹ-ede Naijiria nilo niru asiko taa wa yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

Atẹjade naa fi kun pe, iyansipo Peter Obi ati ajọsepọ rẹ Atiku Abubakar ti wọn ba de ipo aarẹ, yoo seranwọ lati mu agbega ba eto ọrọ aje wa, irẹpọ ati agbega ba Naijiria lapapọ.

Atiku yan peter Obi gẹgẹ bii igbakeji rẹ

Olùdíje fún ipò aarẹ l'ábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ti yan Peter Obi gẹ̀gẹ̀ bi igbakejì rẹ̀ tí wọn yóò jọ síje dú ipò l'ọ́dún 2019.

Igbákejì alukoro ẹgbẹ́ PDP, Diran Ọdẹyẹmi sọ fun BBC Yoruba pé wọ́n yan Obi tó ti jẹ́ gómìnà rí ní ìpínlẹ̀ Anambra, nítorí pé ọmọ Nàìjíríà tòótọ́ ni, tí kò sí tún dàgbà tàbí kéré jù.

"Bákan nàá ni ẹgbẹ́ wo àwọn àṣeyọrí tó ṣe nígbà tó wa ní ipò gómínà, àti láti ìgbà tó ti fi ipò sílẹ̀."

Yíyàn tí a yan Obi kíì ṣe láti fa ojú ẹ̀yà ìgbò mọ́ra, ṣùgbọ́n nítorí pé ẹgbẹ́ wa gbà pé ẹ̀yà kan kò ju òmíràn lọ ní Nàìjíríà.''

Ìyànsípò Peter Obi ti n fa àríyànjiyàn lórí ẹ̀rọ̀ ayélujára.

Bí àwọn kan ṣe n gbóríyìn fún ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbe, ní àwọn kan ti sọ ọ̀rọ̀ nàá di ẹní bá láyà láàrin ìgbákejì aarẹ Nàìjíríà, Yemi Ọṣinbajo àti Peter Obi, ti olùdíjé fún ipò aarẹ nínú ẹgbẹ́ PDP, Atiku Abubakar, ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn.

Ohun tó yẹ kí Atiku Abubakar ó rò kí o tó yan igbákejì

Àáyáa Atiku Abubakar oludije fún ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí bẹ́ sílẹ̀ ó bẹ́ ááré báyìí.

Lẹyìn ìkéde rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò sójú ẹgbẹ́ náà, n'isẹ ní àwọn ọmọ orílèèdè Nàìjíríà n dá aba oríṣi lórí ẹni tí yóò kọwọrin pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí igbákejì.

Ọrọ náà gbà ìṣirò diẹ nítorípé o lè ṣe atọna tàbí kó jẹ ijakulẹ fún.

Buhari ati Atiku Image copyright FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òsèlú onígbaàálẹ̀, APC ti kí Igbákejì Ààrẹ Tẹ́lẹ̀rí, Atiku Abubakar kú oríire pẹ̀lú bí ó se jáwé olùborí nínù ìdìbò sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ PDP.

Àwọn orúkọ kọọkan ti n jẹ yọ lójú òpó ayelujara ṣùgbọ́n kò tí sí ìkéde kánkan pàtó lórí ìgbésẹ yí.

Ṣáájú kí a tó mọ irú ẹni tí Atiku yóò yan, a ni kí a jijọ ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tí o gbọdọ fi sọkan ki o to le yan ẹ́nikẹni ni igbákejì rẹ.

Ẹsìn

Òṣèlú Nàìjíríà ní àwọn ohun tó ya sọto pẹlú tí ibòmíràn.

Nínú àwọn nnkán ti o sí le se atọna tàbí àkóbá fún Atiku Abubakar nípasẹ igbákejì to bá yan ni ẹsin ti ẹni náà bá n tẹlé.

Aworan Mosalasi ati Soosi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipa ti ko se fọwọ rọ sẹyin ni ẹsin nko ninu oselu Naijiria

Kò fẹ sí oludije ààrẹ tabi ipo miran ti kí yan igbákejì to bá n ṣẹsin to yàtọ sí ti rẹ ki o ba ma da bí wipe o n gbé lẹyìn ẹsìn kàn.

Fún ìdí èyí,o ṣeéṣe kí atiku mu ẹlẹsin Kristẹni ní igbákejì ààrẹ.

Ọjọ́ orí

Ọmọ ọdún méjìlelaadọrin ní Atiku Abubakar .

Tí a bá sì wò bí ìpolongo fífún àwọn ọdọ ni ààyè nínú òṣèlú ti ṣe n lọ, òhun tó fẹ dájú ni wí pé,Atiku yóò yan ọdọ gẹgẹ bí igbákejì.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOwó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ gọbọi- olùdíje

Pẹlú bí òun náà ti ṣe tẹnu mọ wí pé òun yóò faye gba awon odo ninu ìṣèjọba rẹ, kí ba da ti ọ bá bẹrẹ lórí yíyan igbákejì ọdọ

Ẹyà

Nínú ìwé òfin orílèèdè Nàìjíríà, kò sí àkọsílẹ wí pé èèyàn gbọdọ yan igbákejì láti ẹyà kan tabi òmíràn ṣugbọn kò sí olóṣèlú ti yóò yan igbákejì lalai woye ẹyà ti ẹni náà ti wa.

Lọwọlọwọ lorílè-èdè Nàìjíríà, ẹyà Igbo kò fi taratara gba ti ìjọba Buhari pàápàá jùlọ lórí ọrọ atunto ti ọ bi ẹgbẹ bi Massob àti ipe fún ìdásílẹ̀ orílèèdè Biafra.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo ko ni waye ti wọn ko ba mu ọkọ mi jade

Afọjusun òpó èèyàn ni pé Atiku yóò yan igbákejì láti ẹyà Igbo kí o bá lè rí ìyọnu wọn ati ìbò wọn lọdun 2019.

Nínú àwọn tí orúko wọn ti n lédè bayi, o adabi ẹ́ni wi pe púpọ jẹ ẹyà Igbo.

Aworan awọn ti Atiku le yan gẹgẹ bi igbakeji

Ọkùnrin tàbí Obìnrin.

Kí ọkùnrin rí ejò kì obinrin rí ejò... òwe yí gbà ọgbọn láti tù nípa yíyan ẹni tí yóò jẹ igbákejì Atiku.

Tí o bá yan obìnrin gẹgẹ bí igbákejì oun ni yóò jẹ oludije akọkọ to lórúkọ ti yóò ṣe bẹ lagbo òṣèlú Nàìjíríà.

Tí kò bá ṣe bẹ àwọn tó n já fún fífún àwọn obìnrin àti ọdọ ní ayé láti kópa nínú òṣèlú Nàìjíríà yóò bẹnu àtẹ lù.

Ọrọ ba di ọba ran ni niṣẹ,odo ọba ya, iṣẹ ọba ko ṣe kọ, bẹẹ si ni odo ko ṣe kan lu.

Botilewukori, ohun kan tó ṣe kókó ni pé tí yóò bá yan obìnrin,o gbọdọ jẹ obinrin tó jẹ ògúnná gbòngbò nínú òṣèlú tí òun náà sí le wọ èro fún Atiku.

Òhun tí ẹgbẹ bá sọ

Ẹgbẹ òṣèlú Atiku Abubakar ní ipá nlá láti kó nínú ìgbésẹ yiyan igbákejì fún un.

Ní ọpọ ìgbà,ẹgbẹ a má yan igbákejì lẹyìn àgbéyẹ̀wò àwọn ìṣirò kọọkan gẹgẹ bí ẹni tí ẹgbẹ bá fẹ àti irú anfààní ti ẹni náà yóò mú bá àṣeyọrí nínú ìdìbò.

Nígbà tí ìkọ BBC Yorùbá n ba akọwe ìpolongo fún ẹgbẹ PDP Ọgbẹni Kola Ologbondiyan lori boya ẹgbẹ yóò yan igbákejì fún Atiku,o ni ''àwọn yóò jọ pa imọran pọ ni ti àsìkò ba to.''

Atiku Abubakar ati aarẹ ana, Olusegun Obasanjo Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Aarẹ ana Olusegun Obasanjọ ti sọ tẹlẹ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun Atiku Abubakar

Nígbà tí Atiku náà du ipò Ààrẹ pẹlu Ààrẹ Olusegun Obasanjo lọdun 1999, ẹgbẹ òṣèlú PDP lo yan fún Obasanjo láti tẹ apá kan orílèèdè Nàìjíríà lọrùn.

Lori ọrọ Aarẹ Obasanjo, ti a ba fi bi o ti ṣe n bẹnu atẹ lu Atiku,ko daju wi pe Atiku yoo yan ni igbakeji rẹ tabi ki Obasanjo tilẹ gbaruku ti Atiku ninu idijẹ fun ipo Aarẹ ni 2019.

APC: Atiku fi owó ra ìbò tó gbé e wọlé ní PDP

Ẹgbẹ Oselu APC ti ni Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Abubakar Atiku ko ni akọsilẹ rere lati le tukọ orilẹede Naijiria.

APC fi eyi lede ninu atẹjade ti wọn fi sọwọ si awọn oniroyin lati fi ki Atiku ku orire bi o se jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ oselu PDP lati fi yan oludije sipo aarẹ lọdun 2019.

Ninu atẹjade naa, APC sọ wi pe iwa ibajẹ ti Atiku hu lọ jẹ ki oun ati Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Olusegun Obasanjo tako ara won.

Wọn tun fi kun un wi pe orilẹede Amerika di eewọ fun igbakeji aarẹ tẹlẹri naa nitori iwa jẹgudujẹra ti o hu, eyi to fa a ti ilẹ Amerika fi n wadii rẹ lati fi jofin ijọba.

Ẹgbẹ oselu APC wa fi kun un wi pe, gbogbo igba ti Atiku ba pinnu lati dije dupo ni o ma n ra ibo awọn eniyan ki o baa le bori.

Saraki kí Atiku kú oríire, ó ṣèlérí àtìlẹ́yìn rẹ̀ ní 2019

Bukola Saraki ati Atiku Abubakar Image copyright @Toyin Saraki/Twitter

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba, Bukola Saraki ti ki Atiku ku oriirẹ, o si tun fi atilẹyin rẹ han fun un lati jẹ ko ṣe aṣeyọri ni 2019.

Saraki ni aṣeyọri naa yẹ Atiku ati wipe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ṣe daradara.

Ninu ọrọ idupe rẹ, Saraki ni o jọ bi ẹni pe Naijiria ko ti i ṣetan fun oun o.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSaraki dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀

Bẹẹ naa ni Ibrahim Dankwambo to jẹ Gomina Ipinlẹ Gombe ṣe ileri wipe oun yoo ba Atiku ṣiṣẹ lati jẹ ko ṣe aṣeyọri.

Lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu PDP kede igbakeji aarẹ nigba kan ri, Atiku gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa ni Port Harcourt, Atiku gboṣuba fun Aarẹ nigba kan ri, Oluṣẹgun Obasanjọ gẹgẹ bii ẹni to jẹ ki oun de ibi to de lonii.

Atiku ni ti kii ba ṣe pe Obasanjọ yan oun gẹgẹ bii igbakeji rẹ laarin 1999 si 2007, oun ko ni wa nipo ti oun wa lonii.

Atiku Abubakar ati aarẹ ana, Olusegun Obasanjo Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Aarẹ ana Olusegun Obasanjọ ti sọ tẹlẹ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun Atiku Abubakar

Eyi ni ọkan lara awọn oun ti Atiku sọ nigba ti oun dupẹ lọwọ awọn aṣoju ẹgbẹ naa to yan gẹgẹbii oludije.

O tun sọ wipe lati igba ti oun ti n dije, oun ti kopa ninu idibo abẹle marun ọtọtọ.

Atiku ni oludije fun PDP ni idibo 2019

Ọsan ọjọ Aiku ni ẹgbẹ́ oṣelu PDP kéde pé Atiku ló tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti kojú Buhari ni 2019.

atiku
Àkọlé àwòrán Atiku Abubakar ni PDP fa kalẹ̀ pé oun ati Buhari a jọ na an tan dupo aarẹ ni 2019

Awọn aṣoju 3, 274 ni wọn dibo ninu awọn ẹgbẹrun mẹrin (4, 000) to forukọsilẹ nigba ti wọn fagile ìbò 68. Eto idibo naa pari ni aago mẹfa kọja iṣẹju mẹrindinlogun.

Ibo 1, 532 ni Atiku fi jawe olubori di oludije fun ẹgbẹ PDP lati dije dupo aarẹ Naijiria ni 2019.

Ero awọn eniyan lori esi idibo to gbe Atiku wọle

Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fesi si idibo to gbe Igbakeji aarẹ tẹlẹri, Abubakar Atiku lẹyin ti idibo abẹle ẹgbẹ PDP gbe wọle pẹlu ibo 1, 532 ni ipade gbogboogbo wọn.

Lara awọn to fesi si idibo naa ni oju opo Twitter ba Atiku yọ pe owó ṣe pàtàkì pẹlu adura pé ko lè bori ninu idibo to n bọ.

Awọn ọmọ Naijiria gbàá nimọran pe ki o fi gbogbo ipa rẹ sin orilẹ-ede Naijiria nitori awọn setan lati se atilẹyin si.

Amọ, awọn ẹlomiran sọ pe magomago ko ni jẹ ki Atiku bori ni idibo to n bọ lọdun 2019, ti wọn si fi idibo ọdun 2019 we idibo Ọṣun to waye ni oṣu to kọja.

Awọn elomiran bi Femi Fani-Kayode ti inu wọn dun si esi idibo abẹle PDP naa ni ki APC mura silẹ fun ogun.

Esi idibo ni kikun

Jonah Jang ni ìbò 19.; Datti Babà Ahmed ni ibo 05; David Mark ni ibo 35; Kabiru Turaki ni ibo 65; Sule Lamido ni ibo 96; Bafarawa Attahiru 48; Ibrahim Dankwanbo ni ibo 111; Makarfi Ahmed ni ibo 74; Kwakwanso Rabiu ni ibo 158; Bukọla Saraki ni ibo 317; Aminu Tambuwal ni ibo 693 àti Atiku Abubakar ni ibo 1,532.

Àwọn oludibo

Abia 106; Adamawa 76; Akwa Ibom 153 ṣugbọn 151 lo dibo; Anambra 54; Bauchi 76; Bayelsa 74; Benue 121; Borno 57; Cross River 95; Delta 150; Ebonyi 101; Edo 79; Enugu 126; Ekiti 109; Gombe 89; Kaduna 103; Kano 129; Imo 117; Jigawa 84; Katsina 102 ṣugbọn 101 lo dìbò; Kebbi 68 ṣugbọn 66 lo dìbò; Kogi 94 ṣugbọn 93 lo dibo; Kwara 102; Lagos 62; Nasarawa 52; Niger 83; Ogun 21; Ondo 64; Osun 89; Oyo 88; Plateau 76; Rivers 131; Sokoto 95; Taraba 93; Yobe 59; Zamfara 48 àti FCT 36.

Bi ètò ìdìbò naa ṣe lọ

Odiwọn iye awọn aṣoju to dibo lati ipinlẹ kọọkan ni yii:

Awọn aṣoju ti bẹrẹ idibo lati yan ẹni ti yoo koju Buhari (APC) lọdun 2019.

Awọn aṣoju 3274 ni yoo dibo naa lati ipinlẹ mẹrindinlogoji ati FCT Abuja.

Awọn oludije mejila lo dije dupo ẹni ti ẹgbẹ PDP yoo fa kalẹ láti kojú Buhari ti ẹgbẹ AOC ti fa kalẹ bayii ni nu idibo sipo aarẹ Naijiria lọdun 2019.

oludibo Image copyright @empic
Àkọlé àwòrán Awọn aṣoju ti n dibo yan ẹni ti wọn fẹ bi aarẹ ni PDP

Ayẹwo awọn oludije ti pari

PDP Image copyright BC
Àkọlé àwòrán Gbogbo àwọn oludije náà niroyin ni wọ́n kọ̀ láti yẹ̀ba fún ara wọ́n nítorí kálukú gbà pé òun lè ṣe é dáadáa

Awọn mejila to n dije dupo asoju ẹgbẹ oselu APC ati awọn asoju wọn ti pari ayẹwo ki idibo to bẹrẹ si ipo oludije aarẹ ni abẹ ẹgbẹ oselu PDP.

Lẹsẹẹsẹ ni awọn asoju naa joko lati bẹrẹ si ni di ibo yan ẹni ti wọn fẹ ko koju Aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo gbogbooogbo ti yoo waye ni ọdun to n bọ.

Bakanaa, olorin takasufe ti igbalode to tun jẹ aburo oludije sipo gomina labẹ egbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ọsun, David Adeleke ti gbogbo eniyan mọ si ‘Davido’ naa ko gbẹyin nibi ipade gbogboogbo to n lọ lọwọ naa.

Àkọlé àwòrán PDP Convention 2018: Wọ́n ti parí àyẹ̀wò àwọn olùdíje fún ààrẹ ní PDP

Papa isere Amaesimaka nilu Port Harcourt ni ipade gbogboogbo naa ti n waye ti n waye

Àkọlé àwòrán Eto ti to nibi ibudo ìdibo abẹle PDP ni Port Harcourt

Oun gbogbo ti wa ni sẹpẹ fun ipade apapọ ẹgbẹ oselu PDP ni papa isere Amaesimaka nilu Port Harcourt.

Oniroyin wa to jabọ lati ibi ti ipade naa yoo ti waye so pe nise ni awọn agbofinro duro digbi lati ri wi pe ohun gbogbo lọ leto leto.

Awọn to n wọ agbegbe idibo naa ni a gbo wi pe awọn ọlọpaa n se ayẹwo finifini fun pẹlu irinsẹ ayẹwo igbalode.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjò Sebe, Ọká, òjòlá àti àkeèké jẹ́ alábagbé Phillipe

Oludije mejila ni yoo kopa ninu ibo abẹnu ẹgbẹ lati yan ẹni ti yoo koju Aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo Aarẹ ọdun 2019.

Àkọlé àwòrán Awọn onisọwo naa ko gbehin nibẹ

Karakata naa si nlọ ni agbegbe naa paapa julọ fun awọn to ba fẹ ra asia ẹgbẹ tabi awọn ohun isaraloge miran lati fi se afihan pe ọmọ ẹgbẹ ni wọn.

Àkọlé àwòrán Jakejado Naijiria ni awọn asoju ẹgbẹ ti wa lati kopa ninu idpade apapọ yi

Bi wakati naa ti se n sunmọ bọ ni awọn amoye ati ara ilu ti n bere ibeere pé: Tani yoo koju Buhari lati PDP?

Awa naa ko le dahun ibere yi bi ki ba se wi pe a gbo abajade ibo abẹnu naa sugbọn oun ti a le se ni ki a se agbeyewo awọn oludije to lewaju larin awọn to n du ipo yi.

Die ninu wọn re ati ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa wọn.

Bukola Saraki

Image copyright PIUS UTOMI EKPEI/GETTY
Àkọlé àwòrán Bukola Saraki ni Aarẹ ile asofin agba

Ninu akoso iṣejọba lorile-ede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki lo wa ni ipo kẹta.

Ọmọ bibi Ilorin to ti figba kan jẹ gomina ni ipinlẹ Kwara ni pẹlu iriri pupọ gẹgẹ bi aṣofin.

Ọpọ lo ti n foju sii lara pe o ṣeeṣe ki o du ipo aarẹ, ko si jẹ iyalẹnu nigba ti o kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ nibi ipade ẹgbẹ awọn ọdọ ni Abuja.

Awọn amoye n fi oju sii lara gẹgẹ bi ọkan lara awọn to le ri tikẹti ẹgbẹ gba ti ireti si wa wi pe ó le koju Buhari ninu idibo ọdun 2019.

Image copyright TWITTER/ATIKU ABUBAKAR
Àkọlé àwòrán Atiku Abubakar ko fi igba kan sinmi nina ọwọ ife si awọn olori kakiri orilẹẹde Naijiria.

Atiku Abubakar

  • O ti se igbakeji Aarẹ ri
  • O wa lara awọn ti wọn du ipo Aarẹ pẹlu Buhari lọdun 2015
  • Odu ni ki s'aimo foloko.
  • O wa lara awọn to kọkọ kede pe ohun fe jẹ Aarẹ lọdun 2019

Atiku ni ti wọn ba yan oun sipo Aarẹ Naijiria, atunto isejọba ni oun yoo gbajumọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC Primaries: A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí

Aminu Waziri Tambuwal

Image copyright @AWTambuwal
Àkọlé àwòrán Tambuwal fi igba kan sa kuro ninu ẹgbẹ PDP lo si APC

Aminu Waziri Tambuwal jẹ olori ile asojusofin nigba kan ri.

Lẹyin to sipo kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lo si APC, o du ipo Gomina nipinlẹ Sokoto ti o si wole gẹgẹ bi Gomina.

Lẹyinwa igba naa ni o tun fi ẹgbẹ APC silẹ pada si PDP nibi ti o ti ferongba silẹ lati du ipo Aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'

Tambuwal ni ọpọlọpọ iriri gẹgẹ bi asofin ti awọn kan si ri gẹgẹ bi irawo ọjọ iwaju ẹgbẹ PDP.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNàíjíríà pé ọmọ ọdún 58 lónìí, ǹjẹ́ o mọ ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ oílẹ̀-èdè rẹ?

Rabiu Kwankwanso

Image copyright Facebook/Kwankwansiya
Àkọlé àwòrán Lọdun 2015, Kwankwaso dije nibo abele APC sugbọn o fidiremi lọwo Buhari.

O pe die ki Rabiu Musa Kwankwanso to sọ boya ohun yoo du ipo aarẹ labe asia ẹgbẹ PDP tabi ẹgbẹ miran.

Sugbọn pẹlu atimaaṣebọ rẹ tẹlẹ ati awọn ipolongo ti awọn ololufe re n se lori ẹro ayelujara, ko ru ẹnikẹni loju pe o fẹ du ipo Aarẹ pẹlu Muhammadu Buhari.

Ọmọ bibi ipinlẹ Kano ni Kwankwanso, o si jẹ ilumọọka oloṣelu ti o ti fi igba kan jẹ Minista ati Gomina ipinlẹ Kano ri.

Kwankwaso kii se ajoji si ka ma du ipo Aarẹ sugbọn idije ọtẹ yi yoo fẹ le die fun un pẹlu bi ọrọ ko ti se wọ laarin oun ati Gomina ipinlẹ rẹ lọwọlọwọ, Abdullahi Ganduje.

Ti Kwankwaso ba ribi ja tikẹti ẹgbẹ PDP gba fun ipo Aarẹ, o seese ki o ba Buhari fa ibo pupo to ma n saba wa lati ipinlẹ Kano.

David Mark.

Image copyright @bukolasaraki
Àkọlé àwòrán Ko daju wi pe Mark yoo fẹ jọwọ ipo Aarẹ fun Saraki lọtẹ yi

Ajagunfẹyinti ni David Mark sugbọn iriri rẹ ninu oselu Naijiria jẹ oun to lami laka.

O ti saaju jẹ Aarẹ ile asofin agba Naijiria laarin ọdun 2007-2015.

Mark wa lara awọn ogunna gbongbo ẹgbẹ oselu PDP lati ibere pẹpẹ ti ko si sipo kuro ninu ẹgbẹ titi di bi a ti se n sọrọ yi.

Mark ni ti wọn ba yan oun gẹgẹ bi Aarẹ, ọdun meji loun yoo fi se atunto orile-ede Naijiria.

Isoro rẹ bayi ni ki o ri tikẹti ẹgbẹ gba. Ọmọ àádọ́rin ọdun nii se.

Sule Lamido

Image copyright @AWTambuwal
Àkọlé àwòrán Sule Lamido ati Aminu Waziri Tambuwal

Sule Lamido ni o fẹ da bi wi pe ipolongo rẹ fun ipo Aarẹ ko gbode sugbọn kii se ẹni a a foju di.

Ipinlẹ Jigawa lo ti wa nibi ti o ti jẹ gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP lọdun 2007.

Ninu awọn to duro ti ẹgbẹ PDP nigba isoro lo jẹ ti awọn to mọ nipa oselu ko si ko iyan rẹ kere rara.

Aarẹ orile-ede Naijiria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo, nigba ti o n gba a ni alejo ni Ota so pe ''Lamido kun oju osunwọn lati dari Naijiria.''

Ti awọn ọmọ ẹgbẹ ba wo ti wi pe o duro gbagba ti awọn, o yẹ ki wọn dibo yan an gẹgẹ bi oludijẹ ẹgbẹ fun ipo Aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn tó n bọ Ṣàngó n jẹ iná níni ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwa obìnrin tó ń lépa afòjúsùn máa n ba ọkùnrin lẹ́rù ni -Toyin Lawani