Ìyansẹ́lódì MMA2: Alẹ́ Ọjọ́bọ ni ìyansẹ́lódì náà wá sópin

Ẹnu ibodè MMA2 Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn arìnrìàjò ní pápákọ̀ òfúrufú MMA2
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn òṣìṣẹ́ pápápọ̀ òfurufú ní Ìpínlẹ̀ Eko fi ẹ̀honú wọn hàn

Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lẹ́kàa ètò ìrìnà òfúrufú ti fagile iyanṣẹlodi ti wọn gun le.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ṣọ pe, ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ ile iṣẹ naa lalẹ Ọjọbọ nibi ti wọn ti gba lati fagi le iyanṣẹlodi naa.

Abioye sọ pe bi adari awọn ti le oṣiṣẹ bi aadọrin lọ, ko ba ofin mu.

Àkọlé àwòrán Àwọn òṣìṣẹ́ MMA2

Ẹ o ranti pe awọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ naa da ẹ̀rù bolẹ̀ wí pé àwọn yóò ti pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed international Airport 2 (MMA) tó wà ní ìlú Eko pa.

Lọ́jọ́rú ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kẹ́wàá ni èyí wáyé lórí ẹ̀sùn pé wọ́n dá òṣìṣẹ́ ogún dúró lẹ́nu iṣẹ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Nígbà tí kò ṣeéṣe fún wa láti fò, a ó lọ́ wọkọ̀'

Ṣáájú, ẹgbẹ́ náà nínú ìkìlọ̀ tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ ìṣẹ́gun ti sọ wí pé àwọn yóò dí iṣẹ́ lọ́wọ́ ní ibùdókọ̀ eléyìí tí ilé iṣẹ́ Bi-Courtney Aviation Services Limited (BASL) ń ṣe àkóso rẹ̀.

Àkọlé àwòrán Àwọn òṣìṣẹ́ MMA2

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ ọ́ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ náà ló rí lọ́jọ́rú tí wọ́n tú síta lówùrọ̀ kùtù hàì sí ẹnu ọ̀nà pápákọ̀ òfúrufú náà láì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé.

Àwọ́n ẹgbẹ́ tó dá a sílẹ̀ ni The National Union of Air Transport Employees (NUATE) and Air Transport Services Senior Staff Association of Nigeria (ATSSSAN) àti the National Association of Aircraft Pilots and Engineers (NAAPE)

Àkọlé àwòrán Ẹnu ibodè MMA2

Akọ̀ròyìn BBC Yorùbá tó bá àwọn òṣìṣẹ́ àti arìnrìnàjò sọ̀rọ̀ jábọ̀ wí pé lóòtọ́ ni wọ́n ti ẹnu ibodè pápákọ̀ òfúrufú pa tí wọn kò sì jẹ́ kí àwọn tó ti forúkọ sílẹ̀ láti rìnrìnàjò wọlé.

Kódà, àwọn tí kò lérò wí pé ìgbẹ́sẹ̀ tí àwọn òṣìṣẹ́ yìí gbè leè pa àwọn lára, ṣe ni wọ́n ń dì ẹrù wọn padà sílé.

Àwọn ẹgbẹ́ náà ní gbogbo iṣẹ́ tó ń wáyé ní MMA2 ní àwọn yóò bẹ́gi dínà rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kẹ́wàá àyàfi bí wọ́n bá dá gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tí dá dúró padà láì pàdánù owó oṣù tàbí ipò gíga wọn.

Image copyright AP
Àkọlé àwòrán Àwọn arìnrìàjò ní pápákọ̀ òfúrufú MMA2

Páropáro ni gbogbo ìnú ọgbà àti ibi ìgbàléjò pápákọ̀ òfúrufú náà dá.

Àkọlé àwòrán Inú ọgbà MMA2

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Pẹ̀lú ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́, kò sọ́nà fún àwọ́n arìnrìn àjò káàkiri oríllèdè Nàìjíríà láti wọ ọkọ̀ bàálù lọ ibikíbi.

A ó máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn wá fún un yín bó ṣe ń lọ látẹnu àwọn akọ̀ròyìn wá.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Murtala Muhammed international Airport 2
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'