Ibikunle Amosun: Ǹ ó fi ẹgbẹ́ òsṣèlú APC sílẹ̀'

Gómìnà Ibikunle Amosun Image copyright Senator Ibikunle Amosun Facebook
Àkọlé àwòrán Gómìnà Ibikunle Amosun

Gómìnà Ibikunle Amosun ti ìpínlẹ̀ Ogun, Sẹ́nétọ̀ Ibikunle Amosun ti dẹ́rù bolẹ̀ lọ́jọ́rú ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá pé oun yóò fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀.

Ó ní òun yóò ṣe èyí bí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá ẹgbẹ́ náà bá kọ̀ láti kéde olùdíje tí òun fà sílẹ̀, Abdul-Kabir Adekunle Akinlade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Èyí wáyé lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Gómìnà Akinwumi Ambode ti ìpínlẹ̀ Eko, Rochas Okorocha ti Imo, Umar Ganduje ti Kano, Mohammed Abubakar ti Bauchi and Kashim Shettima ti Borno ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Muhammadu Buhari láti mú u kí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò abẹ́lé ìpínlẹ̀ wọn.

Gẹ́gẹ́ bí ọkan lára àwwọn tó kópa níbi ìpàdé náà ṣe sọ ọ́, gómìnà ọ̀hún tó jábọ̀ àbábọ̀ ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú ààrẹ Buhari kò ta ẹnikẹ́ni lólobó ẹgbẹ́ t íyóò ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́.

Ó sọ fún àwọn oníròyìn pé dípò kí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ yá yanjú ọ̀rọ̀ náà, ṣe ni wọ́n ní kí òun pín tíkẹ̀ẹ̀tí ilé àṣòfin àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ pẹ̀lú àwọn kan tó ní wọn ò bá wọn kópa nínú ìdìbò abẹ́lé ti gómìnà àti ti aṣòfin ìpínlẹ̀.