Atiku: Ọ̀dọ́ yóò gba isẹ́ 40%, obìnrin yóò mú 30%

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Àkọlé àwòrán,

Mo ti ṣetan lati sin Naijiria

Oludije si ipo aarẹ lẹgbẹ oselu PDP ni Naijiria fun idibo 2019, Atiku Abubakar ti ni ida aadọrin ninu awọn ti awọn yoo jọ se ijọba yoo jẹ ọdọ ati obinrin.

Abubakar sọ eyi lasiko to n se ipolongo ni ipinlẹ Yola.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ida ogoji yoo jẹ fun awọn ọdọ, nigbati ida ọgbọn yoo lọ si ọdọ awọn obinrin ati wi pe awọn agbalagba ni yoo wa ni ida ọgbọn to ku.

Àkọlé fídíò,

Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

Ìwé ìlànà ìṣèjọba ọlọdún méje tí Atiku gbé jáde lọjọ Àìkú tún sọ wí pé, àwọn eeyan to padanu isẹ wọn lati 2014 ti to miliọnu meje bayii.

Sé ìgbé ayé yín dára si láti 2015? - Atiku bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Nàíjíríà

Oludije ipo Aarẹ fun ẹgbẹ oselu PDP lorileede Naijiria Atiku Abubakar, ti sefilọlẹ eto ipolongo ibo rẹ ni ọsan ọjọ Aje, to si ni oun ti fa ara oun kalẹ lati ba ireti ati ilakaka awọn ọmọ Naijiria pade.

Nigba to n bawọn omilẹgbẹ ololufẹ rẹ sọrọ loju opo ikansiraẹni Twitter ati Facebook rẹ lori itakun agbaye, Atiku ni, ibeere to se pataki to wa niwaju awọn ọmọ Naijiria ni pe ‘N jẹ igbe aye wọn ru gọgọ si lati ọdun mẹrin sẹyin ti ijọba to wa lode ni orilede yii ti gba ijọba’?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

World Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Bakan naa lo woye pe ọpọ eeyan ni ko ni isẹ lọwọ, ti ẹka awọn ileesẹ to n pese asọ sita si ti dẹnu kọlẹ patapata.

Atiku ni " Orilẹede wa ko tii pinya bii eyi ri, ohun gbogbo lo ti dẹnu kọlẹ, ọpọ eeyan lo ti padanu is wọn, eyi to n sọ awọn ọmọ orilede yii sinu agbami isẹ ati osi. Amọ mo si jẹjẹ lati jẹ́ ki Naijiria gberasọ pada."

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Atiku fi kun pe gbogbo ileri ti oun n se yii kii se afẹnuse lasan, amọ oun setan lati mu ki awn ileri yii wa si imusẹ laipẹ ti oun ba wọle sipo aarẹ.

Atiku Abubakar ti seleri lati pese miliọnu mẹta iṣe lọdọọdun

Oludije ipọ Aarẹ fun ẹgbẹ oselu PDP lorileede Naijiria Atiku Abubakar ti seleri lati pese miliọnu mẹta iṣe lọdọọdun, ti ohun ba jẹ Aarẹ Naijiria.

Ileri yi jẹ ọkan gboogi ninu awọn eto ti o la kalẹ ninu iwe ilana iṣejọba to gbe jade lọjọ Aiku.

Atiku sọ pe ''o sunmọ miliọnu merindinlogun eeyan ni ko nisẹ ni Naijira, ti eyi si fi miliọnu mesan ju iye awọn ti ko nise lọwọ lodun 2014 lọ.''

Oríṣun àwòrán, @atiku

Àkọlé àwòrán,

Atiku ni iṣẹ nla lo wa niwaju ohun

''Pipese isẹ ṣe pataki lati maṣe jẹ ki awọn ọdọ darapọ mọ ẹgbẹ kẹgbe ati ti a ba fẹ mu adinku ba awọn ikunsinu to n fa gbọnmisi omi o too lawujọ''

Fun idi eyi,o sọ wi pe oun yoo ṣe ''agbekalẹ eto idanilokowo eleyi ti o muna doko ti yoo si pese pese miliọnu mẹta iṣe ati ọna ise lẹka aladani lọdọọdun''

Yatọ si ọrọ iṣe ti iwe naa mẹnuba,Atiku sọ pe ọun yoo mu idagbasoke ba ipese awọn ohun amayederun ati wi pe ohun yoo mu adinku ba iṣẹ oun oṣi lawujọ.

Oríṣun àwòrán, Atiku.org

Àkọlé àwòrán,

Lati ilẹ ni Atiku ti tẹnumọ ipese iṣẹ ni adisọkan rẹ

Bakannaa ni iwe eto iṣejọba naa ni ti awọn ọmọ Naijiria ba dibọ fun Atiku,yoo sọ ajọ to wa nidi ọrọ epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC di aladani ti yoo si ta awọn ile iṣe ifọpo epo mẹrẹrin to wa ni Naijiria.

Lọjọ aje ni ayeye agbekale ẹto ipolongo Atiku Buhari yoo waye.

Atiku Abubakar ti fi igba kan jẹ igbakeji Aarẹ lorileede Naijiria ti o si wa lara awọn ti o ṣetan lati gba agbara lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.

Oríṣun àwòrán, Atiku.org

Àkọlé àwòrán,

Odu ni Atiku lagbo oselu Naijiria

Lai pẹ yi ni ijọba Naijiria fesi si ẹsun ti Oludije sipo Aarẹ, Atiku Abubakar fi kan awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu to wa ni ilu Abuja pe wọn fi abuku kan oun lasiko ti ọkọ ofurufu oun balẹ si papakọ naa.

Atiku ninu atẹjade to fi si oju opo Twitter rẹ sọ pe awọn oṣiṣẹ fi ipa wọ oun ati oṣiṣẹ oun.

Minisita fọrọ ofurufu, Hadi Sirika lasiko to n fesi ṣalaye pe ẹsun naa ko ni idi nlẹ nitori pe ohun to pọn dandan ni ki wọn ṣe ayẹwo ọkọ ofufuru ati awọn eniyan to ba balẹ si papakọ ofurufu lorilẹ-ede Naijiria.

Sirika fikun un wi pe gbogbo ọ̀wọ̀ tó tọ́ si Atiku ni awọn fi fun un, ati pe ko si ohun to jọ bii arifin ninu iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣotọọtọ lori èyí

Bakan naa, awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fun Atiku lesi lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter rẹ lẹyin ti o fi ẹsun naa lede.

Lara awọn to fun un lesi bu ẹnu atẹ lu u pe ohun to pọn dandan ni lati ṣe ayẹwo ni papakọ ofurufu ati wi pe ko nii ṣe pẹlu ipo ti eniyan di mu lawujọ.

Ẹlomiran ninu ọrọ tirẹ ni "ati minisita, ati ọba ilu o, ko sẹni ti kii ṣe ayẹwo ni papakọ ofurufu".

Àkọlé fídíò,

Somalia: 'Wọ́n pàṣẹ fún mi láti dá Ramla dúró ká tò lè ṣe igbeyàwó'

Amọ, awọn ẹlomiran dáhùn pe kani bi wọn ṣe n ṣe ayẹwo lojoojumọ fun Atiku ni yii, ko ni ke gbajari si ta wi pe wọn ṣe oun baṣubaṣu ni papakọ ofurufu Abuja.

2019 Election: Tinubu ní Atiku lè ṣèpàdé nínú igbó tó bá wù ú

Ẹgbẹ́ oṣèlú PDP ti ṣeé níkìlọ̀ fún adarí àgbà ẹgbẹ́ oṣèlú All Progressive Congress (APC), Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu lórí pé ó ní ẹ̀rù ò bodò kódà bí Atiku bá lọ ṣèpàdé ní Dubai tàbí nínú igbó.

Wọ́n ní kí Aṣíwájú má kò ara rẹ̀ síta nípa sísọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí olùdíje ẹgbẹ́ PDP, Atiku Abubakar.

''Kò yẹ kí Aṣíwájú gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ́lẹ̀ nípa dídarapọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ àlùfànsá sísọ eléyìí tó ti di bárakú ẹgbẹ́ oṣèlú rẹ̀ aláìríṣẹ́ṣe".

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

PDP kóTinubu ní ìjánu

Ẹgbẹ́ oṣèlú PDP nínú àtẹ̀jáde rẹ̀ tí akọ̀wé ẹgbẹ́, Kọla Ọlọgbọ́ndíyàn fọwọ́ sí sọ wí pé "èèyàn bíi Tinubu leè ṣe òṣèlú rẹ̀ láì dá sí lílo ọ̀rọ̀ òdì èyí tí kò bọ̀wọ̀ fún ènìyàn bíi Atiku ẹni tí gbogbo Nàìjíríà káàkírí ti gbà láti jẹ́ Ààrẹ wọn tó mbọ̀."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ̀rù ò b'odò bí Atiku bá lọ ṣèpàdé ní Dubai

Ọgọrọ eeyan lo ti fesi lori ẹrọ ayelujara sọrọ ti abẹnugan ẹgbẹ oṣelu APC Asiwaju Bola Tinubu sọ lori ipade oludije fun ipo Aarẹ labé asia ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar ati awọn alatilẹyin rẹ ṣe ni ilu Dubai.

Adaba tiwa ko nọnni a n kungbẹ, ina n jo ẹyẹ oko n lọ...lowe ti Tinubu fi bọnu lori bi Atiku Abubakar ti lọ ṣepade nilu Dubai.

Àkọlé àwòrán,

Òkò ọ̀rọ̀ ṣáájú ìdìbò 2019

Tinubu sọrọ yii lẹyin to ṣepade idakọnkọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari nilu Abuja.

Asiwaju sọrọ, o fa kumookun rẹ yọ, o ni ''to ba wu Atiku o le lọ ṣepade ninu aginju igbo tabi ni Abu Dhabi, ohun to wa nibẹ nipe awọn eeyan lanfani lati pade nibi kibi to ba wu wọn. Ṣugbọn o daju pe awọn ọmọ Naijiria ko ni pada s'ijọba PDP mọ.''

@_MrAwaji ati @ayanbaba1 tako ara wọn lori ọrọ Tinubu, @_MrAwaji lo kọkọ sọ pe ẹru lo n ba Tinubu lo jẹ ko sọrọ bẹẹ ṣugbọn @ayanbaba1 ni irọ nio wipe ko si ẹru kankan fun Tinubu ati ẹgbẹ APC.

@CaptainGabby100 ni awọn oriroyin ni wọn n gbe ọrọ yii gẹgẹ, o ni kosi nkankan nibẹ. Amọ o sọ pe Atiku lanfani lati gbegba oroke ninu idibo Aarẹ ọdun 2019 ju Aarẹ Muhammadu Buhari lọ.

Ọrọ lori alaga ẹgbẹ oṣelu APC Adams Oshiomole lo jẹ @KabirAbdulazee6 logun ni tirẹ, o ni wọn yan an sipo wipe ko sẹni to dipo fun gẹgẹ alaga ẹgbẹ APC.

@shittuisiakao tiẹ binu tan, o ni ọpọlọpọ eeyan ko mọ pe ko boju mu rara fun oludije fun ipo aarẹ lati ni ofisi rẹ si ilu okere. Bẹẹ naa lo sọ pe Aarẹ Muhammadu gbọdọ jara mọṣẹ lori iṣejọba rẹ.

Tinubu tun sọrọ lori bi awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n sọ pe ki wọn yọ alaga ẹgbẹ oṣelu naa Adams Oshiomole nipo, o ni kosi ohun to jọ bẹ rara.

Asiwaju Tinubu ni iku wa ajọku, awẹ wa ajọgba ni ọrọ Oshiomole nitori ẹgbẹ lo yan an sipo to wa.

Obasanjo ṣatilẹyin fun Atiku

Awọn ajagunfẹ́yinti kan ni ilẹ Yoruba ti se atilẹyin fun aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ lori bo se n se atilẹyin fun igbakeji rẹ, Atiku Abubakar lati lọ dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede yii.

Awọn ajagunfẹyinti naa, ti wọn jẹ ẹya Yoruba, ninu eyi ti a ti ri David Medayese Jẹmibẹwọn ati Ajibọla Togun ni, ko si ohun to buru ninu ohun ti Ọbasanjọ se yii, gẹgẹ bo se n sugba Atiku lati di aarẹ Naijiria lọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi awọn mejeeji ti wi," Bi o tilẹ jẹ pe lọpọ igba ni Ọbasanjọ maa n tako Atiku, sugbọn ko si ohun to buru to ba pinnu lati yi ero rẹ pada nipa Atiku, a sa n pa ọna oko da, anbọsin ọna ẹnu."

Àkọlé fídíò,

Ìyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

Awọn ajagunfẹyinti naa ni Ọbasanjọ ko ti s si ofin lori igbesẹ rẹ yii, o si ni ẹtọ labẹ ofin lati sọ tabi se ohun to ba ba ero ọkan rẹ lọ.

Awọn agbaagba ilẹ Yoruba ni Atiku lawọn n ba lọ

Bakan naa, awọn agbagbagba ilẹ Yoruba ti kede pe, igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri Atiku Abubakar ni awọn yoo satilẹyin fun ninu ibo Aarẹ lọdun 2019, lẹyin ti Aarẹ ana Oluṣẹgun Obasanjọ kede atilẹyin rẹ fun Atiku.

Akọwe ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Yoruba Council of Elders (YCE), Kunle Olajide to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, o ṣeeṣe ki ẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba tẹle Atiku nitori oun fara mọ atunto Naijiria, ti ẹgbẹ naa ti n sọ fun igba pipẹ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ètò Atiku ló bá èròngbà Yorùbá mu

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Sẹ́nẹ́tọ̀ Femi Okunronmu sọ pé Atiku ló le tún Nàìjírìa ṣe

Bakannaa Sẹnẹtọ Femi Okunronmu naa sọrọ, to si fa komookun rẹ yọ pe, ibi ti Obasanjọ lọ gan an l'oun n lọ lori ọrọ ibo Aarẹ lọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Okunronmu sọ pe, Atiku lo to gbangba sun lọyẹ lati gba awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọwọ iṣẹ ti o n ba wọn finra, ati pe Atiku lo le ṣe eto aabo to peye lorilẹede Naijiria.

Ẹwẹ, ile iṣẹ Aarẹ ti fesi tẹlẹ pe Aarẹ orilẹede Naijiria ana, Olusẹgun Obasanjọ ati igbakeji rẹ Atiku Abubakar, yoo jọ padanu ninu idibo Aarẹ ọdun 2019 nigbati Aarẹ Muhammadu Buhari ba jawe olubori.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari Garba Shehu, lo fọrọ naa lede lẹyin ti Obasanjo kede pe oun ti dariji Atiku, ati pe oun ṣetan lati ṣatilẹyin fun-un lati di aarẹ Naijiria.

Shehu salaye pe, igbesẹ Obasanjo ko ya Aarẹ Buhari lẹnu, nitori o fi han gbangba pe, oye nipa eto oṣelu ode oni ko ye e.

Oríṣun àwòrán, Usman Okai Austin

Àkọlé àwòrán,

Kódà, ìpàdé nàá kò yọ àwọn olórí ẹ̀sìn sílẹ̀

O fi kun ọrọ pe, Aarẹ Buhari ti kọ eti ikun si ọrọ Obasanjo ati Atiku nitotri o n tẹsiwaju ninu eto igbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ

Ẹyin l'ohùn,tó bá ti jabọ kìí ṣe ko mọ

Rẹgi ni ọrọ yi ṣe ti a ba wo ọrọ ti Aarẹ ana l'orileede Naijiria, Olusẹgun

Oríṣun àwòrán, @atiku

Àkọlé àwòrán,

Ṣaaju ni Ọbasanjọ sọ pe Ọlọrun ko ni dari ji oun ti oun ba gbe lẹyin Atiku Abubakar.

Ṣugbọn, bi Ọbasanjọ ṣe ti wa a yi ero rẹ pada pẹlu bi o ti se fori jin Atiku, to si tun sọ pe oun ''ṣetan lati ṣatilẹyin fun lati di aarẹ Naijiria'' ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa lori ayelujara.

Tẹ o ba gbagbe, abi ko dayin loju wi pe o sọ ọrọ yi, ẹ wo fọnran fidio yi nibi ti Obasanjọ ti n sọrọ nipa Atiku ninu iwe rẹ to fi sita,''My Watch''.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ninu fọnran naa to wa loju opo YouTube,Ọbasanjọ sọ pe pẹlu ''ohun ti oun mọ nipa Atiku, Ọlọrun ko ni forijin oun ti oun ba segbe lẹyin Atiku''

Ṣe Ọlọrun yoo fori ji Ọbasanjọ?

Ibeere re ti awọn ọmọ Naijiria n gba ni agba tungba loju opo Twitter niyii lẹyin ti Obasanjọ fori jin Atiku.

Sugbọn kii ṣe ọrọ Obasanjọ nikan lo gboju opo ayelujara.

Awọn kan mẹnu ba bi awọn adari ẹsin kan bi David Oyedepo,Sheikh Ahmad Gumi ati Bisọọbu Mathew Kuka ti ṣe kọwọrin lọ ọ ba Atiku pari aawọ laarin oun ati Obasanjọ

L'ọjọbọ ni Atiku Abubakar tii ṣe oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar, gunlẹ si ile aarẹ ana l'orilẹede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni nkan bi aago kan ọsan.

Lẹyin ipade naa, Atiku Abubakar sọ pe idunnu lojẹ fun oun lati ṣepade pẹlu ọ̀ga oun nigba kan, tawọn si tun jọ jẹ ounjẹ ọsan.

Abubakar to jawe olubori laipẹ yii gẹgẹ bi aṣoju ẹgbẹ PDP fun idibo aarẹ ti yoo waye ni Naijiria l'ọdun 2019, lo ṣeeṣe ko bẹ Ọbasanjọ wo pẹlu ireti pe yoo ṣe atilẹyin fun erongba rẹ lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Atiku Abubakar jẹ igbakeji aarẹ lasiko ti Ọbasanjọ fi jẹ aarẹ Naijiria laarin ọdun 1999 si 2007. Ṣugbọn, aarin awọn mejeeji pada daru, ti Ọbasanjọ si jẹẹjẹ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun ipinnu Atiku lati aarẹ Naijiria lailai.

Oríṣun àwòrán, Usman Okai Austin

Àkọlé àwòrán,

Atiku bẹ Ọbasanjọ wo pẹlu ireti pe yoo ṣe atilẹyin fun erongba rẹ lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni alaga gbogboogbo fun ẹgbẹ oṣélu PDP, Uche Secondus, ati oludari eto ipolongo ibo fun Atiku, Gbenga Daniel, naa kọwọrin pẹlu rẹ.

Awọn olori ẹ̀sìn bi olùdásílẹ̀ ìjọ Living Faith Church, Bíṣọ́ọ̀pù David Oyedepo, tó fi mọ Bíṣọ́ọ́pù ijọ Aguda ni ipinlẹ Saokoto, Matthew Kukah, ati Oniwaasu ẹsin Islam, Ahmed Gumi. Sẹnetọ Ben Murray-Bruce ati Alagba Ayọ Adebanjọ to jẹ eekan ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre.

Àkọlé fídíò,

'Mo kẹ́kọ̀ọ́ fásitì sùgbọ́n aṣọ òké ló ń jáwó báyìí'