Celestine ẹlẹ́wọ̀n: Òun àti ọmọ rẹ̀ ló wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Paul àti Celestine

Oríṣun àwòrán, GLOBAL SOCIETY FOR ANTI-CORRUPTION

Àkọlé àwòrán,

Paul àti Celestine Egbuchune ti lo ọdún méjìdínlógún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n

Celestine Egbunuche ti pé ọgọ́rùn ún ọdún, tí àwọn kan si gbàgbọ́ pé òun ni ẹlẹ́wọ̀n tó dàgbà jù ní Nàìjíríà, èyí sì tí mú kí àwọn ènìyàn maa bẹ ìjọba láti tu u sílẹ̀.

Ó ti lo ọdún méjìdínlógún ní ọgbà ẹwọn lẹ́yìn tí wọ́n ní ó kó àwọn kan jọ láti ṣekúpa ẹnìkan.

Celestine àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, Paul Egbunuche, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì, ni wọ́n jọ wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Enugu Maximum Security Prison, ní ẹkùn Ìlà Oorùn Gúsù, fún ẹ̀sùn kan nàá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan wọ́n pé wọ́n gba àwọn ènìyàn kan láti jí ọkùnrin kan gbé, tí wọ́n sì tún pa á nítorí ilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Imo.

Bàbá àgbàlagbà ọ̀hún kò le sọ̀rọ̀ mọ́, ó sì n ṣe bi ẹni tó ní àìsàn, débi pé ọmọ rẹ̀ ló n gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀.

Nínú oṣù Kẹfà, ọdún 2000, ni ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ wọ́n, kó tó di pé wọ́n dájọ́ ikú fún bàbá àti ọmọ ní ọdún 2014. Paul sọ pé àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

Ó sọ pé bàbá òun kò tilẹ̀ mọ nkankan tó n lọ ní agbègbè rẹ̀ mọ́.

''Tí ẹ bá bi i ní ìbéèrè kan, ọ̀tọ̀ ni ìdáhùn tí yóò fún yín. Àwọn dókítà sọ fún mi pé ọjọ́ orí rẹ̀ lójẹ́ kí ó maa ṣe bi ọmọdé.''

''Nígbà míràn, ó maa n bi mí pé kíni àwọn ènìyàn yìí (àwọn ẹlẹ́wọ̀n) n ṣe níbí?''

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlọ́wọ̀n ló n retí ìdájọ́ ikú láti ọjọ́ pípẹ́.

Paul sọ pé òun ni ó n tọ́jú bàbá òun nínú ẹ̀wọ̀n láti ìgbà tí ìlera rẹ̀ ti mẹ́hẹ̀. Ó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ojú rẹ̀ kò sì ríran dáàda mọ́.

''Ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí kò pọ́n ni mo maa n fun un jẹ́, àwọn olùṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n naa si maa n fun ní òògùn.''

Inú yàrá kan naa ni Paul àti bàbá rẹ̀ jọ wà l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n, pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n mi i tó n retí ìdájọ́ ikú.

"Tí mo bá jí ní òwúrọ̀, màá gbé omi kaná láti fi wẹ̀ fun un.''

Àkọlé fídíò,

Wo fidio 'ẹwọn idẹra'

''Màá pàárọ̀ aṣọ rẹ̀, màá sì ṣe oúnjẹ rẹ̀ fun un. Tí wọ́n bá ṣí ìlẹ̀kùn yàrá tí a wà, máà gbe jáde síta kí òòrùn le pá díẹ̀.''

Paul sọ pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n yóòkù maa n ran òun lọ́wọ́ láti tọ́jú bàbá rẹ̀ nígbà mi i.

Lẹ́yìn tí Bàbá àgbà Celestine ṣe ọjọ́ ìbí ọgọ́rùn ún ọdún l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni àwọn akọ̀ròyìn kọ nípa rẹ̀.

Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí bèérè pé ọdún mélòó gan ló yẹ́ kí ẹni tó bá ti gba ìdájọ́ ikú lò l'ẹ́wọ̀n.

Àkọsilẹ̀ láti iléèṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà fihàn pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ló n retí ikú ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ó ṣeesẹ kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, Rochas Okorocha buwọ́ lùú pé kí wọ́n tú Alàgbà Egbuchune sílẹ̀.

Pamela Okoroigwe tó jẹ́ agbẹjọ́rò fún ètò ìrànwọ́ Legal Defence and Assistance Project (LEDAP) sọ pé ''ó wọ́pọ́ láti bá ẹni tó ti gba ìdájọ́ ikú láti bi ọgbọ̀n ọdún.''

"Àwọn gómìnà kìí ṣábà buwọ́ lu àṣẹ láti pa ẹlẹ́wọ̀n, bákan nàá ni wọ́n kìí fún wọn ní òmìnira, ló fàá tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó n retí ikù pọ̀.''

Franklin tó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ tó n gbógun ti ìwà ìbàjẹ́, Global Society for Anti-Corruption (GSAC) sọ pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ Alàgbà Egbuchune tó ìjọba àti agbẹjọ́rò àgbà fún ìpínlẹ̀ Imo, Miletus Nlemedim létí, pé kí ìjọba f'oríji bàbá nàá, ṣùgbọ́n gómìnà Rochas Okorocha kò tìí buwọ́ lùú.

Ọmọ rẹ̀, Paul sọ pé ''yóò dára tí wọ́n bá fun ní òmìnira, kó le bà á ní ànfàání láti kú ní ìrọ̀rùn ní ilé rẹ̀ ju pé kó kú sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n.