Ṣọla Allyson: Orin mi ń yí àwọn èèyàn tó fẹ́ pa ara wọn lọ́kàn padà

Ṣọla Allyson, tii se ilumọọka olorin ẹmi, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, ọpọ eniyan to wọn ti pinnu lati pa ara wọn, amọ ti wọn gbọ orin oun nigba to ku diẹ ki wọn gbe igbesẹ naa, ni wọn yi ero wọn pada.

Bakan naa lo tun sọ pe, oun ko nilo lati si awọn ẹya ara oun kan silẹ, kawọn eeyan to mọ pe arẹwa ni oun nitori oun funra oun gan mọ pe oun gangan ni ẹwa.

Allyson fi kun pe oun kọkọ maa n ronu jinlẹ lori ipa ti orin ti oun fẹ gbe jade yoo ni lori ẹni to ba gbọ orin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: