Ìtàn Mánigbàgbé: D.O Fágúnwà máa ń sùn sí ibojì, aginjù tàbí ti ara rẹ̀ mọ́lé láti kọ̀wé

Àkọlé àwòrán Ẹmi kan lo maa n dari Fagunwa, to si maa n ba ẹmi airi sọrọ

Ọpọ ọdọ lode oni ni ko mọ ohunkohun nipa gbaju-gbaja Onkọwe nni, to kọkọ kọ iwe ni ede abinibi nilẹ adulawọ, eyiun Daniel Ọlọrunfẹmi Fagunwa.

D.O Fagunwa, gẹgẹ bi ọpọ eeyan se mọ si, lo kọ iwe Ogboju ọdẹ ninu igbo Irunmọlẹ̀ lọdun 1938, Igbo Olodumare lọdun 1945, Ireke Onibudo lọdun 1949, Irinkerindo ninu igbo Elegbeje lọdun 1954, Adiitu Olodumare ni 1961, to si n kọ apa keji rẹ, to pe ni Ireọla Olodumare ati Igbo Adimula lọwọ nigba ti Ọlọjọ de.

Ohun to yẹ ko mọ nipa D.O Fagunwa

 • Ọdun 1903, eyiun ọdun marundinlọgọfa sẹyin, ni wọn bi Daniel Ọlọrunfẹmi Fagunwa nilu Oke Igbo to wa nipinlẹ Ondo
 • Ọmọ meji ni baba rẹ bi, to si ko ẹbi mọra
 • Omuwẹ to dantọ ni Fagunwa, to si maa n doola ẹmi awọn eeyan ati ẹru to ba fẹ ba omi lọ amọ iku odo lo papa pa omuwẹ rẹ
 • Ọdọ baba kan, ti wọn n pe ni Daniel Ojo lo gbe nilu Ibadan, to si tun kawe nibẹ
 • Ipo kinni ni Fagunwa maa n gbe nile ẹkọ tori pe ọpọlọ rẹ ji pepe
 • Fagunwa maa n gba itan lẹnu aburo baba rẹ obinrin to n jẹ Fabunmi
 • Nigba miran, o maa n sun si itẹ oku, igbo aginju tabi ko ti ara rẹ mọnu ile lati kọwe
 • Ẹmi kan lo maa n dari rẹ, to si maa n ba ẹmi airi sọrọ
 • Iyawo meji lo ni, Mary ati Olubankẹ, to si bi ọmọ marun
 • Akọbi Fagunwa, Olufẹmi ko si laye mọ
 • O le lo to ọsẹ mẹfa tabi ju bẹẹ lọ nin u igbo kiji-kiji lati kọwe
 • Ọjọ keje, osu kejila ọdun 1963 ni Daniel Ọlọrunfẹmi ri sinu omi ni Bussa, lẹba Lọkọja nipinlẹ Kogi, lasiko to lọ si odo Ọya (River Niger) lati kọwe, ti wọn si sin si ilu abinibi rẹ, Oke Igbo
 • Iwe Igbo Adimula lo n kọ lọwọ nigba to jade laye.

BBC Yoruba gbọ pe lati igba ti D.O Fagunwa ti dara ilẹ, Ijọba ko fi bẹẹ se ohunkohun lati maa se iranti rẹ, tawọn ẹbi rẹ ko si ri ọwọ ijọba rara.

Sugbọn bi onirese Daniel Ọlọrunfẹmi Fagunwa ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ, ko lee parun.