BBC: Ìrọ́ ní, a kò ṣètò owó ẹ̀kọ́ òfẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ gboyè fásítì

Àkọlé àwòrán BBC: Ìrọ́ ní a kò ṣé ètò owó ẹ̀kọ́ òfẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ gboyè fásítì

Àtẹ̀jíṣẹ́ kan ti ń jà ràin-ràin ká orí ẹ̀rọ ayélujara bayii pé, BBC ń ṣètò owó ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ gboyé àkọ́kọ̀ ní fásítì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà atawọn to nílò ẹ̀yáwó láti tẹ̀síwájú nílùú òyìnbó.

Àtẹ̀jíṣẹ́ náà tun fi kun pe, BBC ń fẹ́ láti ran ọ̀gọ̀run lọ́nà ẹgbẹ̀rùn àkẹ́kọ̀ọ́ jáde fásitì lọ́wọ́ láti tẹ̀síwáju nínú ẹ̀kọ́ wọn ní Fásítì tó wù wọn lágbàyé.

Nibayii, ileesẹ BBC lagbaye ati ni orilẹ-ede Naijiria ti wa n kede bayii pe, irọ to jinna sootọ ni ahesọ ọrọ yii, oun ko gbero lati seto iranwọ iranwọ owo eto ẹ́kọ fun akẹkọọ kankan ni Naijiria tabi loke okun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀
Àkọlé àwòrán Ilé iṣẹ́ BBC kò ṣe ètò owó ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́

Gẹgẹ bi ileesẹ BBC lagbaye ti wi, yoo dara kawọn araalu yẹra fun awọn iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ bii iru eyi.

BBC tun gba wọn nimọran lati yẹra fawọn onijibiti ẹda to lee fẹ maa gbe wọn mọra lati gba owo iforukọsilẹ lọwọ wọn.