Jemimah: Wàhálà àwọn òbí mi pọ̀ ló jẹ́ kí n gbé ara mi níyàwó

Lulu Jemimah Image copyright Lulu Jemimah

Arábìnrin kan tó ti sú láti maa dáhùn ìbéèrè lori ìdí tí kò fi tì i l'ọ́kọ, ti gbé ara rẹ̀ níyàwó.

O ti su Lulu Jemimah láti maa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìdì tó fi gbọdọ̀ l'ọ́kọ.

Ṣùgbọ́n, ìgbéyàwó kò ti lee sí ní ọkàn rẹ̀ rárá, nítorí pé óun kẹ́kọ̀ọ́ láti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò ní fásitì Oxford, tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Ṣùgbọ́n, ìgbéyàwó kò ti lee sí ní ọkàn rẹ̀ rárá, nítorí pé ó n kẹ́kọ̀ọ́ láti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò ní fásitì Oxford, tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Níṣe ni Lulu dájọ́ ayédèrú ìgbéyàwó, àmọ́ ó fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ojúlówó ìwé ìpè.

Ó yá aṣọ ìyàwó, ó sì lọ síbi tí ayẹyẹ ìgbéyàwó nàá yóò ti wáyé. Ìgbà tí ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀ ni ó tó sọ fún àwọn àlejò rẹ̀ pé kò sí ọkọ kankan.

Lulu jẹ́wọ́ pé, òun gbé ìgbésẹ̀ ọ̀hún láti lé fi rú bàbá àti màmá rẹ̀, tó wà ní ìlú wọn ní Uganda, l'ójú ní, ṣùgbọ́n ó sọ pé, ayẹyẹ nàá ni ọ̀nà pàtàkì láti so òun àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ papọ̀.

Gbogbo owó tó ná fún ayẹyẹ nàá kò sì ju ẹgbẹ̀rún kan àti àádọ́ta Naira tàbí Dọ́là mẹ́ta lọ̀, eyi si jẹ owó ọkọ̀ tó gbe de ibùdó ayẹyẹ nàá, nítorí pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá nkan ìpanu, owó àti ẹ̀bùn jọ fun un.

Image copyright Lulu Jemimah

Lulu sọ pé ''ara n yá mi láti mú àfojúsùn mi láti jẹ́ ọ̀mọ̀wé ṣẹ.''

''Ṣùgbọ́n nkan ẹyọkan tí ẹbí mi n bá mi sọ ni ìgbà tí màá ṣe ìgbéyàwó - òhun ló ṣe pàtàkì jù ní ìlú tí mo ti wá ní Uganda - ìgbà tí màá bímọ ló sì tẹ le.''

"Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni bàbá mi ti kọ ọ̀rọ̀ tí yóò sọ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó mi''

''Àdúrà kan ṣoṣo tí màmá mi sì maa n gbà fún mi láti ìgbà tí mo ti di obìnrin, kò ju ọkọ níní lọ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lulu ti ṣe àṣeyọrí lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ l'órílẹ̀-èdè Australia, tó sì tún ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléèṣẹ́ kan nínú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, ohun kan tó kan ẹbí rẹ̀ ni ìgbà tí yóò mú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ wá sílé, tí yóò sì ṣe ìgbéyáwó.

Image copyright Lulu Jemimah
Àkọlé àwòrán Lulu Jemimah

Ìgbà tó ṣe àbẹ̀wò sí Uganda l'óṣù Kẹjọ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kéjìlélọ́gbọ̀n rẹ̀, ní eròngbà nàá wọ́ ọ́ l'ọ́pọlọ.

Lulu sọ pé ''ní kété tí mo fi ìwé ìpè ránṣẹ́, ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pè mí pé taa ni ọkọ ìyàwó, ṣùgbọ́n mo sọ pé ìyàlẹ́nu ni mó fẹ́ fi ṣe fún wọn.''

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá àti bàbá Lulu kò wá fún ayẹyẹ nàá, Lulu padà sọ fún wọn.

Lulu sọ pé, bàbá òun kò tì sọ ohunkóhun nípa ìṣẹ̀lẹ̀ nàá, ọ̀rọ̀ nàá jẹ́ kàyéèfì fun un, ó sì tún dùn ún.

Lulu padà ṣàlàyé fún màmá rẹ̀ pé, aṣọ ìgbéyàwó jẹ́ àpẹrẹ pé òun ti ṣetan láti l'ọ́kọ.