Ìjámbá ọkọ̀: Ẹ̀mí mẹ́rin sọnù sínú ìjámbá ọkọ̀ n'Íbàdàn

Ẹni kẹrin dúró jẹ́ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ọkọ̀ epo nàá kan an ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèéjì, ó sì tún kú kí wọ́n tó ò gbe dé ilé ìwòsàn.
Àkọlé àwòrán Ẹni kẹrin dúró jẹ́ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ọkọ̀ epo nàá kan an ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèéjì, ó sì tún kú kí wọ́n tó ò gbe dé ilé ìwòsàn.

Omijé ló gba ojú àwọn ènìyàn ní agbègbè Ring Road nílùú Ibadan lẹ́yìn tí ìjàmbá ọkọ kan gba ẹ̀mí ènìyàn mẹ́rin lọ.

Akọ̀ròyìn BBC tó bẹ ibi tí ìjàmbá nàá ti wáyé wò jábọ̀ pé ìjàmbá nàá wáyé láàrin ọkọ̀ agbépo iléèṣẹ́ Total kan, àti ọkọ̀ takisí Micra kan tó fi mọ ọ̀kadà kan ní ọjọ́ Ẹtì ní òpópónà tó lọ láti Challenge sí Ring Road.

Ènìyàn mẹ́rin; lára wọn ni obìnrin kan àti ọmọ ti kò tí ì le pé ọdún kan tó pọ̀n sẹ́yìn rẹ̀, ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ nàá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIjamba ọkọ le m'ẹmi lọ

Àwọn ti ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣojú wọn sọ fún akọ̀ròyìn BBC Yoruba pé ọkọ̀ agbépo ọ̀hún tó kún bámú fún epo ni bíréèkì ọkọ̀ rẹ̀ déède kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ní apá ibi tí ọ̀nà naa ti da gẹ̀gẹ́-gẹ̀rẹ́, èyí tó mú kí o fara ti takisí Micra nàá 'láti ràn án lọ́wọ́.'

ṣùgbọ́n ti Micra naa ya ara rẹ̀ kúrò, èyí tó mú kí ọkọ̀ agbépo nàá lọ kọ lu alùpùpù (ọ̀kadà) kan tó fẹ́ já àwọn èèrò tó gbé; obìnrìn nàá àti ọmọ rẹ̀.

Ṣùgbọ́n, orí kò kó ọlọ́kadà nàá àti àwọn èérò rẹ̀ yọ nítorí pé l'ójú ẹsẹ̀ ni gbogbo wọ́n kú.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Ẹni kẹrin dúró jẹ́ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ọkọ̀ epo nàá kan an ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèéjì, ó sì tún kú kí wọ́n tó ò gbe dé ilé ìwòsàn.

Ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò tó wà ni ìbi tí ìjàmbá nàá ti wáyé ti tẹ awakọ̀ ọkọ̀ epo nàá, tí wọn kò sì jẹ́ kí àwọn aráàlú pá, tàbí dáná sun ọkọ̀ epo rẹ̀.

Bákan nàá ni àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ẹ̀ṣọ́ ojúpópó, FRSC, ti kó àgékù ara àwọn tó kú lọ sí ilé ìgbókùú sí.

Related Topics