Agneroh: Ohun gbogbo tí ẹ bá rí lórí ẹ̀rọ ayélujára kọ́ ni òtítọ́

Arlène Agneroh Image copyright CHRISTIAN SHABANTU MPENGA
Àkọlé àwòrán Arábìnrin Arlène Agneroh sọ ìrírí rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujáre lẹ́yín tò fi àwòrán ọ̀hún àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọkùnrin tí wọ́n ti wọ asọ kan náà sórí afẹ́fẹ́.

Arabinrin to jẹ ọmọwe ati gbajumọ lawujọ, Arlène Agneroh sọ iriri rẹ lori bi awọn eniyan se ma n fi agbara mu awọn ọmọbinrin to ti to oju bọ, lati lọ fẹ ọkọ, nitori abamọ nla ni loju wọn ti obinrin to ba balaga, ko ba fẹ ọkọ lasiko.

Ọrẹ Arlẹ̀ne kan lo fi iwe ipe ransẹ si i wi pe, oun se igbeyawo ni Kinshaha, to jẹ olu-ilu Democratic Republic of Congo, ti oun ati ọrẹ ọkunrin rẹ si jọ wọ asọ kan naa gẹgẹ bo se wọpọ laarin awọn ẹya ilẹ naa, lati ma a da asọ ẹbi lasiko igbeyawo.

Arlene ni, oun ati ọrẹ oun ọkunrin ti wọn jọ joko papọ ni wọn wọ asọ kan naa, ti wọn si ya aworan lati fi si ori ẹrọ ikansiraẹni Facebook.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Ọrẹ wọn miran to wa si ibi igbeyawo naa, to ya awọn aworan lorisirisi lo fi si ori itakun rẹ ni Facebook.

Arlene ni, ka to wi ka to fọ ni ipe bẹrẹ si ni ja lu ipe lori ẹrọ ilewọ oun ati gbogbo oju opo ikansiraẹni, ti awọn eniyan si n ki oun ku orire igbeyawo ati wi pe ọjọ wo gangan ni igbeyawo ọhun, ki awọn ba le wa yẹsi.

‘Ohun gbogbo tí ẹ bá rí lórí ẹ̀rọ ayélujára kọ́ ni òtítọ́’

N se ni ẹnu ya Arlene, to si pinnu pe oun ati ọrẹ oun naa yoo ya aworan miran ni aaye ọtọ, lori aga ti wọn ma n pese fun awọn ọkọ ati iyawo lọjọ igbeyawo wọn, lati fi kọ awọn eniyan ni ọgbọn wi pe, ohun gbogbo to dan kọ ni wura.

Ninu ọrọ rẹ, Arlene ni ọrọ ọhun ju ti tẹlẹ lọ, ti awọn miran ti ẹ n beere fun gbagede ti wọn ti fẹ se igbeyawo naa, ati wi pe, awọn mọlẹbi ati ibatan ti oun ko gburo lati bii ogun ọdun sẹyin bẹrẹ si ni pe oun.

Image copyright LARISSA DIAKANUA
Àkọlé àwòrán Kii se gbogbo aworan ti eniyan ba fi si oju opo ikansiraẹni ni o jẹ otitọ tabi ki awọn eniyan ma a sọ oun ti oju wọn kori
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

Lẹyin eyi ni Arlene wa gbe igbese lati kilọ fun awọn eniyan lori ẹrọ ayelujara wi pe, gbogbo ohun to dan ko ni wura, nitori ọrẹ lasan ni awọn mejeeji, ti ko si si ohun to jọ igbeyawo ninu aye oun bayii.

Ati wi pe, kii se gbogbo aworan ti eniyan ba fi si oju opo ikansiraẹni, ni o jẹ otitọ tabi ki awọn eniyan ma a sọ ohun ti oju wọn ko ri.