Igbésẹ̀ Buhari láti yọ orúkọ Omisore àti Obanikoro kò bójú mú

Image copyright @MBuhari

Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Yorùbá kan tí korò ojú sí ìgbésẹ̀ ààrẹ Muhammadu Buhari fún yíyọ oríkọ Sẹnátọ Iyiola Omisore àti Musiliu Obanikoro kúrò nínú àwọn orúkọ ti wọn fi síta pé wọn ò gbọdọ̀ rìnrìn àjò lọ sí òkè òkún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ọ̀hún sọ èyí di mímọ̀ nínú àtèjáde kan tí ààrẹ ẹgbẹ́ náà Olalekan Hammed àti akọ̀wé ẹgbẹ́ Olawale Ajao fọwọ́sí nílùú Osogbo lójọ́ ìsinmi.

Wọn ní yíyọ orúkọ̀ àwọn olóṣèlú méjèèjì ọ̀hún túbọ̀ ń fi lọ́lẹ̀ pé gbígbogun tí ìwà jẹgúdújẹrá tí ìjọba Buhari ń jà ń fári apá kan dápákan sí ni.

Awọn ọ̀dọ́ Yorùbá ọ̀hún sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti ríi pé ìjọba yọ orúkọ àwọn olóṣèlú méjèjì tí wọn ni ẹsun ìkówójẹ lọ́rùn

PDP: Buhari ni kẹ mú tí ibi bá se ọmọ ẹgbẹ́ alátakò

Muhammadu Buhari Image copyright BayoOmoboriowo

Ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi ni Naijiria, PDP ni, oun kọ igbesẹ iṣakoso aarẹ Muhammadu Buhari lati maa lo aṣẹ onikumọ tabi dẹyẹ si ẹgbẹ tabi ẹya kankan ni orilẹ-ede naa.

PDP ni, oun tako aṣẹ ti Buhari pa lati fi ofin de awọn ọmọ Naijiria kan lati ma se rinrinajo lọ silẹ okeere.

Akọwe ipolongo ẹgbẹ PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan, ninu ikede kan to fi sita sọ pe, ọna lati gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako, to fi mọ awọn ti Buhari n foju wo gẹgẹ bi ọta rẹ, awọn olori ẹsin ati awọn oniṣowo, ti wọn n foju wo pe, o tako idibo yan Buhari gẹgẹ bi aarẹ fun saa keji, ni asẹ naa wa fun.

PDP ti wa kesi awujọ agbaye, lati di ẹbi ru eto iṣakoso Buhari ti iṣẹlẹ buruku kankan ba ṣẹlẹ si olori ẹgbẹ oṣelu alatako kankan, to fi mọ awọn oniṣowo pataki tabi olori oṣelu jakejado Naijiria, lasiko ti imurasilẹ lọ lọwọ fun eto idibo ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé ẹ rántí orin - Má ṣe jẹ́jẹ́ ma wà mi lọ?

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Abamẹta ni ileeṣẹ Aarẹ Naijiria kede pe, oun fi ofin de awọn aadọta awọn ọmọ Naijiria to jẹ eekan ilu, lati mase rinrinajo lọ si ilẹ okeere.

Bo tilẹ jẹ wi pe wọn ko gbe orukọ awọn aadọta eniyan naa sita, sibẹ, agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu to fi ikede naa sita sọ pe, awọn ti ọrọ̀ kan jẹ awọn eeyan to ni dukia ti owo rẹ to aadọta miliọnu Naira, ti wọn si ti fi ẹsun iwa ibajẹ kan wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌrẹ Falọmọ: Buhari yóò rí ìbò Yorùbá gbà ju Atiku, Ọbasanjọ lọ

Shehu salaye pe, aṣẹ ti aarẹ Buhari pa ọhun jẹ ọkan lara ọna lati ri daju pe, ofin ti wọn n pe ni 'Executive Order Number 6' fidimulẹ, eyi ti ko faaye gba ẹnikẹni ti o ba ni iru dukia bẹẹ, ti ijọba si n wadi rẹ fun ẹsun iwa ibajẹ, lati raaye fi orilẹ-ede Naijiria silẹ, titi ti wọn yoo fi gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ wọn.

Bakan naa ni shehu sọ pe, 'ijọba n sọ bi awọn ti ọrọ ọhun kan ṣe n nawo lati le ri daju pe wọn ko ta iru dukia bẹẹ, tabi dọwọ bo iṣẹ iwadi loju.

Ati pe, aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun Agbẹjọro agba to tun jẹ minisita fun eto idajọ̀ ni Naijiria, lati ri daju pe ofin naa ṣe iṣẹ rẹ.

O si rọ gbogbo ọmọ Naijiria rere pe, ki wọn fi ọwọ sowọpọ pẹlu eto iṣakoso aarẹ Buhari ninu igbogun ti iwa ibajẹ ni ibamu pẹlu ofin ọdun 1999.