Ìlú Igbo-Ọra: Ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ayẹyẹ ọdun ibeji fún ìgbà àkọ́kọ́

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa onka awọn eeyan ilu fidirẹ mulẹ wi pe ilu Igbo Ọra lo ni onka awọn ibeji to pọ julọ l'agbaye.
Àkọlé àwòrán Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa onka awọn eeyan ilu fidirẹ mulẹ wi pe ilu Igbo Ọra lo ni onka awọn ibeji to pọ julọ l'agbaye.

Tilu, torin ati oniruuru asọ alarambara ni awọn ibeji, ibẹta, awọn obi, aṣoju ijọba ati awọn eeyan ilu peju pesẹ silu Igboọra nipinlẹ Ọyọ lọjọ Abamẹta fun ayẹyẹ ọdun awọn ibeji.

Ayẹyẹ naa to jẹ akọkọ iru rẹ lo waye nipasẹ ajọsepọ laarin ẹka ile iṣẹ iroyin, aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Ọyọ, ijọba ibilẹ Ibarapa, ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu IgboỌra ati ajọ to n risi idagbasoke awọn ibeji l'agbaye.

Lara awọn eniyan pataki to ba wọn pejọ pọ sibi ayẹyẹ naa ni alakoso fun iroyin, asa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Ọyọ, Oloye Toye Arulogun, alaga ijọba ibilẹ Ibarapa, Họnọrebu Ibrahim Habib Adegoke ati bẹẹbẹẹ lọ.

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa D.O Fágúnwà?

Àwọn ìbejì yabo Igbó Ọrà fọ́dún ìbejì lágbàáyé

‘‘Àwọn egúngún ń mu òògún olóró ló ń jẹ́ kí wọ́n sì ìwà hù’

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo kẹ́kọ̀ọ́ fásitì sùgbọ́n aṣọ òké ló ń jáwó báyìí'

Ọba Jamiu Adedamọla Badmus, JP, Ayelẹsọ III, Olu Aso ti Iberekodo naa ko gbẹyin ninu awọn ọba ati ijoye to darapọ mọ ọdun naa.

Ninu ọrọ rẹ nibi ipejọpọ naa, alakoso fun iroyin, aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun ṣalaye wi pe ẹbun lati ọrun wa ni ilu IgboỌra jẹ fun ipinlẹ Ọyọ ati orilẹede Naijiria l'apapọ, gẹgẹ bi ilu ti ibeji ati awọn ọmọ to ju meji lọ ti pọ julọ ni agbaye.

Àkọlé àwòrán Arulogun sọ wi pe akanṣe eto naa duro gẹgẹ bi ipilẹ fun ilepa lati ṣe akojọpọ awọn ibẹji l'agbaye.

Arulogun fi kun ọrọ rẹ wipe akanṣe eto naa duro gẹgẹ bi ipilẹ fun ilepa lati ṣe akojọpọ awọn ibẹji l'agbaye, pẹlu afojusun akọsilẹ ninu iwe to n ṣe onka awọn iṣẹlẹ ayanilẹnu l'agbaye, 'Guiness Book of Record'.

O tẹsiwaju wipe ajọdun ibeji tọdun yii jẹ ọkan lara awọn alakalẹ eto fun ayajọ ọjọ irinajo igbafẹ ni agbaye fun ọdun 2018, lati ọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, pẹlu alaye wipe gbogbo ọna ni ijọba ipinlẹ naa n gbaa lati rii daju wi pe idagbasoke de ba eto ọrọ aje, aṣa ati ẹka irinajo igbafẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ wo àrà tí ẹ le fi gèlè dá láàrín ìṣẹ́jú mẹ́ta

"Ọdun awọn ibeji yoo fun wa ni anfani lati ṣe afihan ilu Igbo-Ọra gẹgẹ bi ilu ti o tayọ ninu onka ibeji ati ọmọ to ju mẹji lọ lagbaye.

A fẹ rii daju wipe ipejọpọ naa n waye ni ọdọọdun, ki a le fi aye gba awọn eto l'oriṣiriṣi ti yoo sọ Igbo-Ọra di ibudo igbafẹ fun awọn arinrinajo lati ilẹ okeere."

Àkọlé àwòrán Ẹṣẹ ko gba eero nibi ayẹyẹ ọdun ibeji niluu Igbo-Ọra

Arulogun ni lẹyin ajọdun tọdun yii, ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo gbiyanju lati ṣe ọdun ibeji ni ẹkun iwọ-oorun guusu ki o to di wipe yoo kari orilẹede Naijiria ati gbogbo agbaye.

Lara awọn eto to waye nibi ayẹyẹ naa ni orin idaraya, idije lọlọkanojọkan laarin awọn ibeji, yiyanfanda bi ologun, ifamiẹyẹdanilọla ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa onka awọn eeyan ilu fidirẹ mulẹ wi pe ilu Igbo Ọra lo ni onka awọn ibeji to pọ julọ l'agbaye, pẹlu alaye wipe okere tan, ibeji mejidinlọgọjọ lo ma a n wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹrun kan ti wọn ba bi nilu Igbo-Ọra.

Eleyi si tayọ ibeji marun un pere to ma a n wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹrun kan ti wọn ba bi ni gbogbo ilẹ Yuroopu.

Ọpọlọpọ awọn eeyan gbagbọ wipe Amala ati ọbe Ilasa ti awọn eeyan ilu naa kundun lo n ṣokunfa ibeji ati ọmọ to ju meji lọ, bẹẹ sini awọn ẹlomii ri iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun ti o ti ọwọ Ọlọrun wa.

Related Topics