Ẹ lọ mú ẹ̀rí ibi tí a ti gba owó wá- NLC/TUC

NLC/TUC Chairmen
Àkọlé àwòrán,

'Àwa ò gba owó lọ́wọ́ Fayose ooo'

Àìtó eyín ká làá dọwọ́ bòó, àwọn olórí òṣìṣẹ̀ méjèjì tí wọn fi ẹsùn owó rìbá kan Nigeria Labour Congress (NLC) àti Trade Union Congress (TUC) ti fèsì.

Wọn ni irọ́ pátápátá ní àwọn to fi ẹ̀sùn kan ń pa bíkò ṣe pé èdè aiyedè tó ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ló faa àhesọ.

Lásìkò tí BBC Yoruba ń ba àwọn alága ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì sọ̀rọ̀ Ade Adesanmi ti NLC àti Odunayo Adesoye ti TUC sàlàyé pé gbogbo ẹni to bá ni ẹ̀rí lórí ọ̀rọ̀ náà kó jáde wa.

Alága NLC ati TUC sọ́ òhun tó fa ìdì abájọ ìbani lórúkọ jẹ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ẹ lọ mú ẹ̀rí ibi tí a ti gba owó wá- NLC/TUC

Ekiti Workers: Ìbásepọ̀ àìtọ́ láàárín Fayose àtàwọn olórí wa ló fìyà jẹ wá

Àkọlé àwòrán,

‘Ẹ wádìí ₦264m táwọn asaájú òsìsẹ́ gba lásìkò Fayose’

Àwọn òṣìṣẹ̀ ìpínlẹ̀ Ekiti tí kọ̀wé ẹ̀hónú sí ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ìpínlẹ̀ Ekìtì, láti ṣe ìwádìí lórí mílíọ̀nù mẹ́fà tí gomina ana nipinlẹ naa, Ayọdele Fayose ń san fáwọn olórí òṣìṣẹ́ lósoosù, tó fi di mílíọ̀nù lọna ọtalerugba o le mẹfa náírà ( 264m).

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Onigbajamọ: Báwo lẹ se gbọ́ èdè Yorùbá sí?

Nínú ìwé ẹ̀hónú náà tó jáde ní ọjọ́ Kẹ́tàlélógún osù Kọkanla, àwọn òsìṣẹ́ lábẹ́ àsíá Ekiti Workers Rescue Team, sàlaàyé pé, ninu mílíọ̀nú mẹ́fà náírà ti wọn n yọ losoosu, mílíọ̀nù márun ń lọ sọ́dọ̀ ẹgbẹ osisẹ NLC nígbà ti mílíọ̀nù kan ń lọ sọ́dọ̀ ẹgbẹ osisẹ TUC, eyi tí kò fojú hàn nínú ìwé owó ẹgbẹ́.

Ìwé ẹ̀hónú náà, tí alága ẹgbẹ́, Ojo Ayodeji àti akọ̀wé ẹgbẹ́, W.A Ajayi fọ́wọsi fi kún un pé, ìbáṣepọ̀ tí kò tọ́ tó wà láàrín àwọn olórí òṣìṣẹ́ àti gómìnà àná ní kò jẹ́ kí àwọn lè rí ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́ gbà nínú ìṣèjọba. Fayose.

Oríṣun àwòrán, @FAYOSE/TWITTER

Nínú èsì ìwádìí ayẹ̀wé owó wò fún ti ọdún 2017, ó hàn gbangba pé ,TUC gba mílíọ̀nù kàn Naira lósoosù tí NLC sì ń gbà mílíọ̀nù márùn-ún náírà lábẹ́ ìjọba Fayose.

Sùgbọ́n alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Ade Adesanmi tako ọ̀rọ̀ yìí, ó ní àwọn kò gba owó lásìkò ìsèjọba Fayose àti pé ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò sí lábẹ́ àkóso ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Fayoṣe vs EFCC: Agbẹnusọ Fayoṣe ní àwọn ti pèsè ohun gbogbo tó yẹ

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀sán ọjọ́ Aje ni Fayoṣe kérò l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi, ní ìpínlẹ̀ Eko.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀, Ayọdele Fayoṣe, ti gba ìtúsílẹ̀ l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Ile ejọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ pàṣẹ ìtúsílẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tó ti san gbogbo nkan tí ilé ẹjọ́ bèérè fún láti gba onídúró rẹ̀.

Ọ̀sán ọjọ́ Aje ni Fayoṣe kérò l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi, ní ìpínlẹ̀ Eko.

Àkọlé fídíò,

Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Agbẹnusọ fún Fayoṣe, Lere Ọlayinka ló fìdí èyí múlẹ̀ fún BBC Yoruba.

Bákan nàá ló kéde lójú òpó Twitter rẹ̀ pé ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kọkànlá ni ìgbẹ́jọ́ yóò maa tẹ̀síwájú.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Fayoṣe ti wà l'ọ́gbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi nípìnlẹ̀ Eko, lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gba onídúró rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú báṣu-bàṣu lásìkò tó fi jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti.

"A ti ṣe ohun gbogbo tí òfin ní ká ṣe, kí wọ́n dá Fayoṣe sílẹ̀ ló kù."

Lere Ọlayinka tó jẹ́ agbẹnusọ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí, Peter Ayodele Fayoṣe ti sọ wí pé gbogbo ìwé àti ẹ̀rí ni àwọn ti kó lọ síwájú ilé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ sì ti rí àrídájú rẹ̀.

Ó sọ ọ́ síwájú pé "ìrètí wà pé títí ọjọ́ Ajé, Fayoṣe yóò jáde látìmọ́lé, a dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà fún àtìlẹ́yìn wọn".

Ta ló dà bí Ọlọ́run Fayoṣe?

Ile ẹjọ giga apapọ to wa ni Ikoyi ni ilu Eko ti fun gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ni anfani oniduro lori igbẹjọ ẹsun ṣiṣowo ilu baṣubaṣu ati gbigba owo kotọ ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC n fi kan an.

Àkọlé fídíò,

'Ta ló dà bíi Ọlọ́run Fayoṣe' lorin tó ń jáde nílé ẹjọ́

Ọjọru ni ileẹjọ naa kede fun gbigbọ ẹjọ lori ẹbẹ fun gbigba oniduro Ayọdele Fayoṣe, babi si ni yara igbẹjọ kun fun awọn agbẹjọro atawọn ololufẹ gomina ana ni ipinlẹ Ekiti ọhun to bẹẹ gẹẹ ti Onidajọ Olatoregun to n gbọ ẹjọ naa ni lati paṣẹ fun gbogbo awọn eeyan ti ko ba tii ṣe agbẹjọro ti wọn ko si ri aaye joko si lati jade sita.

Ikọ agbẹjọro Fayose rọ ile ẹjọ naa lati fi ojuure wo ẹbẹ rẹ fun gbigba oniduro rẹ. O ni olorukọ nla lawujọ ni gomina ana naa ti ko si lee sa mọ ofin lọwọ paapaa julọ pẹlu bi o ṣe jẹ wi pe ko si akọsilẹ pe irufẹ igbesẹ bẹẹ ṣẹlẹ ri sii.

Kini awọn ohun ti ile ẹjọ n beere fun beeli Fayose?

Àkọlé àwòrán,

Onidajọ to n gbọ ẹjọ naa ni ọgba ẹwọn ikoyi ni Fayoṣe yoo wa titi ti yoo fi mu awọn ilana beeli rẹ ọhun ṣẹ

Onidajọ Ọlatoregun to n gbọ ẹjọ naa ninu idajọ to gbe kalẹ lori boya ki wọn gba beeli rẹ tabi rara, ni ile ẹjọ naa yoo faye silẹ fun un gbigba oniduro rẹ bi o ba ti lee mu awọn ilana ti ile ẹjọ la kalẹ fun beeli rẹ ṣẹ.

Ninu idajọ rẹ, adajọ to n gbọ ẹjọ naa ni ki Fayose san owo iduro aadọta miliọnu naira ki o si jọwọ iwe irinna rẹ soke okun si akoso ile ẹjọ naa.

Bakan naa ni ile ẹjọ tun bere fun oniduro meji ti wọn gbọdọ ni dukia bi ile tabi ilẹ ni ilu Eko ti wọn si gbọdọ ni ẹri owo ori sisan fun ọdun mẹta sẹyin.

Onidajọ to n gbọ ẹjọ naa ni ọgba ẹwọn ikoyi ni Fayoṣe yoo wa titi ti yoo fi mu awọn ilana beeli rẹ ọhun ṣẹ.

Ariwo ati ijo ayọ laarin awọn ololufẹ Fayose lẹyin idajọ naa.

Idunnu nla, Ijo ati ariwo ayọ ni wọn n pa ni ayika ile ẹjọ naa to bẹẹ gẹ ti gomina ana naa ni lati ke si wọn ki wọn dakẹ ariwo nitori gbagede ile ẹjọ ni wọn wa.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, agbẹnusọ fun Ayọ Fayose, Lere layinka, ni idunu nla lo jẹ fun wọn pe ile ẹjọ fi aye silẹ fun gbigba oniduro gomina ana naa.

Àkọlé fídíò,

'EFCC ti wá dà bíi ara ẹgbẹ́ òṣèlú APC'

O ni ipenija nla ni igbẹjọ Fayoṣe jẹ fun APC ati gbogbo awọn ti wọn ti fi ẹsun ikowojẹ kan labẹ aarẹ Buhari ati iṣejọba rẹ.

Bakan naa lawọn obinrin kan ti wọn ni awọn wa lati ilu Ado ekiti si ilu Eko nitori igbẹjọ naa ṣalaye pe "ajọyọ nla lo jẹ, o si da wa loju pe ọga wa yoo bọ ninu idamu yii."

Lasiko ti a fi n kọ iroyin yii, awọn agbẹjọro rẹ ko tii ri ilana beeli rẹ muṣẹ.

Bakan naa si ni awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti gbe e pada si ọgba ẹwọn ikoyi titi di igba ti yoo fi lee pari eto gbogbo lori beeli ọhun.

Ile ẹjọ ti gba oniduro Gomina tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe.

Àkọlé àwòrán,

Wọn si ti sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018

Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti gba onídùúró gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí, Ayodele fayoṣe lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn an, wọ́n ti gbé e lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.

Ọjọru ni ajọ to n gbogunti ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC, pada gbe Fayoṣe lọ sile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa ni adugbo Ikoyi nipinlẹ Eko.

Ninu idajọ to gbe kalẹ, adajọ to n gbọ ẹjọ awọn ẹ̀sun ti wọn fi kan Fayoṣe, Onidajọ Ọlatoregun, sọ pe ki wọn gba oniduro Fayose pẹlu aadọta miliọnu Naira, ati wi pe ko fi iwe idanimọ irinna silẹ okeere rẹ sile ẹjọ.

Bakan naa ni adajọ sọ pe o gbọdọ mu awọn meji ti yoo ṣe oniduro rẹ wa. Wọn si gbọdọ ni iwe ẹri owo ori ti wọn san fun ọdun mẹta, ati ilẹ̀ tabi ile to j'oju nigbese.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn alátìlẹyìn Fayoṣe tẹ̀lè lọ sílé ẹjọ́

Wọn si ti sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018.

Ni ọjọ Aje ni ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC, gbe Fayoṣe lọ si ile ẹjọ giga apapọ to wa ni Ikoyi nilu Eko lori ẹsun ikowojẹ ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ati gbigbowo rin lọna ti ko bofinmu, eleyi ti gomina ana ọhun dahun si pe oun ko jẹbi.

Fayoṣe gunlẹ si ile ẹjọ naa ni nkan bi aago mẹjọ owurọ Ọjọru, ni awọn alatilẹyin rẹ duro wamu-wamu lati ṣe koriya fun.

Eero kun ile ẹjọ debi wi pe awọn kan ko raaye joko, ti adajọ to n gbọ ẹjọ naa de awọn ti ko raaye joko, eyi ti ko yọ awọn akọroyin silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn agbẹjọro rẹ beere fun ore ọfẹ ile ẹjọ naa lati lee gba oniduro rẹ ẹyin ti wọn ni awọn ti kọwe ẹbẹ fun gbigba oniduro rẹ ranṣẹ siwaju ile ẹjọ naa ṣaaju ni ọjọ ẹti.

Ni ọjọru ni ile ẹjọ naa sun igbẹjọ rẹ si lati sọrọ lori boya ki wọn fun un laye lati gba oniduro tabi ki wọn ṣi fi si ahamọ.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Fayoṣe síwájú di Ọjọ́rú

Wọ́n ti gbé ẹjọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀, Ayodele Fayose sí iwájú adájọ́ àgbà Ọlatoregun ní ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.

Wọ́n mú Fayose wọ inu kòtò ìjẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn agbẹjọ́rò ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí àwn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Bí wọ́n ṣe ń ka gbogbo àwọn ẹ̀sùn náà ni Ayo fayose ń dáhùn wí pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan;

Agbẹjọ́rò: Ẹsun pe Ọgbẹni Ayọ Fayoṣe ati Ọgbẹni Abiọdun Agbele ti ajọ naa sọ pe o ti na papa bora gba N1.219 biliọnu ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2014, lati fi ṣeto ipolongo ibo gomina rẹ lọdun 2014 nipinlẹ Ekiti.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Agbẹjọ́rò: Ẹsun pe Ọgbẹni Ayọ Fayoṣe ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2014, tẹwọ gba owo ti iye rẹ jẹ miliọnu marun dọla owo ilẹ amẹrika lọwọ Sẹnetọ Musiliu Obanikoro, ẹni to jẹ minisita abẹle feto abo nigba naa. Owo yii ju iye ti ofin la kalẹ fun ẹnikẹni lati gba lorilede Naijiria.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Àkọlé àwòrán,

Fayoṣe ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko

Agbẹjọ́rò: Ẹsun pe Fayoṣe gbe owo to jẹ ọọdunrun miliọnu naira, N300 miliọnu, ti ajọ EFCC ni o jẹ ara owo ti ko bofinmu, si aṣuwọn ifowopamọsi rẹ to wa pẹlu banki Zenith ni ọjọ keje oṣu kẹrin ọdun 2015.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Agbẹjọ́rò: Pe Ayọdele Fayose ati ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ spotless limited jumọ gba owo kan ti apapọ rẹ jẹ N317 miliọnu laarin ọjọ kẹtadinlogun osu kẹfa si ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2014.

Owo yii ni ajọ EFCC ni o wa lara owo kan ti ko bofinmu.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Agbẹjọ́rò: Pe Fayose tun gba owo kan laarin ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹfa si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹjọ ti owo naa ko si bofinmu. Iye owo ọhun jẹ N305.760 miliọnu.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Àkọlé àwòrán,

Fayoṣe àti Fani Kayode ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko

Lẹ́yìn ẹ̀sùn ìkarùn ún, ni agbẹjọ́rò Fayoṣe bá bèrè lórúkọ rẹ̀ pe ki wọn gba oníduró fún òun. Ó ní ọjọ́ ẹtì tó kọjá ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi tó àwọn létí tí àwọn sì ti kọ̀wé láti gba oníduró.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọ́rò Oyedepo tó ń ṣojú àjọ EFCC sọ pé òun tẹ́wọ́ gbà á. Adájọ́ ní Fayoṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ súgbọ́n nígbẹ̀yìngbẹ́yìn, ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú di Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ (ọjọ́kẹ́ẹ̀rǹlélógún ọṣù kẹẹ̀wá).

Fayoṣe bẹ̀rẹ̀ ìjẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga Eko

Àkọlé àwòrán,

Fayoṣe ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ ajé, ọgbà ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko níbi tí ìjẹ́jọ́ Fayose yóò ti wáyé ti ń kórajọ́ fún iṣẹ́ òòjọ́.

Àwọn agbẹjọ́rò sì ti ń wọ'ṣẹ́ ní ìgbáradì fún ẹjọ́ náà.

Ni owurọ ọjọ aje ni gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose yoo foju ba ile ẹjọ.

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Eko

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ni ọjọ iṣẹgun ni Fayoṣe farahan ni ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC gẹgẹ bii ileri rẹ to ṣe ninu lẹta kan to ti kọ lasiko ti o ṣi fi wa lori ipo gomina.

Lati igba naa ni o si ti wa ni ahamọ ajọ naa ni ilu Abuja.

Ni irọlẹ ọjọ aiku ni ajọ EFCC gbe Fayoṣe lọ silu Eko lati lọ jẹjọ lori ẹsun mọkanla ti wọn fi kan an eleyi to nii ṣe pẹlu ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Fayoṣe ni gbigba oniruuru owo lọna ti ko bofinmu, gbigba owo ẹyin lọwọ awọn ileeṣẹ kan ati fifi owo ilu ra ile kaakiri awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.