SERAP si Buhari: Pàṣẹ fún amòfin àgbà, EFCC láti ṣèwáàdí Ganduje

Gomina Umar Ganduje ati aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @GovUmarGanduje

Ajọ kan to n ja fun ẹtọ araalu ati ijọba rere, SERAP ti ke si aarẹ Muhammadu Buhari pe ko tete wa n kan ṣekan lori ẹsun gbigba owo riba ti wọn fi kan gomina ganduje tipinlẹ Kano.

Ninu lẹta kan ti o kọ si aarẹ Buhari, ajọ SERAP ni pẹlu fidio to n lọ kaakiri ninu eyi to ṣafihan gomina Ganduje nibi ti o ti n gbowo ẹyin yii, O di dandan ki aarẹ tete dari amofin agba orilẹede yii atawọn ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lati tete bẹrẹ iwaadi lori ẹsun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbedeke ọjọ mẹrinla ni wọn fun aarẹ lati bẹẹrẹ iwaadi gomina Ganduje nitori, "ẹsun riba gbigba tabi ṣiṣi ipo iṣejọba lo ti wọn ba fi kan ẹnikẹni nipinlẹ yoowu lorilẹede Naijiria kan gbogbo ọmọ Naijiria, nitori naa o si yẹ ko kọ iṣejọba rẹ lominu pẹlu."

Oríṣun àwòrán, @GovUmarGanduje

Lai pẹ yii ni awọn fidio kan bọ si ori ẹrọ ayelujara eyi ti o ṣafihan gomina ipinlẹ Kano ti o n gba owo dọla ilẹ Amẹrika lọpọ yanturu lọwọ ẹnikan ti wọn funra pe o jẹ Kọngila.

Bi o tilẹ jẹ pe Gomina Ganduje ti ṣalaye pe oun ko gba owo ẹyin lọwọ ẹnikẹ ri, sibẹ olori ileeṣẹ iroyin to gbe fidio naa sita, Jafar Jafar farahan niwaju ile aṣofin ipinlẹ Kano nibi ti o ti sọ pe ootọ ni gbogbo ohun to wa ninu fidio naa, o si fi ẹsun kan gomina naa pe lootọ lo gba owo ẹyin lọwọ awọn kọngila ti wọn gbe iṣẹ ijọba fun nipinlẹ ọhun.

SERAP wa ke si aarẹ Buhari pe o nilati ṣeto abo to peye fun oniroyin naa lọwọ ewu ti o lee fẹ wu u nitori aṣiri awọn alagbara ti o tu sita naa.

Àkọlé fídíò,

Omar Victor Diop: Ipa Áfíríkà nínú àkọsílẹ̀ ìwé kọja ògo tí wọ́n ń fún un lágbáyé

Ganduje kọ̀ láti yọjú sí Ilé Asòfin lórí ẹ̀sùn àjẹbànu

Oríṣun àwòrán, GANDUJE HALLACCI

Àkọlé àwòrán,

Ja'afar Ja'afar tí ò ń jẹ́jọ́ lórí fídìo tó s'àfihàn bí gomina ipinlẹ Kano ti ń gba rìbá dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ pé òtítọ́ ni.

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti kọ lati yọju si Ile Igbimọ Asofin ipinlẹ Kano lori ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan an.

Awọn igbimọ ti wọn yan lati Ile Igbimọ Asofin ipinlẹ naa n sewadii lori fidio ti akọrọyin kan fi lede to fi han pe gomina naa n gba riba.

Gomina Ganduje ran kọmisọna fun ọrọ to jẹ mọ iroyin ni ipinlẹ naa, Muhammad Garba lati lọ soju rẹ pẹlu lẹta ti ọga rẹ Ganduje kọ.

Àkọlé fídíò,

'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Lẹta naa sọ wi pe Gomina ipinlẹ Kano naa ko gba riba ri lati igba ti wọn ti bii, ati wi pe iruẹsun ajẹbanu pẹlu fidio yii ti sẹlẹ si Gomina Ipinle naa tẹlẹri, Ibrahima Shekarau ati Emir ti Kano.

Fídíò Ganduje: Akọ̀ròyìn fọwọ́ sọ̀yà pé òtítọ́ ni fídìo tí òun fi síta

Oludasilẹ iwe iroyin ori ayelujara kan, Daily Nigeria, Ja'afar Ja'afar to gbe fidio ibi ti Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti n gba owo jade si duro lori ẹsẹ rẹ pe fidio naa ko lẹja nbakan rara.

O fidi ọrọ naa mulẹ niwaju Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ kano to n se iwadi nipa fidio ọhun.

Àkọlé àwòrán,

Jafar Jafar niwaju igbimo ile asofin ipinle Kano

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbimọ ile naa ti saaju fi iwe pe Ja'afar Ja'afar lati wa wi tẹnu rẹ nipa fidio naa ti o n ja rain-rain.

Ninu fidio, nise ni Gomina Ganduje n ri owo dolla to gba lọdọ ẹnikan bọ inu apo rẹ.

Ìjọba Kano sọ pé Gómìnà kọ́ ló wà nínú fídíò rìbá gbígbà naa.

Oríṣun àwòrán, @GovUmarGanduje

Iroyin to tẹwa lọwọ so pe Oludasilẹ iwe Iroyin Daily Nigeria ọhun kọ lati jẹwọ ẹni to fi fidio owo gbigba naa sọwọ si i.

Amọ ṣa, o jọwọ ẹri to fi mọ ohun iko nkan elo ẹrọ ayarabiaṣa komputa pamọ si (hard disk) ati awọn nkan miiran.

Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ niwaju igbimọ iwadi, Jaafar Jaafar ni ile ise iroyin Daily Nigeria se iwadi ofintoto saaju ki wọn to gbe fidio ibi ti Ganduje ti n gba owo abẹtẹlẹ jade.

Ẹwẹ awọn akẹkọ kan ti fi atilẹyin wọn han si Gomina Ganduje pẹlu bi wọn ti ṣe gbe iwe ifẹhonuhan niwaju ile asofin Kano.

Loju opo Twitter awọn eyan ti n bẹnu atẹ lu igbese yi.

Ọjọ Aiku to kọja ni fidio kan gba ori ẹrọ ayelujara, eyi to ṣafihan gomina Abdullahi Umar Ganduje to n gba 'riba lọwọ agbaṣẹṣe kan.'

Ja'afar Ja'afar sọ pe, awọn oṣiṣẹ ijọba kan fi to oun leti pe, awọn akẹẹgbẹ wọn kan, lai ni ọwọ gomina Ganduje ninu, n gbeero lati kọlu oun.

Oniweeroyin ọhun ni, o da oun loju pe owo ti gomina gba ninu fidio naa jẹ ọkan lara awọn owo ti ko tọ, ti gomina maa n gba lọwọ oriṣiriṣi awọn kọngila to n ṣe awọn akansẹ iṣẹ ni ipinlẹ naa.

Ja'afar sọ pe ''ẹ̀rù ile ẹjọ́ ti ijọba ipinlẹ naa ni oun yoo gbe mi lọ ko ba mi, nitori mo mọ pe otitọ ni iroyin ti mo gbe jade.''

''Iwe iroyin mi kii gbe ayederu iroyin tabi eyi to le ba orukọ ẹnikẹni jẹ, jade . Gbogbo iroyin wa ni a maa n wadii daada ki a to gbe jade. A si ni ẹ̀rí to daju lori iroyin yii.''

Fidio naa kii ṣe ẹyọkan, ko da, o to mẹẹdogun tabi ko ju bẹ ẹ lọ. A kan da ọwọ duro lori gbigbe awọn fidio to ku jade ni, nitori aabo ẹmi mi ati ti ẹbi mi.

Oríṣun àwòrán, @GovUmarGanduje

Ṣe irọ ni fidio to ṣafihan Gomina Ganduje?

Aṣofin agba kan ni ile aṣofin apapọ ilẹ wa, Sẹ́netọ́ Ben Murray Bruce ti kede pe ẹ́bu lasan ni fidio kan to n ja rain-rain pe Gomina ipinlẹ́ Kano, Abdullahi Ganduje gba owo abẹtẹlẹ to to miliọnu marun dọla.

Murray Bruce ni iwadi oun nipa ọrọ naa ti fi han pe, owo idana ni gomina Ganduje n gba lori ọmọ rẹ obinrin, kii se owo abẹtẹlẹ lori isẹ agbase.

Loju opo Twitter rẹ, @BenMurrayBruce, ni Murray Bruce ti ṣiṣọ loju ọrọ yii faraye.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ aiku ní fọ́nrán kan gbòde níbi ti gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdulllai Ganduje, tí ń kó owó dọ́là sínú àpò agbádá rẹ̀ eyi tí Daily Nigerian gbé síta.

Àkọlé fídíò,

Ìjọba Ọ̀yọ́: Kò sí ilé kan tí wọn kò tíì bí ìbejì ní Igbó Ọrà

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà si ló tí ń gbarata lórí ọ̀rọ̀ náà pé, owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní Ganduje ń gbà lọ́wọ́ àwọn kọngila.

Oríṣun àwòrán, @GovUmarGanduje

Ahesọ ọrọ ni

Ṣugbọn ijọba ìpínlẹ̀ Kano ti fi àtẹ̀jáde kan síta lálẹ́ ọjọ aiku pé, àwọn yóò gbe ile iṣẹ́ ìròyìn náà àti akọ̀ròyìn Jafar Jafar lọ sílé ẹjọ́, ní tori pé wọn ń gbìyànjú àti ba gómìnà lórúkọ jẹ́ ni.

Agbẹnusọ fun Gomina Kano,Muhammad Garba salaye pe ayederu ni fọnran fidio naa a ti wi pe ẹni to gbe fidio naa jade ko ṣẹṣẹ ma wu iri iwa bẹ.

Lálẹ́ ọjọ Aiku ní wọn gbé fọ́nrán tí ẹnikan yọ́lẹ̀ ya, níbi ti gómìnà ń kó dọ́là tó tó mílíọ̀nù márùn sínú àpò agbádá rẹ̀, èyí ti wọn ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tó ń gbà lọ́wọ́ kọngilá tó fẹ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní.

#BabanrigaMobileBanking

Ọrọ yi ti mu iriwisi ọtọọtọ wa ti o si ti bi hastag kan to n ja rain rain loju opo Twitter-#BabanrigaMobileBanking .

Nise ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjírìa tí n sọ èrò wọn lórí fọnrán náà, tí wọn sì bẹnu àtẹ́ lu ìgbèsẹ̀ gómìnà Kano.

rẹ̀, ni, tòun, èrò, tiyín, ìgbésẹ̀, yìí