Ka nípa ọ̀nà tí agogo inú ara rẹ ń gbà ṣiṣẹ́

Foggy Lake at sunrise Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbéra kí o tàn - ọjọ́ tuntun wà ní iwájú re

Ǹjẹ́ o mọ̀ pẹ́ gbogbo ńǹkan abẹ̀mí lo ní agogo ara, láti orí kòkòrò àf'ojúrí (fungi) sí ènìyàn?

Ó dà bí ẹní pẹ́ gbogbo ńǹkan abẹ̀mí - àti kòkòrò àìf'ojúrí (bacteria) - ní agogo ara (circadian cycle): tó tó bíi wàkàtí mẹ́rìnlélógún tó sì ń ṣẹ atọ́kùn fún ìṣẹ̀mí wa.

Sùgbọ́n báwo ní ìwọ yóò ṣe mọ̀ bí agogo yìí ṣe ń ṣiṣẹ́?

1. Ọjọ́ ti pẹ́ tí agogo ara ti wà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọbẹ̀ ayé àtijọ́ yìí ní láti wá ọ̀nà àti tú ara rẹ̀ tò

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rò wí pé òòrun ba àwọn sẹ́ẹ́lì àkọ́kọ́ jẹ́. Nítorí ìdí ẹ̀yí ni wọ́n fi má ń tún ara wọ́n ṣe ní alẹ́.

2. Ìwọ nìkan kọ́ ló ní wọn

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igi mimosa kọ̀ nílo òrùn láti mọ̀ àsìkọ̀ tí yóò fẹ àwọn ewé rẹ̀

Wọ́n lérò wí pé gbogbo irú ńkan abẹ̀mí tó máa ń gba agbára láti inú òòrùn ló ní agogo ara (circadian rhythm), látí lè lo iná àti òkùnkùn .

Àyẹ̀wò ti fi hàn pé ewé igi mimosa yóò ṣí sílẹ̀ tàbí kó padé nínú òkùnkùn, nípasẹ̀ agogo ara rẹ̀, yàtọ̀ sí oòrun.

3. Wọ́n máa ń fún ìṣẹ̀mí lágbárá

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olú (mushroom) gáa ní agogo nínú ara rẹ

Agogo ínú ara (Circadian rhythms) máa ń fún àwọn àsìkọ̀ bíi alẹ́ àti ọ̀sán, àsìkọ̀ ooru àti òtútú ànfàní àti mọ̀ ìgbà tí ǹkan yóò ṣẹlẹ̀, nítorí náà wọ́n máa ń gbaradì fún wọn.

4. O ní agogo láraà rẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbàgbé nípa agogo GMT, agogo to jà jù fún ara rẹ ni igun ọpọlọ rẹ tí wọ́n pe ní hypothalamus

Ó wà ní igun tí hypothalamus nínú ọpọlọ rẹ, gẹ́gẹ́ bíi atọ̀nà, tó ń fi ojú sí bí àlàyé ṣe ń lọ sí gbogbo ara ní àsìkò ọ̀tọ̀tọ̀.

5. O ní agogo ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ara 'ọmọ ènìyàn máa ń gbìnyànjú láti dúró dédé ni gbogbo ìgbà...

Gbogbo àwọn ríkèé ríkèé ara rẹ ní àlẹékún agogo tí agogo ńlá inú ọpọlọ máa ń mójú tó.

6.Ò sì ní agogo nínú gbogbo sẹ́ẹ́lì rẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbogbo sẹ́ẹ́lì lọ́ mọ̀ àsìkò

Gbogbo sẹ́ẹ́lì ni ara rẹ ní agbára àti máa jí à ti máa jí l'àáàrín wákàtí 24.

7. Agogo ara

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àsìkò oúńjẹ àárọ̀, ní ìlànà ẹranko esi (bear)

Ní àsìkò tí alẹ́ ń gùn sií ti àsìkò orun sì ń gùn sií, ọpọlọ máa ń gbẹ́ èròjà melatonin jáde- èròjà tó máa ń mójútọ́ orun àtí títají.

Ọpọlọpọ eranko, bíi àgbọ̀rín, máa ń lo àsìkò yìí látí ṣe ìbálópọ̀ tá bí kí wọ́n fí ara pamí (hibernate).

Àwọn olùmọ̀ rò wípé ara èèyàn máa ń pèsè èròjà tó máa ń gbógun tí àìsàn nígbà ọ̀tútù.

8.Ọ̀sán máa ń mú ara dá ní gbogbo ìgbà

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán O ní láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òye ọ̀sán l'ojojúmọ́ fún ìlẹra

Tí o bá [wa nínú òkùnkùn, agogo ara rẹ yóò tàsé agogo wákàtí mẹ́rìnlélogún (24).

Àwọn wọ́n yìí ni àwọn isan tó máa ń fi iná ránsé sí igun ọpọlọ tó máa ń jẹ́ kí agogo ara ṣe dédé.

9. Kín l'àsìkò orun?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Báwo ló ṣe mo àsìkò orun?

Láti àsìkò tí o bá jí ní òwúrọ̀, ni wàhálà orun ti ń máa kójọ pọ.

Súgbọ́n o kọ́kín sùn títí tí agogo ara rẹ yóò fi sọ fún o wípé àsìkò tí to láti sùn.

10. Jet lag

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán It can take time to catch up on your sleep after crossing time zones

You feel jet lagged when your body's master clock is at one time and other parts of your body such as your liver, gut, brain and muscles are at slightly different times.

It takes about one day for each time zone crossed for them to synchronise.

11. Wàhálà orun

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nígbà tí agogo rẹ sọ fún o wípé kí o lọ sùn sùgbọ́ ara rẹ sọ wípé "rara"

Àwọn tí wọ́n ṣe isé àsìkò ọ̀tọ̀tọ̀ àti àwọn èlọ̀míràn ti wọ́n ní kọ́núńkọ́họ láàárín àsìkò ara wọn àti àsìkò ìbagbépọ̀ le ní ńǹkan tí wọ̀n pè ní 'social jet lag'.

E lé yìí ni ìyàtọ̀ láàárín àsikò tí ara wọn fẹ́ jí àti àsìkò tí agogo ara wọn sùn.

Àwọn ìwádí fi hàn pé ìabáṣepọ̀ wà láàárín elé yìí àti ọpọ ìrọ̀nú, sísanra jù, àìsan sug àìsàn ọkàn àti àìsàn jejere .

12. E jẹ́ kí àwọn ọdọ́mọdé tó ti rẹ̀ símí

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìsùn àti àìgbọràn láàárń àwọn ọdọ́ wọ́n jọ ń rìn ni

Àwọn èròjà ara (hormone) máa ń pọ̀ síi nígbà t'ọmọ dé bá fẹ́ bàlàgà eléyìí tó ń máa ń dá owọ́ agogo dúró fún bíi wákàtí méjì.

Pípàsẹ fún ọ̀dọ́mọdé kó jí ní agogo 7 òwúrọ̀ dà bíi kí èèyàn jí ẹni àádọ́ta ọdún ní aago 5 òwúrọ̀.

Nígbà tí aba dàgbà aó padà sí bí à ń tí ń sùn tí à ń jí ń gbà tí a wà ní ọ̀dọ́ .