Agbègbè Somolu f'ojú winá ìjà ní ìpínlẹ̀ Èkó

Eko Image copyright Getty Images

Ìjà ìgboro bẹ́ sílẹ̀ ní agbègbè Ṣomolu, ní ìpínlẹ̀ Èkó lásìkò tí ìwọ́de ẹgbẹ́ òṣèlú ń lọ lọ́wọ́.

Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa pé l'Ọjọru tó kọjá ni ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì ló kọlu ara wọn lásìkò tí ẹgbẹ́ òṣèlú kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́páà fi orúkọ bò láṣírí, ń ṣe ìwọ́de òṣèlú nú agbègbè náà.

Ìjà tó wáyé ọ̀hún sì mú kí àwọn olùgbé ní agbègbè Somolu, Bariga, Onipanu àti àwọn àdúgbò míràn tó súnmọ́ wọn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShomolu gbajúmọ̀ fún ìwé títẹ̀

Ẹka ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko to n gbogun ti iwa ọdaran, Rapid Response Squad, RRS, sọ loju opo Twitter rẹ pe ọwọ tẹ eniyan mọkanlelogun lori iṣẹlẹ naa, ti iṣẹ iwadii si n tẹsiwaju.

Ṣugbọn alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko, Chike Oti, kọ̀ lati fi idi eyi mulẹ fun akọroyin BBC, tabi sọ bi iṣẹlẹ naa ṣewaye ati ibi ti nkan de duro.

Related Topics