Arábìnrin kan rè é tó n ṣa ìdọ̀tí l'étí òkun láti dóòlà ìjàpá inú omi ní Nàìjírià

Doyinsola Ogunye on a beach in Lagos, Nigeria Image copyright Ijeoma Ndukwe

Doyin Ogunye ati awọn ogún ọmọde to n finufindọ ba a ṣiṣẹ, maa n fi gbogbo igba ṣa ike ati panti ni bebe odo, eyi to le ṣe akoba fun ijapa inu omi ni ilu Eko.

Ogunye to jẹ olupolongo fun ayika to mọ,ti akọroyin BBC, Ijeoma Ndukwe ba pade ni Elegushi beach sọ pe pipalẹ idọti mọ nigba mi maa n kọja agbara.

L'ọsọọsẹ ni oun ati awọn ọmọde kan maa n ko idọti ti yoo kun aadọta apo nla.

Iṣẹ to l'agbara ni, amọ o fi ara rẹ jin lati dena ijamba to le sẹ awujọ.

Image copyright Ijeoma Ndukwe
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọde yii nkẹkọọ nipa lilo idọti lati pese nkan mi i

Yatọ si pe o maa n ko iti kuro ni bebe òkun naa, o tun maa n gbin igi, o si tun maa n doola awọn ijapa to wa ninu òkun.

Bakan naa ni Ogunye da ibudo kan to to eeka ilẹ mẹtadinlogun silẹ, nibi ti awọn ọmọde maa n lọ lati kọ́ nipa ayika.

Image copyright Ijeoma Ndukwe
Àkọlé àwòrán Kò yẹ ki a máa pa àwọn ẹranko inu omi nipakúpa

Arabinrin Ogunye gbagbọ pe lati ọdọ awọn ọmọde ni ayipada ti n bẹrẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ amofin ni arabinrin Ogunyẹ kọ nileewe, o gba pe oun to wu u ṣe ni lati jẹ ki ìran to n bọ jogun ifẹ ati ẹmi ifọkansin to ni fun ayika.

O pinnu lati da àjọ kan silẹ l'ọdun meje sẹyin lasiko to fi wa nileewe. Ara rẹ si ni ọgbà 'Kids' Beach Garden' ti dide.

Image copyright Ijeoma Ndukwe
Àkọlé àwòrán Diẹ lara awọn ike omi ti wọn ko jade ninu Òkun Elegushi lati fi ṣe awọn nkan mi i

"Gbogbo igba ti mo ba fẹ gba atẹgun alaafia, bebe òkun ni mo maa n wa lati sinmi."

"Mo si ṣakiyesi pe òkun naa dọti. Ko tilẹ si bi ara mi yoo ṣe balẹ niru ibẹ.

Eyi lo mu ki arabinrin Ogunye gbe igbesẹ. O lo akọsilẹ rẹ lati ṣawari awọn ti yoo maa tun òkun naa ṣe laigbowo, lẹyin naa niyoo sa awọn nkan to ṣe fi ṣe nkan mi i lara wọn.

'Ijapa inu omi maa n jẹ ike ju ounjẹ lọ'

Ko pẹ to fi ye e pe oun gbọdọ maa doola awọn ijapa inu okun, bi oun ba se n tun òkun ṣe.

Ọpọlọpọ awọn ẹranko naa lo ri ti omi ti gba si eti òkun.

Image copyright Ijeoma Ndukwe
Àkọlé àwòrán Apẹja kan lo doola ijapa yii ninu omi, sugbọn o ku ki wọn to o le tju rẹ

O ṣalaye pe nkan to n pa ọpọlọpọ ẹranko naa ni ike jijẹ.

"Awọn ọmọ ti wọn ba bi si maa n ku nitori pe ayika eti òkun ko fararọ fun wọn."

Image copyright Ijeoma Ndukwe
Àkọlé àwòrán Yatọ si pe oun tun ayika òkun ṣe, arabinrin Ogunyẹ ti gbin ẹgbẹta igi agbọn seti òkun

O sọ pe o ṣe pataki fun awọn to n gbe ni ayika omi lati ni imọ nipa titọju awọn nkan inu omi.

O ni o pọn dadan lati laa ye awọn agbegbe to n fi ẹja pipa ṣe iṣẹ́ pe ewu nla ni fun wọn ti ko ba fi si ijapa inu omi mọ.