NYSC: àgùnbánirọ̀ márùn ún gb'òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé

NYSC

Oríṣun àwòrán, NYSC

Àkọlé àwòrán,

NYSC

Ile iṣẹ ọlọpaa ti gba awọn agunbanirọ marun ati awọn eeyan meji miran silẹ lọwọ awọn ajinigbe ninu igbo kan nipinlẹ Imo.

Awọn agunbanirọ naa n rinrin ajo lati ilu Ibadan lọ si Ipinlẹ Rivers ati Akwa Ibom l'Ọjọru ki wọn to ji wọn gbe loju ọna mọrosẹ ilu Owerri si Port Harcourt.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Imo Dasuki Galadanchi ni orukọ awọn agunbanirọ ni Abiola Temitope, Olubisi Adekanmi, Jose Temitayo, Folarin Opeyemi and Shonibare Ademola.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

'Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwa dìbò fún Buhari'

O salaye pe awọn ajinigbe ọhun fẹsẹ fẹ nigba ti wọn ri awọn agbofinro ninu igbo ti wọn wa pẹlu akẹẹkọ gboye naa, ṣugbọn o ni wọn ko awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn agunbanirọ ọhun lọ.

Ọga ọlọpaa Galadanchi fi kun ọrọ rẹ pe miliọnu marun naira lawọn ajinigbe ọhun kọkọ beere lọwọ ẹbi awọn agunbanirọ naa ki awọn to fi wọn silẹ.

'Kaduna ni àjọ NYSC pín mi sí sùgbọ́n...'

Àkọlé fídíò,

'Kaduna ni àjọ NYSC pín mi sí sùgbọ́n...'

Josephine Olawa jẹ́ àgùnbánirọ̀ tó yẹ kó lọ sìnrú ìlú ní ìlú Kaduna. Ó ti ra ohun gbogbo bẹ̀ẹ́ sì ni ó ti ṣe gbogbo ètò tó yẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ náà ni àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó yẹ̀ kí wọ́n jọ lọ sùgbọ́n tí ìsẹ̀lẹ̀ Kaduna ti dí wọ́n lọ́wọ́. Àtàwọn àgùnbánirọ̀ àtàwọn òbí wọn ni ìbẹ̀rù bojo ti gba ọkàn wọn.

Ẹ̀wẹ̀, ìgbìmọ aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ti n wá ojúùtú si rògbòdìyàn tó mú ẹ̀mí ènìyàn márùnléláàdọ́ta lọ lọ́jọ́ àìkú.

Lówùrọ̀ ọjọ aje ni wọn ṣe ìpàdé kan ti igbimọ aláṣe si fẹnukò pé kí wọn mú àdínkù bá iye wákàti tí ètò kóníléógbélé yóò fi wà.

Abájáde ìpàdé èètò ààbò naa ti Samuel Aruwan oluranlọwọ fun Gomina Kaduna lori ọrọ ibanisọrọ fi sita ṣe àlàkalẹ ètò kóníléógbélé naa.

Lawọn àdúgbò bi Kasuwan Magani àti Kujama wọn yóò máa wà lábẹ́ kóníléógbélé fún wákàti méjìlá.

Èyí túmọ̀ sí pé láàrín ààgo mẹ́fà ààrọ̀ sí ààgo márùn-ún ìrọ̀lẹ́ dípò wákàti mẹ́rìnlélógun tí wọn gbé lée tẹ́lẹ̀ ni kóníléógbélé yoo fi wa kí àwọn ènìyàn lè ní àànfàní láti lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn.

Oríṣun àwòrán, NASir El-Rufai/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹlẹ naa lo mu ki ijọba ipinlẹ Kaduna kede aṣẹ ko nile o gbele fun wakati mẹrinlelogun.

O sàlàyé pé àgbègbè Kabala West, Kabala Doki, Sabo-Tasha, Narayi àti Maraban Rido tó wà ní ìgboro Kaduna kò ti fararọ nítori àwọn alákatakítí ọ̀hún sí ń gbiyanju lati kógùn já àwọn ènìyàn ní inú sọọsì lásìkò ìṣọ́-òru.

Wọn fi kún-un pé àwọn agbègbè tó kù kò tíì fararọ to nítori náà wọn fi ààyè díẹ̀ sílẹ̀ farailu láti ní àǹfàní fún ríra àwọn ǹkan ti wọn ba nílò nínú ilé.

Ìpàdé náà tún fẹ́nukò pé àwọn agbófinro yóò yí àwọn àdúgbò àti ọja ká láti mójú tó kùdìẹ́-kúdíẹ̀ tó ba wà nílẹ̀.

Lójú òpó twitter gomina ìpínlẹ̀ Kaduna Nasir El-Rufai kabamọ lóri gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai ti fi ẹdun ọkan rẹ han si ija ẹsin to waye nipinlẹ naa lọsẹ to kọja, ninu eyi ti ọpọlọpọ eniyan ti padanu ẹmi wọn.

Iṣẹlẹ yìí lo mu ki ijọba ipinlẹ Kaduna kede aṣẹ ko nile o gbele fun wakati mẹrinlelogun.

El Rufai ni ki awọn ti ọrọ naa kan fi ọkan balẹ nitori pe ijọba yoo ri i daju pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ, ati pe awọn ọdaran to ṣe iṣẹ naa ko ni lọ lai jiya to tọ labẹ ofin.

Ninu ọrọ to sọ lasiko to ba awọn olugbe ni ipinlẹ naa sọrọ lalẹ ọjọ Aje, El-Rufai ba awọn to padanu eniyan wọn tabi dukia sinu iṣẹlẹ naa kẹdun.

O ni ohun to ba ijọba lọkan jẹ pupọ ninu wahala ọhun to waye ni pe ayederu iroyin kan to tan kaakiri gbogbo agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, ni awọn janduku lo anfaani rẹ lati ṣe iṣẹ ibi.

O wa rọ gbogbo awọn olugbe nipinlẹ naa lati faaye gba ara wọn, nitori pe ofin orilẹede Naijiria fi aaye silẹ fun gbogbo eniyan lati gbe ni ibi to ba wu wọn.

Ati pe ọna kan ṣoṣo to le mu ki alaafia jọba lawujọ ni ki awọn to n gbe ninu rẹ ni ọkan lati gbe pọ ni alaafia, isọkan, ati yiyanju aawọ ni ilana ofin.

Oríṣun àwòrán, NASir El-Rufai/Facebook

Lati wa ri i daju pe ẹtọ awọn ọmọ Naijiria lati gbe tabi ṣiṣẹ ni ibi to ba wu wọn, Gomina El-Rufai sọ pe ijọba oun yoo tete ṣiṣẹ lati fi oju eniyan mẹẹdọgbọn ti ọwọ awọn agbofinro tẹ lori iṣẹlẹ to ṣẹṣẹ waye yii, ati awọn mẹtalelọgọta ti wọn mu lasiko eyi to waye ninu oṣu Keji, ọdun 2018 ni agbegbe Kasuwan Magani.

Ọjọ Iṣẹgun, ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa ni igbimọ to n mojuto eto aabo ipinlẹ naa yo tun ṣe ipade lati lati jiroro lori ohun to kan lati ṣe si aṣẹ konile o gbele to wa nita.

Bakan naa lo sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo ti wa nilẹ lati mojuto awọn to n rinrinajo gba ipinlẹ Kaduna lati awọn ipinlẹ bi Eko, ati ilu bi i Abuja, Zaria, Kachia ati Jos.

Látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé ní Kaduna, àjọ àgùnbánirọ̀ (NYSC) tí kéde sísun ètò ìgbaniwọlé àgùnbánirọ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Ọjọ Ajé ni àjọ náà ṣe ìkéde yìí lórí ìtàkùn ayélujára Facebook.

Eyi ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìpínlẹ̀ Kaduna pàṣẹ kónílé ó gbélé wákàtí mẹ́rìnlélógún ní ìlú náà àti agbègbè rẹ̀ nítorí ìdàrúdàpọ̀ titun tó ń jà rọ̀ìn rọ̀ìn ní ìhà àríwá náà lórí kíkásẹ̀ rògbòdìyàn nílẹ̀ ní agbègbè Kasuwan Magani n'ípinlẹ̀ náà l'ọ́jọ́ ẹtì.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

'Ó ṣojú mi kòró, ẹ wọ bí ìgbà ayé Bàbá Fagunwa ṣe rí'

Ó ti di ènìyàn márùnléláàdọ́ta tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí.Ninu àtẹ̀jáde kékeré kan lórí ẹrọ ayélujára twitter ni gómìnà Nasir El-Rufai ti kéde àṣẹ kónílé ó gbélé yìí.

Ọgá ọlọpa Ibrahim Idris ti da ẹ̀ka ọlọ́pàá tó ń ṣe ìwádìí sí'ta, ìgbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá tó n mójú tó zone 7 sì ló darí ẹgbẹ́ náà.

Idris, tí o ṣe lòdì sí ìpànìyàn ní ìpínlẹ̀ náà wí pé àwọn ọlọ́pàá ti jáde si'ta láti bẹrẹ ìwádìí fínífíní sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí o là ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ yìí.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@elrufai

Àkọlé àwòrán,

Gómǹà Elrufai sọ wípé ìgbésẹ̀ náà lótọ́ fún ìpínlẹ̀ náà

Gómínà ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai, ti kéde kónílé ó gbélé ní ìgboro Kaduna àti àwọn agbègbè rẹ̀ nítorí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú náà.

Nínú ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ jáde lórí òpó Twitter rẹ̀, El-Rufaí sọ wípé òhun gbé ìgbésẹ̀ náà ni nítorí ìlọsíwájú ìpílẹ̀ náà.

Ìjà tó ròpọ̀ mọ́n ẹ̀sìn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Kasuwar Magani tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru n' Ọjọ́bọ.

Ìjọba ìpílẹ̀ Kaduna ti kọ́kọ́ séde ní ìlú tí ìjà náà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@elrufai

Àkọlé àwòrán,

Ní Ọjọ́bọ́ ní ìjá kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú Kasuwar Magani ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru

Sùgbọ́n ìjà náà padà tàn dé olú ìlú ìpílẹ̀ náà l'ọjọ́ Àìkú.

Àkọlé àwòrán,

El Rufai: A ti mú àdínkù ba kóníléógbélé