Ìdìbò Cameroon: Paul Biya wọlé ipò àarẹ lẹ́ẹ̀keje

Aarẹ Biya Image copyright Anadolu Agency/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Biya, ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn ti wà ní ipò láti ọdún 1982

Ààrẹ orílẹ̀èdè Cameroon, Paul Biya, ti jáwé olúborí sí ipò àarẹ fún ìgbá keje.

Ó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò nàá tí àwọn aráàlú kò ti jáde láti dìbò, bàkan nàá ni wọn dẹ́rù ba àwọn olùdìbò.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ó ṣojú mi kòró, ẹ wọ bí ìgbà ayé Bàbá Fagunwa ṣe rí'

Ọ̀gbẹ́ni Biya, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàdọ́rùn, ni olórí orílẹ̀èdè tó dàgbà jù ní ilẹ Afrika, ló tún borí pẹ̀lú ìbò ìdá mọ́kànlélàádọ́rin gẹ́gẹ́ bi èsì ìbò tí wọ́n kéde.

Ẹgbẹ́ alátakò tí n polongo fún àtúndì ìbò àarẹ tó wáyé ọ̀hún, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ olùṣàkóso kọ̀ ọ́.

L'ọ́jọ́ Àìkú sì ni wọ́n ti kó àwọn ọlọ́pàá dìgbòlùjà lọ sí àwọn ìlú nla tó wà ní orílẹ̀èdè nàá; Yaounde àti Douala, nítorí tí àwọn alátakò bá fẹ́ ṣe ìfẹ̀hónúhàn.

Agbègbè méjì tí wọ́n ti n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀èdè nàá ti n kojú rògbòdìyàn àti ìkọlù láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀, nínú èyí tí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àkọlé àwòrán Àjọ tó n pẹ̀tù sáàwọ̀ ní àgbáyé sọ pé àwọn olùdìbò kò jáde tó l'áwọn agbègbè méjéèjì tí wọ́n ti n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì

Ọjọ́ méjì ṣáàjú kí wọ́n tó kéde èsì ìbò ni Ààrẹ tó ti pẹ́ lórí oyè julọ̀ ní Afrika, Teodoro Obiang Nguema, tí orílẹ̀èdè Equatorial Guinea kí Ọ̀gbẹ́ni Biya kú oríìre.

Alátakò gbòógì tí Biya ní, Maurice Kamto, ti ẹgbẹ́ òṣèlú MRC/CRM, ní ìdá mẹ́rìnlá péré nínú ìbò tí wọ́n dì.

Ìlàjì àwọn tó tó ìbò dì ní Cameroon ló jáde dìbò, Tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn kò sì ráàyè dìbò nítorí ètò àábò tó mẹ́hẹ.

Ìdúnkookò tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti fi síta láti kọlu àwọn olùdìbò tó wà ní agbègbè tí wọ́n ti n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìrìyìn sọ pé ó jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ jókòó sílé wọn.

Fayoṣe: Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan

Íjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ti kéde kónílé ó gbélé

Oshiomole pajúdà sí àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC

Àwọn kan tilẹ̀ sọ fún ilé iṣẹ́ ìròyìn AFP pé àwọn gbọ́ ìró ìbọn ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Ajé ní Buea, tíì ṣe olú ìlú agbègbè tí wọ́n ti n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Bákan nàá ni àjọ elétò ìdìbò Cameroon, Elecam, nàá dín ibùdó ìdìbò kù jákèjádò àwọn agbègbè tí wọ́n ti n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Ṣáàjú kí wọ́n tó kéde èsì ìbò ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò ti kọ ìwé ẹ̀sùn pé kí àtúndì ìbò wáyé, nítorí 'màgò-mágó, ní ilé ẹjọ́ tó wà fún òfin orílẹ̀èdè Cameroon, èyí tí yóò kéde èsì ìbò nàá.

Ọ̀gbẹ́ni Kamto tilẹ̀ kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹni tó gbégbá orókè nínú ètò ìdìbò nàá láì ní ẹ̀rí kankan láti fi ìdí èyí múlẹ̀.

Image copyright Anadolu Agency/Getty Images
Àkọlé àwòrán Díẹ̀ l'àwọn tó dìbò fi ju ìdá àádọ́ta lọ

Àwọn ònwòye ètò ìdìbò nàá tó ṣojú àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Afrika, sọ pé ètò ìdìbò nàá lọ dáàda, ṣùgbọ́n wọ́n fi kun un pé ''ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú ni kò ní aṣojú ní ibùdó ìdìbò.but added that "most parties were not represented amongst the polling personnel".

Ọjọ́ kan nàá tí ṣe ọjọ́ keje, oṣù Kẹwàá, tí ìdìbò àarẹ wáyé nàá l'óyẹ kí ti ilé aṣòfin wáyé, ṣùgbọ́n wọ́n ti sun un sí ọdún 2019.