NHIS: Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje kalẹ̀ lórí wàhálà iléeṣẹ́ adójútòfò ìlera

Ọjọgbọn Usman Yusuf, akọwe agba ileeṣẹ NHIS

Oríṣun àwòrán, NHIS Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Inu awọn oṣiṣẹ NHIS ko dun si bi ọga agba ajọ naa ko ṣe tẹle aṣẹ lọ rọọ kun nile ti wọn fun un

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye, ijọba apapọ ti ran akọwe agba ajọ adojutofo ilera lorilẹede Naijiria, NHIS, Ọjọgbọn Usman Yusuf lọ si isimi ni kiakia bayii.

Ijọba apapọ tun gbe igbimọ ẹlẹni meje kalẹ lati wadi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Igbimọ iṣakoso ileeṣẹ naa ti fi ẹsun aṣemaṣe lẹnu iṣẹ kan ọjọgbọn Yusuf, eleyi to mu ki wọn ni ko lọ rọọ kun nile laipẹ yii ṣugbọn ti akọwe agba naa kuna lati tẹle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi fa ọpọlọpọ ikunsinu ni ileeṣẹ NHIS, debi pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ṣe iwọde.

Ṣaaju asiko naa ni Ọjọgbọn Yusuf sọ pe awọn ti o fẹ maa ṣe owo araalu to wa labẹ eto adojutofo ilera baṣubaṣu ni wọn n ko ina wahala mọ oun ni idi, ṣugbọn awọn ọmọ igbimọ naa sọ pe o di igba ti abọ iwadi ba jade ki awọn eeyan to ri idi okodoro ọrọ naa.

NHIS: Kíni ó ń fa wàhálà fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Usman Yusuf lórí ọ̀rọ̀ adójútòfò ìlera?

Àkọlé àwòrán,

Minisita feto ilera naa ti f'gbakan ri paṣẹ lọ rọọkun nile fun Ọjọgbọn Yusuf ṣugbọn ti aarẹ Buhari daa pada

Ina ru ni ileeṣẹ adojutofo ilera lorilẹede Naijiria, NHIS, ina ọhun kii sii ṣẹ kekere.

Awọn igbimọ alakoso ileeṣẹ naa ni wọn pe birikoto paṣẹ lọ rọọkun nile naa fun ẹni to jẹ ọga agba ileeṣẹ naa, Ọjọgbọn Usman Yusuf lori ẹsun iwa ko-tọ ti wọn fi kan an.

Wọn ni ko yẹra fun igba diẹ ki wọn fi ṣe iwadii lori awọn ẹsun ọhun, ṣugbọn Ọjọgbọn Yusuf kọ jalẹ ko tẹle aṣẹ yii lo ba tun gba ileeṣẹ naa lọ ni ọjọ aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa ọrọ kọ sisọ nitori nṣe lawọn oṣiṣẹ ajọ naa dabu rẹ ti wọn pẹlu iwọde ti wọn ko si fun un lanfani lati wọ ileeṣẹ naa.

Ni afẹmọjumọ lawọn oṣiṣẹ naa ti lọ ti abawọle ileeṣẹ naa pa, ti wọn si ni Ọjọgbọn Yusuf ko lẹtọ lati wa si ibi iṣẹ nitori wọn ti ni ko lọ rọọkun nile naa.

Àkọlé àwòrán,

Igbimọ alakoso NHIS ni ki ọga agba ileeṣẹ naa, Ọjọgbọn Usman Yusuf lọ rọọkun nile naa

Amọṣa, eyi kọ ni igba akọkọ ti ọga agba ajọ adojutofo ilera lorilẹede Naijiria yoo maa ko sinu ọgbun wahala bayii.

Ni oṣu diẹ sẹyin ni minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Isaac Adewọle pẹlu ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun lori oniruuru ẹsun iwa ijẹkujẹ ṣugbọn ti aarẹ Buhari daa pada pe ko lọ bẹrẹ iṣẹ.

Eyi mu ki ọpọ eeyan maa bere pe ki gan an lo wa laarin aarẹ ati ọjọgbọn Usman Yusuf?

Oríṣun àwòrán, @IsaacFAdewole

Àkọlé àwòrán,

Inu awọn oṣiṣẹ NHIS ko dun si bi ọga agba ajọ naa ko ṣe tẹle aṣẹ lọ rọọ kun nile ti wọn fun un

Ọjọgbọn Usman Yusuf ni ko si ohun ikọkọ kan laarin ohun ati aarẹ ati pe ilana ofin ni aarẹ n tẹlẹ eleyi to fidi rẹ mulẹ wi pe igbimọ tabi minisita ko lee yọ oun bi ko ṣe aarẹ.

Ọjọgbọn Usman Yusuf ni awọn eeyan ti wọn n lo owo ara ilu lati lu jibiti lẹka naa ni wọn n fin ina mọ oun nidi.

O ni awọn alakoso eto adojutofo ilera ti amọ si HMO ko ri owo ọfẹ na mọ; wọn ko si gbadun awọn ilana atunto gbogbo ti oun n gbe kalẹ lo faa; eyi lo si n fa wahala lọ rọọ kun nile ti wọn n fun oun.