2019 Election: INEC ya ọ̀sẹ̀ kan sílẹ̀ fún àyẹ̀wò orúkọ oludibo

Aworan ayẹwo orukọ

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán,

Aworan alaye ayẹwo orukọ awọn oludibo

Ajọ eleto idibo lorile-ede Naijiria, INEC ti bẹrẹ afihan iwe orukọ awọn oludibọ jakejado orileede Naijiria.

INEC ni igbesẹ yi wa ni ibamu pẹlu ofin idibo orileede Naijiria.

Laarin agogo mẹsan owurọ titi di aago mẹta ọsan ni ayẹwo orukọ naa yoo ma waye lojumọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Lekan Kingkong: Níbikíbi tí mo bá wà, màá gbé àṣà Yorùbá ga

Oju opo Twitter INEC ni ikede nipa ibẹrẹ ayẹwo orukọ yii ti waye.

Laipẹ yii ni Alaga ajọ eleto idibo, INEC, ọgbẹni Mahmood Yakubu ba awọn akọroyin sọrọ lori awọn alaye to ni se pẹlu idibo to n bọ lọna.

Pataki lara awọn ohun ti wọn sọ nibi ipade naa ni pe, awọn yoo fun awọn ara ilu lanfani lati gba ile ẹjọ lọ, ti alaye kankan nipa oludije ipo Aarẹ ati awọn to n du ipo ile asọfin agba ti wọn ba fi sita ninu iwe 'Form CF001' ko ba tẹ wọn lọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awon oludibo

Mahmood salaye pe, igbese yii yoo fun awọn ara ilu laanfani lati tọpinpin awọn to fẹ soju wọn saaju ọjọ idibo.

Ninu alaye rẹ, o ni wọn le gba ile ẹjọ giga lọ ti wọn ba ri aisedede kankan ninu ohun ti oludije naa ba fi sọwọ.

Yakubu fikun pe, awọn yoo fi ọsẹ kan se afihan orukọ awọn oludibo, bẹrẹ lati ọjọ kẹfa Oṣu kọkanla ọdun yi titi di ọjọ kejila Oṣu kọkanla

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Ireti INEC ni pe, ayẹwọ orukọ yi yoo fun awọn ara ilu lanfaani lati mọ boya aisedede kankan wa ninu orukọ wọn.

Ọjọ méjìléláàdọ́fà lo ku ki idibo ọdun 2019 fi waye, awọn oludije mọ́kàndínlọ́gọ́rin ( 79) si ni yoo du ipo Aarẹ.

INEC sọ wi pe, ẹgbẹ oselu mọ́kàndínláàdọ́rùn ún lo ti fi orukọ oludije bii ẹgbẹrun kan ati mẹtalelẹgbẹrin (1,803) sọwọ fun ipo asofin agba, nigba ti wọn si ti fọwọ si orukọ awọn 4,548 fun ipo asoju-sofin.