Aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkìtì tí wọ́n yìnbọn fún ti kú nílé ìwòsàn

Aworan ọkọ kan ti wọn yinbọn lu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kò tí ìdájú ìdí tí àwọn agbébọn náà ṣe ṣíná fún ọkọ̀ Adedeji

Iléese ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti ti fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé aṣòfin Micheal Adedeji tí agbébọ́n yìnbọ́n fún l'ọ́jọ́ Etì ti rẹ̀ walẹ̀ àsà.

Ní ọjọ́ Ajé ni agbenusọ fún ilé iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Caleb Ikechukwu, sọ pé ìwádìí ti fi hàn pé asòfin náà ti pá'pò dà.

Lọ́jọ́ Etì ní àwọn agbébọn kan yìnbọn fún Micheal Adedeji.

Nígbà náà, orí bá Micheal ṣeé pẹ̀lu bí í ti ṣe ríbi jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn agbégbon ọ̀hún nígbà tí ó ń lọ sí ìlú Akurẹ.

Igbákejì olórí ilé asòfin Ekiti, Segun Adewumi fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn oníròyìn l'ọ́jọ́ Ẹtì.

Àkọlé fídíò,

Ìṣẹlẹ iyinbon APC Ekiti : Ki gaan lo ṣẹlẹ?

Ó ní wọ́n sáré gbé Adedeji tó ń sojú agbègbè iwọ̀ oòrùn guusu kejì ní ilé asòfin Ekiti lọ sí ilé ìwòsàn kan ní Ado Ekiti lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì tún gbée lọ sí ilé ìwòsàn olùkọ́ni ìjọba àpapọ̀ ní Ido Ekiti.

Ta ni Aṣofin Adedeji?

Ọ̀gbẹ́ni Adedeji wà lára àwọn asojú tí wọ́n yọ olórí ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ , Kola Oluwawọle tí wọ́n sì fi Adeniran Alagbada rọ́pò rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, olórí ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ekiti, Adeniran Alagbada ti ké sí àwọn ọlọ́pàá latí ríi wí pé wọ́n se ìwádìi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìyìnbọn mọ́ Adedeji.

Nínú àtèjáde kan láti ọwọ́ agbenusọ fún olórí ilé ,Oluwatoyin Babablola, ó ní èyí kìí se ''ìgba àkọ́kọ́ tí àwọn kan yóò máa dún kùkùlàjà mọ́ àwọn ọmọ ilé asòfin tófi mọ́ oun náà''

''Ejò ọ̀rọ̀ yíì lọ́wọ́ nínú, fún ìdí èyí mo rọ̀ àwọn ọlọ́pàá láti tọ pinpin rẹ̀''

Àkọlé fídíò,

Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Àkọlé fídíò,

#67yearoldmother:ọ̀pọ̀ gbà pé àdúrà ló gbà lóri tọkọtaya Otubusin