Ochanya Ogbanje: Iwọ́de fún Ochanya wáye nílu Eko

Ochanya Ogbanje: Iwọ́de fún Ochanya wáye nílu Eko

Lẹyin ti iwọde fun Ochanya Ogbanje, ọmọ obinrin ti wọn fipa balopọ waye ni olu ilu Naijiria l'abuja, awọn oluwọde miiran se iwọde fun nilu Eko.

Ni ile iwọsan ikọni ipinlẹ Benue ni Ochanya ti gbẹmi mi latari bi awọn okunrin meji, baba ati ọmọkunrin rẹ ṣe fipa ba a lo pọ ti o si fa aisan oju ara obirin ti wọn pe ni Vesicovaginal fistula (VVF) fun un.

Ọjọ kọkandinlogun osu kẹwa ni Ochanya papoda ni ile iwosan ikọni to wa ni Makurdi.

Lára àwọn aṣèwọ́de fi ẹ̀hónú wọn han fún akọ̀ròyìn BBC nípa ọ̀rọ̀ obìnrin nílẹ̀ Áfíríkà, Abigail Ony Nwaohuocha.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: